Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




2 Peteru 2:2 - Bibeli Mimọ

2 Ọpọlọpọ ni yio si mã tẹle ìwa wọbia wọn; nipa awọn ẹniti a o fi mã sọ ọrọ-odi si ọ̀na otitọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Ọpọlọpọ eniyan ni yóo bá wọn kẹ́gbẹ́ ninu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn; nítorí ìṣe wọn, àwọn eniyan yóo máa gan ọ̀nà òtítọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò si máa tẹ̀lé ọ̀nà ìtìjú wọn, tí wọn yóò sì mú kí ọ̀nà òtítọ́ di ìsọ̀rọ̀-òdì sí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




2 Peteru 2:2
36 Iomraidhean Croise  

Nwọn si pè Loti, nwọn si bi i pe, Nibo li awọn ọkunrin ti o tọ̀ ọ wá li alẹ yi wà? mu wọn jade fun wa wá, ki awa ki o le mọ̀ wọn.


Nitori mo ti nkiye si ọ̀na Oluwa, emi kò fi ìka yà kuro lọdọ Ọlọrun mi.


Opopo kan yio si wà nibẹ, ati ọ̀na kan, a o si ma pè e ni, Ọ̀na iwà-mimọ́; alaimọ́ kì yio kọja nibẹ; nitori on o wà pẹlu wọn: awọn èro ọ̀na na, bi nwọn tilẹ jẹ òpe, nwọn kì yio ṣì i.


Bayi li Oluwa wi, ẹ duro li oju ọ̀na, ki ẹ si wò, ki ẹ si bere oju-ọ̀na igbàni, ewo li ọ̀na didara, ki ẹ si rin nibẹ, ẹnyin o si ri isimi fun ọkàn nyin. Ṣugbọn nwọn wipe, Awa kì yio rin.


Nwọn si rán awọn ọmọ-ẹhin wọn pẹlu awọn ọmọ-ẹhin Herodu lọ sọdọ rẹ̀, wipe, Olukọni, awa mọ̀ pe olotitọ ni iwọ, iwọ̀ si nkọni li ọ̀na Ọlọrun li otitọ, bẹ̃ni iwọ ki iwoju ẹnikẹni: nitoriti iwọ kì iṣe ojuṣaju enia.


Nitori awọn eke Kristi, ati eke wolĩ yio dide, nwọn o si fi àmi ati ohun iyanu nla hàn; tobẹ̃ bi o le ṣe ṣe nwọn o tàn awọn ayanfẹ pãpã.


Nitori pe hihá ni ẹnu-ọ̀na na, ati toro li oju-ọ̀na na, ti o lọ si ibi ìye, diẹ li awọn ẹniti o nrin i.


Nigbati nwọn si de, nwọn wi fun u pe, Olukọni, awa mọ̀ pe olotitọ ni iwọ bẹ̃ni iwọ kì iwoju ẹnikẹni: nitori iwọ kì iṣe ojuṣãju enia, ṣugbọn iwọ nkọ́ni li ọ̀na Ọlọrun li otitọ: O tọ́ lati mã san owode fun Kesari, tabi kò tọ́?


Nitori awọn eke Kristi, ati awọn eke woli yio dide, nwọn o si fi àmi ati ohun iyanu hàn, tobẹ̃ bi o ṣe iṣe, nwọn iba tàn awọn ayanfẹ pãpã.


Jesu wi fun u pe, Emi li ọ̀na, ati otitọ, ati iye: kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi.


Iwọ ti o kún fun arekereke gbogbo, ati fun iwà-ìka gbogbo, iwọ ọmọ Eṣu, iwọ ọta ododo gbogbo, iwọ kì yio ha dẹkun ati ma yi ọna titọ́ Oluwa po?


Ṣugbọn awọn alaigbagbọ́ Ju rú ọkàn awọn Keferi soke, nwọn si rọ̀ wọn si awọn arakunrin na.


On na li o ntọ̀ Paulu ati awa lẹhin, o si nkigbe, wipe, Awọn ọkunrin wọnyi ni iranṣẹ Ọlọrun Ọgá-ogo, ti nkede ọ̀na igbala fun nyin.


O si bẹ̀rẹ si fi igboiya sọrọ ni sinagogu: nigbati Akuila on Priskilla ti gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, nwọn mu u si ọdọ nwọn si tubọ sọ idi ọ̀na Ọlọrun fun u dajudaju.


Ṣugbọn nigbati ọkàn awọn miran ninu wọn di lile, ti nwọn kò si gbagbọ́, ti nwọn nsọ̀rọ ibi si Ọna na niwaju ijọ enia, o lọ kuro lọdọ wọn, o si yà awọn ọmọ-ẹhin sọtọ̀, o si nsọ asọye li ojojumọ́ ni ile-iwe Tirannu.


Mo si ṣe inunibini si Ọna yi titi o fi de iku, mo ndè, mo si nfi wọn sinu tubu, ati ọkunrin ati obinrin.


Ṣugbọn eyi ni mo jẹwọ fun ọ, pe bi Ọna ti a npè ni adamọ̀, bẹ̃li emi nsìn Ọlọrun awọn baba wa, emi ngbà nkan gbogbo gbọ́ gẹgẹ bi ofin, ati ti a kọ sinu iwe awọn woli:


Nitori orukọ Ọlọrun sá di isọrọ-buburu si ninu awọn Keferi nitori nyin, gẹgẹ bi a ti kọ ọ.


Nitorina mo fẹ ki awọn opo ti kò dagba mã gbeyawo, ki nwọn mã bímọ, ki nwọn ki o mã ṣe alabojuto ile, ki nwọn ki o máṣe fi àye silẹ rara fun ọtá na lati sọ̀rọ ẹ̀gan.


Lati jẹ alairekọja, mimọ́, òṣiṣẹ́ nile, ẹni rere, awọn ti ntẹriba fun awọn ọkọ wọn, ki ọrọ Ọlọrun ki o máṣe di isọ̀rọ-òdi si.


Ọ̀rọ ti o yè kõro, ti a kò le da lẹbi; ki oju ki o tì ẹniti o nṣòdi, li aini ohun buburu kan lati wi si wa.


Ki ìwa nyin larin awọn Keferi kí o dara; pe, bi nwọn ti nsọ̀rọ nyin bi oluṣe buburu, nipa iṣẹ rere nyin, ti nwọn o mã kiyesi, ki nwọn ki o le mã yìn Ọlọrun logo li ọjọ ìbẹwo.


Ṣugbọn awọn wọnyi, bi ẹranko igbẹ́ ti kò li ero, ẹranko ṣa ti a dá lati mã mu pa, nwọn nsọ̀rọ ẹgan ninu ọran ti kò yé wọn; a o pa wọn run patapata ninu ibajẹ ara wọn.


Nwọn kọ̀ ọ̀na ti o tọ́ silẹ, nwọn si ṣako lọ, nwọn tẹle ọ̀na Balaamu ọmọ Beori, ẹniti o fẹràn ère aiṣododo;


Nitori igbati nwọn ba nsọ̀rọ ihalẹ asan, ninu ifẹkufẹ ara, nipa wọbia, nwọn a mã tan awọn ti nwọn fẹrẹ má ti ibọ tan kuro lọwọ ti nwọn wà ninu iṣina.


Nitori ìba san fun wọn, ki nwọn ki o má mọ̀ ọ̀na ododo, jù lẹhin ti nwọn mọ̀ ọ tan, ki nwọn ki o yipada kuro ninu ofin mimọ́ ti a fifun wọn.


O si yọ Loti olõtọ, ẹniti ìwa wọbia awọn enia buburu bà ninu jẹ:


Ṣugbọn awọn wọnyi nsọ̀rọ-òdi si ohun gbogbo ti nwọn kò mọ̀: ṣugbọn ohun gbogbo ti nwọn mọ̀ nipa ẹda, bi ẹranko tí kò ni iyè, ninu nkan wọnyi ni nwọn di ẹni iparun.


Lati ṣe idajọ gbogbo enia, lati dá gbogbo awọn alaiwa-bi-Ọlorun lẹbi niti gbogbo iṣe aiwa-bi-Ọlorun wọn, ti nwọn ti fi aiwa-bi-Ọlorun ṣe, ati niti gbogbo ọ̀rọ lile ti awọn ẹlẹṣẹ aiwa-bi-Ọlọrun ti sọ si i.


Nitori awọn enia kan mbẹ ti nwọn nyọ́ wọle, awọn ẹniti a ti yàn lati igbà atijọ si ẹbi yi, awọn alaiwa-bi-Ọlọrun, ti nyi ore-ọfẹ Ọlọrun wa pada si wọbia, ti nwọn si nsẹ́ Oluwa wa kanṣoṣo na, ani Jesu Kristi Oluwa.


Ani bi Sodomu ati Gomorra, ati awọn ilu agbegbe wọn, ti fi ara wọn fun àgbere iṣe bakanna, ti nwọn si ntẹle ara ajeji lẹhin, awọn li a fi lelẹ bi apẹrẹ, nwọn njìya iná ainipẹkun.


A si lé dragoni nla na jade, ejò lailai nì, ti a npè ni Èṣu, ati Satani, ti ntàn gbogbo aiye jẹ, a si lé e jù si ilẹ aiye, a si le awọn angẹli rẹ̀ jade pẹlu rẹ̀.


O si ntàn awọn ti ngbe ori ilẹ aiye jẹ nipa awọn ohun iyanu ti a fi fun u lati ṣe niwaju ẹranko na; o nwi fun awọn ti ngbe ori ilẹ aiye lati ya aworan fun ẹranko na ti o ti gbà ọgbẹ idà, ti o si yè.


Gbogbo awọn ti ngbe ori ilẹ aiye yio si mã sin i, olukuluku ẹniti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe iyè Ọdọ-Agutan ti a ti pa lati ipilẹṣẹ aiye.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan