Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




2 Peteru 1:3 - Bibeli Mimọ

3 Bi agbara rẹ̀ bi Ọlọrun ti fun wa li ohun gbogbo ti iṣe ti ìye ati ti ìwa-bi-Ọlọrun, nipa ìmọ ẹniti o pè wa nipa ogo ati ọlanla rẹ̀:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Nípa agbára Ọlọrun tí kì í ṣe ti eniyan, ó ti fún wa ní ohun gbogbo tí yóo jẹ́ kí á gbé irú ìgbé-ayé tí ó dára ati ti ìwà-bí-Ọlọrun, nípa mímọ ẹni tí ó fi ògo ati ọlá rẹ̀ pè wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Bí agbára rẹ̀ bí Ọlọ́run ti fún wa ní ohun gbogbo tí a nílò fún ṣe ti ìyè àti ti ìwà-bí-Ọlọ́run, nípa ìmọ̀ ẹni tí ó pè wá nípa Ògo àti ìṣeun rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




2 Peteru 1:3
39 Iomraidhean Croise  

Ọlọrun ore-ọfẹ gbogbo, ti o ti pè nyin sinu ogo rẹ̀ ti kò nipẹkun ninu Kristi Jesu, nigbati ẹnyin ba ti jìya diẹ, On tikarãrẹ, yio si ṣe nyin li aṣepé, yio fi ẹsẹ nyin mulẹ, yio fun nyin li agbara, yio fi idi nyin kalẹ.


Ẹniti o gbà wa là, ti o si fi ìpe mimọ́ pè wa, kì iṣe gẹgẹ bi iṣe wa, ṣugbọn gẹgẹ bi ipinnu ati ore-ọfẹ tirẹ̀, ti a fifun wa ninu Kristi Jesu lati aiyeraiye,


Nitori Oluwa Ọlọrun li õrun ati asà: Oluwa yio fun ni li ore-ọfẹ ati ogo: kò si ohun rere ti yio fà sẹhin lọwọ awọn ti nrìn dede.


Ẹniti kò da Ọmọ on tikararẹ̀ si, ṣugbọn ti o jọwọ rẹ̀ lọwọ fun gbogbo wa, yio ha ti ṣe ti kì yio fun wa li ohun gbogbo pẹlu rẹ̀ lọfẹ?


On si wi fun mi pe, Ore-ọfẹ mi to fun ọ: nitoripe a sọ agbara mi di pipé ninu ailera. Nitorina tayọ̀tayọ̀ li emi ó kuku ma ṣogo ninu ailera mi, ki agbara Kristi ki o le mã gbe inu mi.


Nitori inu eyi li a pè nyin si: nitori Kristi pẹlu jìya fun nyin, o fi apẹrẹ silẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mã tọ̀ ipasẹ rẹ̀:


Eyiti o ti pè nyin si nipa ihinrere wa, ki ẹnyin ki o le gbà ogo Jesu Kristi Oluwa wa.


Ṣugbọn ẹnyin ni iran ti a yàn, olu-alufa, orilẹ-ède mimọ́, enia ọ̀tọ; ki ẹnyin ki o le fi ọla nla ẹniti o pè nyin jade kuro ninu òkunkun sinu imọlẹ iyanu rẹ̀ hàn:


Ki ẹnyin ki o le mã rìn ni yiyẹ Ọlọrun, ẹniti o npè nyin sinu ijọba ati ogo On tikararẹ.


Nitori Ọlọrun kò pè wa fun ìwa ẽri, ṣugbọn ni ìwamimọ́.


Ṣugbọn gẹgẹ bi Ẹni ti o pè nyin ti jẹ mimọ́, bẹ̃ni ki ẹnyin na si jẹ mimọ́ ninu ìwa nyin gbogbo:


NITORINA emi ondè ninu Oluwa, mbẹ̀ nyin pe, ki ẹnyin ki o mã rìn bi o ti yẹ fun ìpe na ti a fi pè nyin,


Olododo li Ọlọrun, nipasẹ ẹniti a pè nyin sinu ìdapọ Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi Oluwa wa.


Ki ore-ọfẹ ati alafia ki o mã bisi i fun nyin ninu ìmọ Ọlọrun, ati ti Jesu Oluwa wa,


Ati nitori eyi nã pãpã, ẹ mã ṣe aisimi gbogbo, ẹ fi ìwarere kún igbagbọ́, ati ìmọ kún ìwarere;


Ẹ máṣe fi buburu san buburu, tabi fi ẽbú san ẽbú; ṣugbọn kàka bẹ̃, ẹ mã súre; nitori eyi li a pè nyin si, ki ẹnyin ki o le jogún ibukún.


Nitori ninu rẹ̀ li a ti dá ohun gbogbo, ohun ti mbẹ li ọrun, ati ohun ti mbẹ li aiye, eyiti a ri, ati eyiti a kò ri, nwọn iba ṣe itẹ́, tabi oye, tabi ijọba, tabi ọla: nipasẹ rẹ̀ li a ti dá ohun gbogbo, ati fun u:


Nitori ṣíṣe eré ìdaraya ní èrè diẹ, ṣugbọn ìwa-bi-Ọlọrun li ère fun ohun gbogbo, o ni ileri ti aiye isisiyi ati ti eyi ti mbọ̀.


Ara kan ni mbẹ, ati Ẹmí kan, ani bi a ti pè nyin sinu ireti kan ti ipè nyin;


Li akotan, ará, ohunkohun ti iṣe õtọ, ohunkohun ti iṣe ọ̀wọ, ohunkohun ti iṣe titọ́, ohunkohun ti iṣe mimọ́, ohunkohun ti iṣe fifẹ, ohunkohun ti o ni irohin rere; bi ìwa titọ́ kan ba wà, bi iyìn kan ba si wà, ẹ mã gbà nkan wọnyi rò.


Jesu si wá, o si sọ fun wọn, wipe, Gbogbo agbara li ọrun ati li aiye li a fifun mi.


Ẹniti iṣe itanṣan ogo rẹ̀, ati aworan on tikararẹ, ti o si nfi ọ̀rọ agbara rẹ̀ mu ohun gbogbo duro, lẹhin ti o ti ṣe ìwẹnu ẹ̀ṣẹ, o joko li ọwọ́ ọtún Ọlánla li oke;


Awọn enia rẹ yio jẹ ọrẹ atinuwá li ọjọ ijade-ogun rẹ, ninu ẹwà ìwà-mimọ́: lati inu owurọ wá, iwọ ni ìri ewe rẹ.


Ẹnyin ti a npamọ́ nipa agbara Ọlọrun nipa igbagbọ́ si igbala, ti a mura lati fihàn ni igba ikẹhin.


Ani awa, ti o ti pè, kì iṣe ninu awọn Ju nikan, ṣugbọn ninu awọn Keferi pẹlu?


Obinrin oniwa-rere li ade ọkọ rẹ̀: ṣugbọn eyi ti ndojuti ni dabi ọyún ninu egungun rẹ̀.


Njẹ nisisiyi, ọmọbinrin mi máṣe bẹ̀ru; gbogbo eyiti iwọ wi li emi o ṣe fun ọ: nitori gbogbo agbajọ awọn enia mi li o mọ̀ pe obinrin rere ni iwọ iṣe.


Ọpọlọpọ awọn ọmọbinrin li o hùwa rere, ṣugbọn iwọ ta gbogbo wọn yọ.


Tani yio ri obinrin oniwà rere? nitoriti iye rẹ̀ kọja iyùn.


Nitõtọ laiṣe ani-ani mo si kà ohun gbogbo si òfo nitori itayọ ìmọ Kristi Jesu Oluwa mi: nitori ẹniti mo ti ṣòfo ohun gbogbo, mo si kà wọn si igbẹ́, ki emi ki o le jère Kristi,


Ati airekọja kún ìmọ; ati sũru kún airekọja; ati ìwa-bi-Ọlọrun kún sũru;


Nitori bi ẹnyin bá ni nkan wọnyi ti nwọn bá si pọ̀, nwọn kì yio jẹ ki ẹ ṣe ọ̀lẹ tabi alaileso ninu ìmọ Oluwa wa Jesu Kristi.


Nitorina, ará, ẹ tubọ mã ṣe aisimi lati sọ ìpe ati yiyàn nyin di dajudaju: nitori bi ẹnyin ba nṣe nkan wọnyi, ẹnyin kì yio kọsẹ lai.


Nitori lẹhin ti nwọn ba ti yọ tan kuro ninu ẽri aiye, nipa mimọ̀ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi, bi nwọn ba si tun fi ara kó o, ti a si ṣẹgun wọn, igbẹhin wọn a buru jù ti iṣaju lọ.


Ṣugbọn ẹ mã dàgba ninu õre-ọfẹ ati ninu ìmọ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi; ẹniti ogo wà fun nisisiyi ati titi lai. Amin.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan