Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 3:3 - Bibeli Mimọ

3 Ọṣọ́ ẹniti ki o má jẹ ọṣọ́ ode, ti irun didì, ati ti wura lilo, tabi ti aṣọ wiwọ̀;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Ẹwà yín kò gbọdọ̀ jẹ́ ti òde ara nìkan bíi ti irun-dídì, ati nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà tí ẹ kó sára ati aṣọ-ìgbà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Kí ọ̀ṣọ́ yín má ṣe jẹ́ ọ̀ṣọ́ òde, tí irun dídì, àti wúrà lílò, tàbí ti aṣọ wíwọ̀;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 3:3
22 Iomraidhean Croise  

O si ṣe, bi awọn ibakasiẹ ti mu omi tan, ni ọkunrin na mu oruka wurà àbọ ìwọn ṣekeli, ati jufù meji fun ọwọ́ rẹ̀, ti ìwọn ṣekeli wurà mẹwa;


Emi si bi i, mo si wipe, Ọmọbinrin tani iwọ iṣe? o si wipe, Ọmọbinrin Betueli, ọmọ Nahori, ti Milka bí fun u: emi si fi oruka si i ni imu, ati jufù si ọwọ́ rẹ̀.


Iranṣẹ na si yọ ohun èlo fadaka, ati èlo wurà jade, ati aṣọ, o si fi wọn fun Rebeka: o si fi ohun iyebiye pẹlu fun arakunrin rẹ̀ ati fun iya rẹ̀.


Nigbati Jehu si de Jesreeli, Jesebeli gbọ́; on si le tìrõ, o si ta ori rẹ̀, o si yọju wode ni fèrese.


O si ṣe li ọjọ kẹta, ni Esteri wọ̀ aṣọ ayaba rẹ̀, o si duro ni àgbala ile ọba ti o wà ninu, lọgangan ile ọba: ọba si joko lori ìtẹ ijọba rẹ̀ ni ile ọba, ti o kọjusi ẹnu-ọ̀na ile na.


Awọn ọmọbinrin awọn alade wà ninu awọn ayanfẹ rẹ: li ọwọ ọtún rẹ li ayaba na gbe duro ninu wura Ofiri.


Olukuluku obinrin ni yio si bère ohun-èlo fadaka, ati ohun-èlo wurà, ati aṣọ, lọwọ aladugbo rẹ̀, ati lọwọ ẹniti o nṣe atipo ninu ile rẹ̀: ẹnyin o si fi wọn si ara awọn ọmọkunrin nyin, ati si ara awọn ọmọbinrin nyin: ẹnyin o si kó ẹrù awọn ara Egipti.


Aaroni si wi fun wọn pe, Ẹ kán oruka wurà ti o wà li eti awọn aya nyin, ati ti awọn ọmọkunrin nyin, ati ti awọn ọmọbinrin nyin, ki ẹ si mú wọn tọ̀ mi wá.


Nigbati awọn enia na si gbọ́ ihin buburu yi, nwọn kãnu: enia kan kò si wọ̀ ohun ọṣọ́ rẹ̀.


Nwọn si wá, ati ọkunrin ati obinrin, iye awọn ti ọkàn wọn fẹ́, nwọn si mú jufù wá, ati oruka-eti, ati oruka-àmi, ati ilẹkẹ wurà, ati onirũru ohun ọṣọ́ wurà; ati olukuluku enia ti o nta ọrẹ, o ta ọrẹ wurà fun OLUWA.


O si fi idẹ ṣe agbada na, o si fi idẹ ṣe ẹsẹ̀ rẹ̀, ti awojiji ẹgbẹ awọn obinrin ti npejọ lati sìn li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.


JI! ji! gbe agbara rẹ wọ̀, iwọ Sioni; gbe aṣọ ogo rẹ wọ̀, iwọ Jerusalemu, ilu mimọ́: nitori lati igbayi lọ, alaikọla on alaimọ́ kì yio wọ̀ inu rẹ mọ.


Emi o yọ̀ gidigidi ninu Oluwa, ọkàn mi yio yọ̀ ninu Ọlọrun mi; nitori o ti fi agbáda wọ̀ mi, o ti fi aṣọ ododo bò mi, gẹgẹ bi ọkọ iyawó ti iṣe ara rẹ̀ lọṣọ́, ati bi iyawó ti ifi ohun ọṣọ́ ṣe ara rẹ̀ lọṣọ́.


Wundia le gbagbe ohun ọṣọ rẹ̀, tabi iyawo ọjá-ọṣọ rẹ̀? ṣugbọn enia mi ti gbagbe mi li ọjọ ti kò ni iye.


Ati iwọ, ẹniti o di ijẹ tan, kini iwọ o ṣe? Iwọ iba wọ ara rẹ ni aṣọ òdodó, iwọ iba fi wura ṣe ara rẹ lọṣọ, iwọ iba fi tirõ kun oju rẹ: lasan ni iwọ o ṣe ara rẹ daradara, awọn ayanfẹ rẹ yio kọ̀ ọ silẹ, nwọn o wá ẹmi rẹ.


Ati pẹlupẹlu, ti pe ẹnyin ranṣẹ pè awọn ọkunrin lati okẽre wá, sọdọ awọn ti a ranṣẹ pè; si kiyesi i, nwọn de: fun ẹniti iwọ wẹ̀ ara rẹ, ti o si le tirõ, ti o si fi ohun ọṣọ́ ṣe ara rẹ li ọṣọ́.


Ki ẹ má si da ara nyin pọ̀ mọ́ aiye yi: ṣugbọn ki ẹ parada lati di titun ni iro-inu nyin, ki ẹnyin ki o le ri idi ifẹ Ọlọrun, ti o dara, ti o si ṣe itẹwọgbà, ti o si pé.


Nigbati nwọn ba nwò ìwa rere ti on ti ẹ̀ru nyin:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan