Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




2 Johanu 1:12 - Bibeli Mimọ

12 Bi mo ti ni ohun pupọ̀ lati kọwe si nyin, emi kò fẹ lo tákàdá ati tàdãwa. Ṣugbọn emi ni ireti lati tọ nyin wá ati lati ba nyin sọrọ lojukoju, ki ayọ̀ nyin ki o le kún.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Àwọn nǹkan tí mo fẹ́ ba yín sọ pọ̀, ṣugbọn n kò fẹ́ kọ ọ́ sinu ìwé. Mo ní ìrètí ati wá sọ́dọ̀ yín, kí á baà lè jọ sọ̀rọ̀ lojukooju, kí ayọ̀ wa lè di kíkún.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Bí mo tilẹ̀ ní ohun púpọ̀ láti ṣe alábápín pẹ̀lú yín, síbẹ̀ èmi kò fẹ́ lo ìwé ìkọ̀wé àti jẹ́lú ìkọ̀wé. Ṣùgbọ́n èmi ní ìrètí láti tọ̀ yín wá àti láti bá a yín sọ̀rọ̀ lójúkojú, kí ayọ̀ yín bá à le è kún.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




2 Johanu 1:12
15 Iomraidhean Croise  

On li emi mbá sọ̀rọ li ẹnu ko ẹnu, ati ni gbangba, ki si iṣe li ọ̀rọ ti o ṣe òkunkun; apẹrẹ OLUWA li on o si ri: njẹ nitori kili ẹnyin kò ṣe bẹ̀ru lati sọ̀rọ òdi si Mose iranṣẹ mi?


Nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin, ki ayọ̀ mi ki o le wà ninu nyin, ati ki ayọ̀ nyin ki o le kún.


Mo ni ohun pipọ lati sọ fun nyin pẹlu, ṣugbọn ẹ kò le gbà wọn nisisiyi.


Titi di isisiyi ẹ kò ti ibère ohunkohun li orukọ mi: ẹ bère, ẹ o si ri gbà, ki ayọ̀ nyin ki o le kún.


Ṣugbọn nisisiyi emi si mbọ̀ wá sọdọ rẹ, nkan wọnyi ni mo si nsọ li aiye, ki nwọn ki o le ni ayọ̀ mi ni kikun ninu awọn tikarawọn.


Ẹniti o ba ni iyawo ni ọkọ iyawo; ṣugbọn ọrẹ́ ọkọ iyawo ti o duro ti o si ngbohùn rẹ̀, o nyọ̀ gidigidi nitori ohùn ọkọ iyawo; nitorina ayọ̀ mi yi di kíkun.


Nigbakugba ti mo ba nlọ si Spania, ng ó tọ̀ nyin wá: nitori mo nireti pe emi o ri nyin li ọ̀na àjo mi, ati pe ẹ o mu mi já ọ̀na mi nibẹ̀ lati ọdọ nyin lọ, bi mo ba kọ kún fun ẹgbẹ nyin li apakan.


T'ọsan t'oru li emi njaìyà ati ri ọ, ti mo nranti omije rẹ, ki a le fi ayọ̀ kún mi li ọkàn;


Ati pẹlu, pese ìbuwọ̀ silẹ dè mi; nitori mo gbẹkẹle pe nipa adura nyin, a ó fi mi fun nyin.


Ṣugbọn emi mbẹ̀ nyin gidigidi si i lati mã ṣe eyi, ki a ba le tète fi mi fun nyin pada.


Ẹ mọ̀ pé a dá Timotiu arakunrin wa silẹ; bi o ba tete de, emi pẹlu rẹ̀ yio ri nyin.


Awa si kọwe nkan wọnyi si nyin, ki ayọ̀ nyin ki o le di kikún.


Nitorina bi mo ba de, emi o mu iṣẹ rẹ̀ ti o ṣe wá si iranti, ti o nsọ ọrọ buburu ati isọkusọ si wa: eyini kò si tẹ́ ẹ lọrùn, bẹ̃ni on tikararẹ̀ kò gbà awọn ará, awọn ti o si nfẹ gbà wọn, o ndá wọn lẹkun, o si nlé wọn jade kuro ninu ijọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan