Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 3:9 - Bibeli Mimọ

9 Ẹ máṣe fi buburu san buburu, tabi fi ẽbú san ẽbú; ṣugbọn kàka bẹ̃, ẹ mã súre; nitori eyi li a pè nyin si, ki ẹnyin ki o le jogún ibukún.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Ẹ má fi burúkú gbẹ̀san burúkú, tabi kí ẹ fi àbùkù kan ẹni tí ó bá fi àbùkù kàn yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa sọ̀rọ̀ wọn ní rere ni. Irú ìwà tí a ní kí ẹ máa hù nìyí, kí ẹ lè jogún ibukun tí Ọlọrun ṣèlérí fun yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, tàbí fi èébú san èébú: ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre; nítorí èyí ni a pè yín sí, kí ẹ̀yin lè jogún ìbùkún.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 3:9
26 Iomraidhean Croise  

Nigbana ni Josefu paṣẹ ki nwọn fi ọkà kún inu àpo wọn, ki nwọn si mú owo olukuluku pada sinu àpo rẹ̀, ki nwọn ki o si fun wọn li onjẹ ọ̀na; bayi li o si ṣe fun wọn.


Ẹnikẹni ti o ba fi ibi san ire, ibi kì yio kuro ninu ile rẹ̀.


Iwọ máṣe wipe, Emi o gbẹsan ibi; ṣugbọn duro de Oluwa, on o si gbà ọ.


Ẹnikẹni ti o mu olododo ṣìna si ọ̀na buburu, ontikararẹ̀ yio bọ si iho, ṣugbọn aduro-ṣinṣin yio jogun ohun rere.


Ati gbogbo ẹniti o fi ile silẹ, tabi arakunrin, tabi arabinrin, tabi baba, tabi iya, tabi aya, tabi ọmọ, tabi ilẹ, nitori orukọ mi, nwọn o ri ọ̀rọrun gbà, nwọn o si jogún ìye ainipẹkun.


Nigbana li Ọba yio wi fun awọn ti o wà li ọwọ́ ọtun rẹ pe, Ẹ wá, ẹnyin alabukun-fun Baba mi, ẹ jogún ijọba, ti a ti pèse silẹ fun nyin lati ọjọ ìwa:


Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹ máṣe kọ̀ ibi; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba gbá ọ li ẹrẹkẹ ọtún, yi ti òsi si i pẹlu.


Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ẹ sure fun awọn ẹniti o nfi nyin ré, ẹ ṣõre fun awọn ti o korira nyin, ki ẹ si gbadura fun awọn ti nfi arankàn ba nyin lò, ti nwọn nṣe inunibini si nyin;


Bi o si ti njade bọ̀ si ọ̀na, ẹnikan nsare tọ̀ ọ wá, o si kunlẹ fun u, o bi i lẽre, wipe, Olukọni rere, kili emi o ṣe ti emi o fi le jogún ìye ainipẹkun?


Si kiyesi i, amofin kan dide, o ndán a wò, o ni, Olukọni, kili emi o ṣe ki emi ki o le jogún iyè ainipẹkun?


Ijoye kan si bère lọwọ rẹ̀, wipe, Olukọni rere, kili emi o ṣe ti emi o fi jogún iye ainipẹkun?


Ẹ mã súre fun awọn ti nṣe inunibini si nyin: ẹ mã sure, ẹ má si ṣepè.


Ẹ máṣe fi buburu san buburu fun ẹnikẹni. Ẹ mã pèse ohun ti o tọ́ niwaju gbogbo enia.


Awa si mọ̀ pe ohun gbogbo li o nṣiṣẹ pọ̀ si rere fun awọn ti o fẹ Ọlọrun, ani fun awọn ẹniti a pè gẹgẹ bi ipinnu rẹ̀.


Awọn ti o si ti yàn tẹlẹ, awọn li o si ti pè: awọn ẹniti o si ti pè, awọn li o si ti dalare: awọn ẹniti o si ti dalare, awọn li o si ti ṣe logo.


Ki ibukún Abrahamu ki o le wá sori awọn Keferi nipa Kristi Jesu; ki awa ki o le gbà ileri Ẹmí nipa igbagbọ́.


Ẹ mã ṣore fun ọmọnikeji nyin, ẹ ni iyọ́nu, ẹ mã darijì ara nyin, gẹgẹ bi Ọlọrun ninu Kristi ti darijì nyin.


Ẹ kiyesi i, ki ẹnikẹni ki o máṣe fi buburu san buburu fun ẹnikẹni; ṣugbọn ẹ mã lepa eyi ti iṣe rere nigbagbogbo, lãrin ara nyin, ati larin gbogbo enia.


Nitori ẹnyin mọ̀ pe lẹhinna ní ani nigbati o fẹ lati jogun ibukun na, a kọ̀ ọ (nitori kò ri aye ironupiwada) bi o tilẹ ti fi omije wá a gidigidi.


Nitõtọ ni bibukún emi o bukún fun ọ, ati ni bibisi emi o mu ọ bisi i.


Ọlọrun ore-ọfẹ gbogbo, ti o ti pè nyin sinu ogo rẹ̀ ti kò nipẹkun ninu Kristi Jesu, nigbati ẹnyin ba ti jìya diẹ, On tikarãrẹ, yio si ṣe nyin li aṣepé, yio fi ẹsẹ nyin mulẹ, yio fun nyin li agbara, yio fi idi nyin kalẹ.


Oluwa má jẹ ki emi nà ọwọ́ mi si ẹni-àmi-ororo Oluwa: njẹ, emi bẹ ọ, mu ọ̀kọ na ti mbẹ nibi timtim rẹ̀, ati igo omi ki a si ma lọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan