Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




2 Johanu 1:2 - Bibeli Mimọ

2 Nitori otitọ ti ngbé inu wa, yio si mã ba wa gbé titi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 nítorí òtítọ́ tí ó ń gbé inú wa, tí ó sì wà pẹlu wa yóo wà títí lae.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 nítorí òtítọ́ tí ń gbé inú wa, yóò sì bá wa gbé títí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




2 Johanu 1:2
11 Iomraidhean Croise  

Emi ó si bère lọwọ Baba, on ó si fun nyin li Olutunu miran, ki o le mã ba nyin gbé titi lailai,


Bi ẹnyin ba ngbé inu mi, ti ọ̀rọ mi ba si ngbé inu nyin, ẹ ó bère ohunkohun ti ẹ ba fẹ, a o si ṣe e fun nyin.


Emi si nṣe ohun gbogbo nitori ti ihinrere, ki emi ki o le jẹ alabapin ninu rẹ̀ pẹlu nyin.


Nitori awa kò wãsu awa tikarawa, bikoṣe Kristi Jesu Oluwa; awa tikarawa si jẹ ẹrú nyin nitori Jesu.


Ẹ jẹ ki ọ̀rọ Kristi mã gbé inu nyin li ọ̀pọlọpọ ninu ọgbọ́n gbogbo; ki ẹ mã kọ́, ki ẹ si mã gbà ara nyin niyanju ninu psalmu, ati orin iyìn, ati orin ẹmí, ẹ mã fi ore-ọfẹ kọrin li ọkàn nyin si Oluwa.


Nigbati mo ba ranti igbagbọ́ ailẹtan ti mbẹ ninu rẹ, eyiti o kọ́ wà ninu Loide iya-nla rẹ, ati ninu Eunike iya rẹ; mo si gbagbọ pe, o mbẹ ninu rẹ pẹlu.


Nitorina emi ó mã mura lati mã mu nkan wọnyi wá si iranti nyin nigbagbogbo bi ẹnyin tilẹ ti mọ̀ wọn, ti ẹsẹ nyin si mulẹ ninu otitọ ti ẹnyin ni.


Bi awa ba wipe awa kò li ẹ̀ṣẹ, awa tàn ara wa jẹ, otitọ kò si si ninu wa.


Emi kọwe si nyin, ẹnyin baba, nitoriti ẹnyin ti mọ̀ ẹniti o wà li àtetekọṣe. Emi ti kọwe si nyin, ẹnyin ọdọmọkunrin, nitoriti ẹnyin li agbara, ti ọ̀rọ Ọlọrun si duro ninu nyin, ti ẹ si ṣẹgun ẹni buburu nì.


Aiye si nkọja lọ, ati ifẹkufẹ rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba nṣe ifẹ Ọlọrun ni yio duro lailai.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan