Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 5:9 - Bibeli Mimọ

9 Ẹniti ki ẹnyin ki o kọ oju ija si pẹlu iduroṣinṣin ninu igbagbọ́, ki ẹnyin ki o mọ̀ pe ìya kanna ni awọn ara nyin ti mbẹ ninu aiye njẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Ẹ takò ó pẹlu igbagbọ tí ó dúró gbọningbọnin. Kí ẹ mọ̀ pé àwọn onigbagbọ ẹgbẹ́ yín ń jẹ irú ìyà kan náà níwọ̀n ìgbà tí wọ́n wà ninu ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Ẹ kọ ojú ìjà sí i pẹ̀lú ìdúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé ìyà kan náà ni àwọn ará yín tí ń bẹ nínú ayé ń jẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 5:9
24 Iomraidhean Croise  

Nitorina ẹ tẹriba fun Ọlọrun. Ẹ kọ oju ija si Èṣu, on ó si sá kuro lọdọ nyin.


Nwọn nmu awọn ọmọ-ẹhin li ọkàn le, nwọn ngbà wọn niyanju lati duro ni igbagbọ́, ati pe ninu ipọnju pipọ li awa o fi wọ̀ ijọba Ọlọrun.


Nitori inu eyi li a pè nyin si: nitori Kristi pẹlu jìya fun nyin, o fi apẹrẹ silẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mã tọ̀ ipasẹ rẹ̀:


Kò si idanwò kan ti o ti ibá nyin, bikoṣe irú eyiti o mọ niwọn fun enia: ṣugbọn olododo li Ọlọrun, ẹniti kì yio jẹ ki a dan nyin wò jù bi ẹnyin ti le gbà; ṣugbọn ti yio si ṣe ọna atiyọ pẹlu ninu idanwò na, ki ẹnyin ki o ba le gbà a.


Nitõtọ, gbogbo awọn ti o fẹ mã gbé igbé ìwa-bi-Ọlọrun ninu Kristi Jesu, yio farada inunibini.


Léke gbogbo rẹ̀, ẹ mu apata igbagbọ́, nipa eyiti ẹnyin ó le mã fi paná gbogbo ọfa iná ẹni ibi nì.


Ṣugbọn bi ẹnyin ba jìya nitori ododo, alafia ni: ẹ máṣe bẹru wọn, ki ẹ má si ṣe kọminu;


Awọn ẹni nipasẹ igbagbọ́ ti nwọn ṣẹgun ilẹ ọba, ti nwọn ṣiṣẹ ododo, ti nwọn gbà ileri, ti nwọn dí awọn kiniun li ẹnu,


Mã jà ìja rere ti igbagbọ́, di ìye ainipẹkun mu ninu eyiti a gbé pè ọ si, ti iwọ si ṣe ijẹwo rere niwaju ẹlẹri pupọ̀.


Ki a máṣe mu ẹnikẹni yẹsẹ nipa wahalà wọnyi: nitori ẹnyin tikaranyin mọ̀ pe a ti yàn wa sinu rẹ̀.


Bẹni ki ẹ má ṣe fi àye fun Èṣu.


A si fi aṣọ funfun fun gbogbo wọn; a si wi fun wọn pe, ki nwọn ki o simi di ìgba diẹ na, titi iye awọn iranṣẹ ẹlẹgbẹ ati arakunrin wọn ti a o pa bi wọn, yio fi pé.


Ṣugbọn niwọnbi ẹnyin ti jẹ alabapin ìya Kristi, ẹ mã yọ̀, ki ẹnyin ki o le yọ̀ ayọ̀ pipọ nigbati a ba fi ogo rẹ̀ hàn.


Ninu eyiti ẹnyin nyọ̀ pipọ, bi o tilẹ ṣe pe nisisiyi fun igba diẹ, niwọnbi o ti yẹ, a ti fi ọ̀pọlọpọ idanwo bà nyin ninu jẹ:


Nitoripe bi emi kò tilẹ si lọdọ nyin li ara, ṣugbọn emi mbẹ lọdọ nyin li ẹmí, mo nyọ̀, mo si nkiyesi eto nyin, ati iduroṣinṣin igbagbọ́ nyin ninu Kristi.


Nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin tẹlẹ̀, ki ẹnyin ki o le ni alafia ninu mi. Ninu aiye, ẹnyin o ni ipọnju; ṣugbọn ẹ tújuka; mo ti ṣẹgun aiye.


Mo si wi fun u pe, Oluwa mi, Iwọ li o le mọ̀. O si wi fun mi pe, Awọn wọnyi li o jade lati inu ipọnju nla, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn, nwọn si sọ wọn di funfun ninu ẹ̀jẹ Ọdọ-Agutan na.


Ṣugbọn mo ti gbadura fun ọ, ki igbagbọ́ rẹ ki o má yẹ̀; ati iwọ nigbati iwọ ba si yipada, mu awọn arakunrin rẹ li ọkàn le.


Emi Johanu, arakunrin nyin ati alabapin pẹlu nyin ninu wahala ati ijọba ati sũru ti mbẹ ninu Jesu, wà ninu erekuṣu ti a npè ni Patmo, nitori ọ̀rọ Ọlọrun, ati nitori ẹrí Jesu Kristi.


Emi ti jà ìja rere, emi ti pari ire-ije mi, emi ti pa igbagbọ́ mọ́:


Ṣugbọn bi ẹnyin ba wà li aisi ibawi, ninu eyiti gbogbo enia ti jẹ alabapin, njẹ ọmọ àle ni nyin, ẹ kì isi iṣe ọmọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan