Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 3:4 - Bibeli Mimọ

4 Ṣugbọn ki o jẹ ti ẹniti o farasin li ọkàn, ninu ọ̀ṣọ́ aidibajẹ ti ẹmí irẹlẹ ati ẹmí tutù, eyiti iṣe iyebiye niwaju Ọlọrun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Ṣugbọn kí ẹwà yín jẹ́ ti ọkàn tí kò hàn sóde, ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ ati ìwà pẹ̀lẹ́. Èyí ni ẹwà tí kò lè ṣá, èyí tí ó ṣe iyebíye lójú Ọlọrun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni tí ó fi ara sin ní ọkàn, nínú ọ̀ṣọ́ àìdíbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí tútù, èyí tí i ṣe iyebíye níwájú Ọlọ́run.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 3:4
40 Iomraidhean Croise  

Nitõtọ emi mu ọkàn mi simi, mo si mu u dakẹjẹ, bi ọmọ ti a ti ọwọ iya rẹ̀ gbà li ẹnu ọmu: ọkàn mi ri bi ọmọ ti a já li ẹnu ọmu.


Oluwa gbé awọn onirẹlẹ soke: o rẹ̀ awọn enia buburu si ilẹyilẹ.


Nitori ti Oluwa ṣe inudidùn si awọn enia rẹ̀; yio fi igbala ṣe awọn onirẹlẹ li ẹwà.


Onirẹlẹ ni yio tọ́ li ọ̀na ti ó tọ́, ati onirẹlẹ ni yio kọ́ li ọ̀na rẹ̀.


Ti ogo ti ogo li ọmọbinrin ọba na ninu ile: iṣẹ wura ọnà abẹrẹ li aṣọ rẹ̀.


Kiyesi i, iwọ fẹ otitọ ni inu: ati niha ìkọkọ ni iwọ o mu mi mọ̀ ọgbọ́n.


Ṣugbọn yio fi ododo ṣe idajọ talakà, yio si fi otitọ ṣe idajọ fun awọn ọlọkàn tutù aiye; on o si fi ọgọ ẹnu rẹ̀ lu aiye, on o si fi ẽmi ète rẹ̀ lu awọn enia buburu pa.


Ayọ̀ awọn onirẹlẹ yio bí si i ninu Oluwa, ati inu awọn talaka ninu awọn enia yio si dùn ninu Ẹni-Mimọ Israeli.


Nitori bayi li Ẹni-giga, ati ẹniti a gbéga soke sọ, ti ngbe aiyeraiye, orukọ ẹniti ijẹ Mimọ́, emi ngbe ibi giga ati mimọ́, ati inu ẹniti o li ẹmi irobinujẹ on irẹlẹ pẹlu, lati mu ẹmi awọn onirẹlẹ sọji, ati lati mu ọkàn awọn oniròbinujẹ sọji.


ẸMI Oluwa Jehofah mbẹ lara mi: nitori o ti fi ami ororo yàn mi lati wãsu ihin-rere fun awọn òtoṣi; o ti rán mi lati ṣe awotán awọn onirobinujẹ ọkàn, lati kede idasilẹ fun awọn igbekùn, ati iṣisilẹ tubu fun awọn ondè.


Ọ̀rọ ti Jeremiah woli paṣẹ fun Seraiah, ọmọ Neriah, ọmọ Maaseiah, nigbati o nlọ niti Sedekiah, ọba Judah, si Babeli li ọdun kẹrin ijọba rẹ̀. Seraiah yi si ni ijoye ibudo.


Ẹ gbà àjaga mi si ọrùn nyin, ki ẹ si mã kọ́ ẹkọ́ lọdọ mi; nitori oninu tutu ati onirẹlẹ ọkan li emi; ẹnyin o si ri isimi fun ọkàn nyin.


Ẹ sọ fun ọmọbinrin Sioni pe, Kiyesi i, Ọba rẹ mbọ̀ wá sọdọ rẹ, o ni irẹlẹ, o joko lori kẹtẹkẹtẹ, ati lori ọmọ kẹtẹkẹtẹ.


Iwọ afọju Farisi, tetekọ fọ̀ eyi ti mbẹ ninu ago ati awopọkọ́ mọ́ na, ki ode wọn ki o le mọ́ pẹlu.


Alabukún-fun li awọn ọlọkàn-tutù: nitori nwọn o jogún aiye.


Ẹnyin alaimoye, ẹniti o ṣe eyi ti mbẹ lode, on kọ́ ha ṣe eyi ti mbẹ ninu pẹlu?


O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li awọn ti ndare fun ara nyin niwaju enia; ṣugbọn Ọlọrun mọ̀ ọkàn nyin: nitori eyi ti a gbé niyin lọdọ enia, irira ni niwaju Ọlọrun.


Nwọn si pa ogo Ọlọrun ti kì idibajẹ dà, si aworan ere enia ti idibajẹ, ati ti ẹiyẹ, ati ẹranko ẹlẹsẹ mẹrin, ati ohun ti nrakò.


Ṣugbọn Ju ti inu ni Ju, ati ikọla ti ọkàn, ninu ẹmi ni, kì iṣe ti ode ara; iyìn ẹniti kò si lọdọ enia, bikoṣe lọdọ Ọlọrun.


Nitori awa mọ eyi pe, a kàn ogbologbo ọkunrin wa mọ agbelebu pẹlu rẹ̀, ki a le pa ara ẹ̀ṣẹ run, ki awa maṣe sìn ẹ̀ṣẹ mọ́.


Inu mi sá dùn si ofin Ọlọrun nipa ẹni ti inu:


ṢUGBỌN emi Paulu tikarami fi inu tutù ati ìwa pẹlẹ Kristi bẹ̀ nyin, emi ẹni irẹlẹ loju nyin nigbati mo wà larin nyin, ṣugbọn nigbati emi kò si, mo di ẹni igboiya si nyin.


Nitori eyi ni ãrẹ̀ kò ṣe mu wa; ṣugbọn bi ọkunrin ti ode wa ba nparun, sibẹ ọkunrin ti inu wa ndi titun li ojojumọ́.


Ìwa tutù, ati ikora-ẹni-nijanu: ofin kan kò lodi si iru wọnni.


Pẹlu irẹlẹ gbogbo ati inu tutù, pẹlu ipamọra, ẹ mã fi ifẹ farada a fun ẹnikeji nyin;


Nitorina, bi ayanfẹ Ọlọrun, ẹni mimọ́ ati olufẹ, ẹ gbé ọkàn ìyọ́nu wọ̀, iṣeun, irẹlẹ, inu tutù, ipamọra;


Nitori ẹnyin ti kú, a si fi ìye nyin pamọ́ pẹlu Kristi ninu Ọlọrun.


Ati pe ki ẹnyin ki o mã dù u gidigidi lati gbé jẹ, lati mã gbọ ti ara nyin, ki ẹ mã fi ọwọ́ nyin ṣiṣẹ, gẹgẹ bi awa ti paṣẹ fun nyin;


Njẹ irú awọn ẹni bẹ̃ li awa npaṣẹ fun, ti a si nrọ̀ ninu Oluwa Jesu Kristi, pe ki nwọn ki o mã fi ìwa pẹlẹ ṣiṣẹ, ki nwọn ki o si mã jẹ onjẹ awọn tikarawọn.


Fun awọn ọba, ati gbogbo awọn ti o wà ni ipo giga; ki a le mã lo aiye wa ni idakẹjẹ ati pẹlẹ ninu gbogbo ìwa-bi-Ọlọrun ati ìwa agbà.


Ẹniti yio mã kọ́ awọn aṣodi pẹlu iwa tutu; boya Ọlọrun le fun wọn ni ironupiwada si imọ otitọ;


Ki nwọn má sọrọ ẹnikẹni ni ibi, ki nwọn má jẹ onija, bikoṣe ẹni pẹlẹ, ki nwọn mã fi ìwa tutù gbogbo han si gbogbo enia.


Nitorina ẹ fi gbogbo ẽri ati buburu aṣeleke lelẹ li apakan, ki ẹ si fi ọkàn tutù gbà ọ̀rọ na ti a gbin, ti o le gbà ọkàn nyin là.


Bi a ti tun nyin bi, kì iṣe lati inu irú ti idibajẹ wá, bikoṣe eyiti ki idibajẹ, nipa ọ̀rọ Ọlọrun ti mbẹ lãye ti o si duro.


Ṣugbọn ẹ bọ̀wọ fun Kristi bi Oluwa lọkan nyin: ki ẹ si mura tan nigbagbogbo lati dá olukuluku lohùn ti mbere ireti ti o mbẹ ninu nyin, ṣugbọn pẹlu ọkàn tutù ati ìbẹru.


Ṣugbọn Oluwa wi fun Samueli pe, máṣe wo oju rẹ̀, tabi giga rẹ̀; nitoripe emi kọ̀ ọ: nitoriti Oluwa kì iwò bi enia ti nwò; enia a ma wò oju, Oluwa a ma wò ọkàn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan