Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




2 Peteru 2:3 - Bibeli Mimọ

3 Ati ninu ojukòkoro ni nwọn o mã fi nyin ṣe ere jẹ nipa ọrọ ẹtàn: idajọ ẹniti kò falẹ̀ lati ọjọ ìwa, ìparun wọn kò si tõgbé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Wọn óo fi ọ̀rọ̀ dídùn tàn yín nítorí ojúkòkòrò, kí wọ́n lè fi yín ṣe èrè jẹ. Ìdájọ́ tí ó wà lórí wọn láti ìgbà àtijọ́ kò parẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìparun tí ń bọ̀ wá bá wọn kò sùn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Nínú ìwà wọ̀bìà wọn, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ òdì wọ̀nyí yóò máa rẹ́ ẹ yín jẹ nípa ìtàn asán. Ìdájọ́ ẹni tí kò falẹ̀ láti ìgbà yìí wá àti ìparun wọn tí kò sí tòògbé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




2 Peteru 2:3
43 Iomraidhean Croise  

Ani ẹnyin ṣẹ́ gege fun alainibaba, ẹnyin si da iye le ọrẹ nyin.


Bi nwọn ti gburo mi, nwọn o gbà mi gbọ́: awọn ọmọ àjeji yio fi ẹ̀tan tẹ̀ ori wọn ba fun mi.


Ẹ wi fun Ọlọrun pe, Iwọ ti li ẹ̀ru to ninu iṣẹ rẹ! nipa ọ̀pọ agbara rẹ li awọn ọta rẹ yio fi ori wọn balẹ fun ọ.


Awọn akorira Oluwa iba ti fi ori wọn balẹ fun u; igba wọn iba si duro pẹ titi.


Awọn ti o wipe, Jẹ ki o yara, ki o si mu iṣẹ rẹ̀ yara, ki awa ki o le ri i: ati jẹ ki ìmọ Ẹni-Mimọ́ Israeli sunmọ ihin, ki o si wá, ki awa ki o le mọ̀ ọ.


Nitõtọ ọjẹun aja ni nwọn ti kì iyó, ati oluṣọ́ agutan ti kò moye ni nwọn: olukuluku wọn nwò ọ̀na ara wọn, olukuluku ntọju ere rẹ̀ lati ẹ̀kun rẹ̀ wá.


Ẹni-kekere kan ni yio di ẹgbẹrun, ati kekere kan yio di alagbara orilẹ-ède: emi Oluwa yio ṣe e kankan li akokò rẹ̀.


Lati kekere wọn titi de nla wọn, gbogbo wọn li o fi ara wọn fun ojukokoro, ati lati woli titi de alufa, gbogbo wọn ni nṣe eke.


Nitorina ni emi o fi aya wọn fun ẹlomiran, ati oko wọn fun awọn ti yio gbà wọn: nitori gbogbo wọn, lati ẹni kekere titi o fi de enia-nla, fi ara wọn fun ojukokoro, lati woli titi de alufa, gbogbo wọn nṣe ẹ̀tan.


Ẹnyin o ha si bà mi jẹ lãrin awọn enia mi nitori ikunwọ ọkà bàba, ati nitori òkele onjẹ, lati pa ọkàn ti kì ba kú, ati lati gba awọn ọkàn ti kì ba wà lãye là, nipa ṣiṣeke fun awọn enia mi ti ngbọ́ eke nyin?


Awọn olori rẹ̀ nṣe idajọ nitori ère, awọn alufa rẹ̀ nkọ́ni fun ọyà, awọn woli rẹ̀ si nsọtẹlẹ fun owo: sibẹ ni nwọn o gbẹkẹle Oluwa, wipe, Oluwa kò ha wà lãrin wa? ibi kan kì yio ba wa.


Ọlọrun yio ti Temani wá, ati Ẹni Mimọ́ lati oke Parani. Ogo rẹ̀ bò awọn ọrun, ilẹ aiye si kun fun iyìn rẹ̀.


Ta si ni ninu nyin ti yio se ilẹkun? bẹ̃li ẹnyin kò da iná asan lori pẹpẹ mi mọ. Emi kò ni inu-didùn si nyin, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, bẹ̃li emi kì yio gba ọrẹ kan lọwọ nyin.


Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin jẹ ile awọn opó run, ati nitori aṣehan, ẹ ngbadura gigun: nitorina li ẹnyin o ṣe jẹbi pọ̀ju.


Mo wi fun nyin, yio gbẹsan wọn kánkán. Ṣugbọn nigbati Ọmọ-enia ba de yio ha ri igbagbọ́ li aiye?


Nwọn si nṣọ ọ, nwọn si rán awọn amí ti nwọn jẹ ẹlẹtan fi ara wọn pe olõtọ enia, ki nwọn ki o le gbá ọ̀rọ rẹ̀ mu, ki nwọn ki o le fi i le agbara ati aṣẹ Bãlẹ.


Bi o si ti nsọ lọwọ, kiyesi i, ọ̀pọ enia, ati ẹniti a npè ni Judasi, ọkan ninu awọn mejila, o ṣaju wọn o sunmọ Jesu lati fi ẹnu kò o li ẹnu.


O si wi fun awọn ti ntà àdaba pe, Ẹ gbe nkan wọnyi kuro nihin; ẹ máṣe sọ ile Baba mi di ile ọjà tità.


Nitori awọn ti o ri bẹ̃ kò sìn Jesu Kristi Oluwa wa, bikoṣe ikùn ara wọn; ọ̀rọ rere ati ọ̀rọ didùndidùn ni nwọn fi npa awọn ti kò mọ̀ meji li ọkàn dà.


Nitori awa kò dabi awọn ọ̀pọlọpọ, ti mba ọ̀rọ Ọlọrun jẹ́: ṣugbọn bi nipa otitọ inu, ṣugbọn bi lati ọdọ Ọlọrun wá, niwaju Ọlọrun li awa nsọ̀rọ ninu Kristi.


Iwọ kò gbọdọ yi idajọ alejò po, tabi ti alainibaba; bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe gbà aṣọ opó ni ogò:


Ti emi ni igbẹsan, ati ẹsan, li akokò ti ẹsẹ̀ wọn yio yọ́: nitoriti ọjọ́ idamu wọn sunmọtosi, ohun ti o si mbọ̀ wa bá wọn nyára wá.


Nitori awa kò lo ọrọ ipọnni nigbakan rí gẹgẹ bi ẹnyin ti mọ̀, tabi iboju ojukòkoro; Ọlọrun li ẹlẹri:


Nigbati nwọn ba nwipe, alafia ati ailewu; nigbana ni iparun ojijì yio de sori wọn gẹgẹ bi irọbi lori obinrin ti o lóyun; nwọn kì yio si le sálà.


Ki o má jẹ ọmuti, tabi onijà, tabi olojukokoro, bikoṣe onisũru, ki o má jẹ onija, tabi olufẹ owo;


Bẹ̃ gẹgẹ li o yẹ fun awọn diakoni lati ni ìwa àgba, ki nwọn má jẹ ẹlẹnu meji, kì nwọn má fi ara wọn fun waini pupọ̀, ki nwọn má jẹ olojukokoro.


Ọ̀rọ̀ ayipo awọn enia ọlọkan ẽri ti kò si otitọ ninu wọn, ti nwọn ṣebi ọna si ere ni ìwa-bi-Ọlọrun: yẹra lọdọ irú awọn wọnni.


Awọn ẹniti a kò le ṣaipa li ẹnu mọ, nitoriti wọn nda odidi agbo ilé rú, ti nwọn nkọni ni ohun ti kò yẹ nitori ere aitọ́.


Nitori o yẹ ki biṣopu jẹ alailẹgàn, bi iriju Ọlọrun; ki o má jẹ aṣe-tinu-ẹni, oninu-fùfu, ọmuti, aluni, olojukokoro;


Ati pẹlu, okuta idigbolu, on apata ikọsẹ̀. Nitori nwọn kọsẹ nipa ṣiṣe aigbọran si ọrọ na ninu eyiti a gbé yàn wọn si pẹlu.


Ẹ mã tọju agbo Ọlọrun ti mbẹ lãrin nyin, ẹ mã bojuto o, kì iṣe afipáṣe, bikoṣe tifẹtifẹ; bẹni ki iṣe ọrọ ère ijẹkujẹ, ṣugbọn pẹlu ọkàn ti o mura tan.


Nitori ki iṣe bi ẹniti ntọ ìtan asan lẹhin ti a fi ọgbọ́n-kọgbọn là silẹ, li awa fi agbara ati wíwá Jesu Kristi Oluwa wa hàn nyin, ṣugbọn ẹlẹri ọlá nla rẹ̀ li awa iṣe.


ṢUGBỌN awọn woli eke wà lãrin awọn enia na pẹlu, gẹgẹ bi awọn olukọ́ni eke yio ti wà larin nyin, awọn ẹniti yio yọ́ mu adámọ ègbé wọ̀ inu nyin wá, ani ti yio sẹ́ Oluwa ti o rà wọn, nwọn o si mu iparun ti o yara kánkán wá sori ara wọn.


Oluwa mọ̀ bi ã ti íyọ awọn ẹni ìwa-bi-Ọlọrun kuro ninu idanwo ati bi ã ti ípa awọn alaiṣõtọ ti a njẹ niya mọ dè ọjọ idajọ:


Egbé ni fun wọn! Nitoriti nwọn ti rìn li ọ̀na Kaini, nwọn si fi iwọra súré sinu ìṣina Balaamu nitori ère, nwọn si ṣegbé ninu iṣọtẹ̀ Kora.


Lati ṣe idajọ gbogbo enia, lati dá gbogbo awọn alaiwa-bi-Ọlorun lẹbi niti gbogbo iṣe aiwa-bi-Ọlorun wọn, ti nwọn ti fi aiwa-bi-Ọlorun ṣe, ati niti gbogbo ọ̀rọ lile ti awọn ẹlẹṣẹ aiwa-bi-Ọlọrun ti sọ si i.


Awọn wọnyi li awọn ti nkùn, awọn alaroye, ti nrìn nipa ifẹkufẹ ara wọn; ẹnu wọn a mã sọ ọ̀rọ ìhalẹ, nwọn a mã ṣojuṣãjú nitori ere.


Nitori awọn enia kan mbẹ ti nwọn nyọ́ wọle, awọn ẹniti a ti yàn lati igbà atijọ si ẹbi yi, awọn alaiwa-bi-Ọlọrun, ti nyi ore-ọfẹ Ọlọrun wa pada si wọbia, ti nwọn si nsẹ́ Oluwa wa kanṣoṣo na, ani Jesu Kristi Oluwa.


Ani bi Sodomu ati Gomorra, ati awọn ilu agbegbe wọn, ti fi ara wọn fun àgbere iṣe bakanna, ti nwọn si ntẹle ara ajeji lẹhin, awọn li a fi lelẹ bi apẹrẹ, nwọn njìya iná ainipẹkun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan