Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




2 Johanu 1:6 - Bibeli Mimọ

6 Eyi si ni ifẹ, pe, ki awa ki o mã rìn nipa ofin rẹ̀. Eyi li ofin na, ani bi ẹ ti gbọ́ li àtetekọṣe, pe, ki ẹnyin ki o mã rìn ninu rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Èyí ni ìfẹ́, pé kí á máa gbé ìgbé-ayé gẹ́gẹ́ bí àwọn òfin Ọlọrun. Bí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀, òfin yìí ni pé kí ẹ máa rìn ninu ìfẹ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Èyí sì ni ìfẹ́, pé, kí àwa máa rin nípa òfin rẹ̀, èyí ni òfin náà, àní bí ẹ ti gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe, pé, kí ẹ̀yin rìn nínú rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




2 Johanu 1:6
14 Iomraidhean Croise  

Bi ẹnyin ba fẹran mi, ẹ ó pa ofin mi mọ́.


Ẹniti o ba li ofin mi, ti o ba si npa wọn mọ́, on li ẹniti ọ fẹràn mi: ẹniti o ba si fẹràn mi, a o fẹrán rẹ̀ lati ọdọ Baba mi wá, emi o si fẹràn rẹ̀, emi o si fi ara mi hàn fun u.


Jesu dahùn o si wi fun u pe, Bi ẹnikan ba fẹràn mi, yio pa ọ̀rọ mi mọ́: Baba mi yio si fẹran rẹ̀, awa o si tọ̀ ọ wá, a o si ṣe ibugbe wa pẹlu rẹ̀.


Bi ẹnyin ba pa ofin mi mọ́, ẹ o duro ninu ifẹ mi; gẹgẹ bi emi ti pa ofin Baba mi mọ́, ti mo si duro ninu ifẹ rẹ̀.


Ọrẹ́ mi li ẹnyin iṣẹ, bi ẹ ba ṣe ohun ti emi palaṣẹ fun nyin.


Lẹhin OLUWA Ọlọrun nyin ni ki ẹnyin ki o ma rìn, on ni ki ẹ si ma bẹ̀ru, ki ẹ si ma pa ofin rẹ̀ mọ́, ki ẹ si ma gbà ohùn rẹ̀ gbọ́, ki ẹ si ma sìn i, ki ẹ si ma faramọ́ ọ.


Ṣugbọn ẹnyin, ki eyini ki o mã gbe inu nyin, ti ẹnyin ti gbọ́ li àtetekọṣe. Bi eyiti ẹnyin ti gbọ́ li àtetekọṣe ba ngbe inu nyin, ẹnyin ó si duro pẹlu ninu Ọmọ ati ninu Baba.


Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba npa ofin rẹ̀ mọ́, lara rẹ̀ li a gbé mu ifẹ Ọlọrun pé nitõtọ. Nipa eyi li awa mọ̀ pe awa mbẹ ninu rẹ̀,


Ẹnyin olufẹ, ki iṣe ofin titun ni mo nkọwe rẹ̀ si nyin, ṣugbọn ofin atijọ ti ẹnyin ti ni li àtetekọṣe. Ofin atijọ ni ọ̀rọ na ti ẹnyin ti gbọ́.


Bi awa ba si mọ̀ pe o ngbọ́ ti wa, ohunkohun ti awa ba bère, awa mọ̀ pe awa rí ibere ti awa ti bère lọdọ rẹ̀ gbà.


Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, pe ki awa ki o pa ofin rẹ̀ mọ́: ofin rẹ̀ kò si nira.


Njẹ nisisiyi mo bẹ̀ ọ, obinrin ọlọlá, kì iṣe bi ẹnipe emi nkọwe ofin titun kan si ọ, bikọse eyi ti awa ti ni li àtetekọṣe, pe ki awa ki o fẹràn ara wa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan