Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 4:3 - Bibeli Mimọ

3 Nitori igba ti o ti kọja ti to fun ṣiṣe ifẹ awọn keferi, rinrìn ninu iwa wọ̀bia, ifẹkufẹ, ọti amupara, ìrède oru, kiko ẹgbẹ ọmuti, ati ìbọriṣa ti iṣe ohun irira.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Ní ìgbà kan rí ẹ ní anfaani tó láti ṣe àwọn ohun tí àwọn abọ̀rìṣà ń ṣe. Ẹ̀ ń hùwà wọ̀bìà, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ìmutípara, ayé ìjẹkújẹ, ìmukúmu ati ìbọ̀rìṣà tí ó jẹ́ èèwọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Nítorí ìgbà tí ó ti kọjá ti tó fún ṣíṣe ìfẹ́ àwọn aláìkọlà, rínrìn nínú ìwà wọ̀bìà, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ọtí àmupara, ìréde òru, kíkó ẹ̀gbẹ́ ọ̀mùtí, àti ìbọ̀rìṣà tí í ṣe ohun ìríra.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 4:3
30 Iomraidhean Croise  

Absalomu si fi aṣẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ki ẹnyin ki o ma kiyesi akoko ti ọti-waini yio mu ọkàn Amnoni dùn, emi o si wi fun nyin pe, Kọlu Amnoni; ki ẹ si pa a: ẹ má bẹ̀ru: ṣe emi li o fi aṣẹ fun nyin? ẹ ṣe giri, ki ẹ ṣe bi alagbara ọmọ.


O si ṣe ohun irira gidigidi ni titọ̀ oriṣa lẹhin, gẹgẹ bi gbogbo ohun ti awọn ara Amori ti ṣe, ti Oluwa ti le jade niwaju awọn ọmọ Israeli.


Nigbati Asa gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, ati asọtẹlẹ Odedi woli, o mu ara le, o si mu awọn ohun irira kuro lati inu gbo-gbo ilẹ Juda ati Benjamini, ati lati inu ilu ti o ti gbà lati oke Efraimu, o si tun pẹpẹ Oluwa ṣe, ti o wà niwaju iloro Oluwa.


Ṣugbọn awọn pẹlu ti ti ipa ọti-waini ṣìna, ati nipa ọti-lile nwọn ti ṣako; alufa ati wolĩ ti ṣìna nipa ọti-lile, ọti-waini mu wọn daradara, nwọn di aṣako nipa ọti-lile, nwọn ṣìna ninu iran, nwọn kọsẹ ni idajọ.


Egbe ni fun awọn ti ima dide ni kùtukutu, ki nwọn le ma lepa ọti lile; ti nwọn wà ninu rẹ̀ titi di alẹ, titi ọti-waini mu ara wọn gbona!


Awọn ti ngbe inu ibojì, ti nwọn si nwọ̀ ni ile awọn oriṣa, ti njẹ ẹran ẹlẹdẹ, omi-ẹran nkan irira si mbẹ ninu ohun-elò wọn;


Nigbana ni iwọ o wi fun wọn pe, Nitoripe awọn baba nyin ti kọ̀ mi silẹ, li Oluwa wi, ti nwọn si rìn tọ̀ ọlọrun miran lọ, ti nwọn si sìn wọn, ti nwọn si foribalẹ fun wọn, ti nwọn kọ̀ mi silẹ, ti nwọn kò pa ofin mi mọ;


Li atetekọṣe, emi o san ẹsan ìwa buburu mejeji wọn, ani, ẹ̀ṣẹ wọn nitoriti nwọn ti bà ilẹ mi jẹ, nwọn ti fi okú ati ohun ẹgbin ati irira wọn kún ilẹ ini mi.


Iwọ o si wi fun awọn ọlọ̀tẹ, ani fun ile Israeli, pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; ki gbogbo ohun-irira nyin to fun nyin, ile Israeli,


Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Ki o to fun nyin, ẹnyin olori Israeli: ẹ mu ìwa ipa irẹ́jẹ kuro, ki ẹ si mu idajọ ati ododo ṣẹ, mu ilọ́nilọwọgbà nyin kuro lọdọ awọn enia mi, ni Oluwa Ọlọrun wi.


Olè, ojukòkoro, iwa buburu, itanjẹ, wọ̀bia, oju buburu, isọrọ-odi, igberaga, iwère:


Pẹlupẹlu igba aimọ̀ yi li Ọlọrun ti foju fò da; ṣugbọn nisisiyi o paṣẹ fun gbogbo enia nibi gbogbo lati ronupiwada:


Jẹ ki a mã rìn ìrin titọ, bi li ọsán; kì iṣe ni iréde-oru ati ni imutipara, kì iṣe ni iwa-ẽri ati wọbia, kì iṣe ni ìja ati ilara.


Ẹnyin mọ̀ pe nigbati ẹnyin jẹ Keferi, a fà nyin lọ sọdọ awọn odi oriṣa, lọnakọna ti a fa nyin.


Bẹ̃ li awọn ẹlomiran ninu nyin si ti jẹ rí: ṣugbọn a ti wẹ̀ nyin nù, ṣugbọn a ti sọ nyin di mimọ́, ṣugbọn a ti da nyin lare li orukọ Jesu Kristi Oluwa, ati nipa Ẹmí Ọlọrun wa.


Ati nigbati mo ba si pada de, ki Ọlọrun mi má ba rẹ̀ mi silẹ loju nyin, ati ki emi ki o má bã sọkun nitori ọpọlọpọ awọn ti o ti ṣẹ̀ na, ti nwọn kò si ronupiwada ẹ̀ṣẹ ìwa-ẽri, ati ti àgbere, ati ti wọ̀bia ti nwọn ti dá.


Njẹ awọn iṣẹ ti ara farahàn, ti iṣe wọnyi; panṣaga, àgbere, ìwa-ẽri, wọ̀bia,


Arankàn, ipania, imutipara, iréde-oru, ati iru wọnni: awọn ohun ti mo nwi fun nyin tẹlẹ, gẹgẹ bi mo ti wi fun nyin tẹlẹ rí pe, awọn ti nṣe nkan bawọnni kì yio jogún ijọba Ọlọrun.


Ẹ má si ṣe mu waini li amupara, ninu eyiti rudurudu wà; ṣugbọn ẹ kún fun Ẹmí;


Kì iṣe ni ṣiṣe ifẹkufẹ, gẹgẹ bi awọn Keferi ti kò mọ̀ Ọlọrun:


Nitori awa pẹlu ti jẹ were nigbakan rí, alaigbọran aṣako, ẹniti nsin onirũru ifẹkufẹ ati adùn aiye, a wà ninu arankàn ati ilara, a jẹ ẹni irira, a si nkorira awọn ọmọnikeji wa.


Bi awọn eleti ọmọ, li aifi ara nyin dáṣà bi ifẹkufẹ atijọ ninu aimọ̀ nyin:


Nitori awọn enia kan mbẹ ti nwọn nyọ́ wọle, awọn ẹniti a ti yàn lati igbà atijọ si ẹbi yi, awọn alaiwa-bi-Ọlọrun, ti nyi ore-ọfẹ Ọlọrun wa pada si wọbia, ti nwọn si nsẹ́ Oluwa wa kanṣoṣo na, ani Jesu Kristi Oluwa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan