Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 3:2 - Bibeli Mimọ

2 Nigbati nwọn ba nwò ìwa rere ti on ti ẹ̀ru nyin:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 nígbà tí wọ́n bá ṣe akiyesi ìwà mímọ́ ati ìwà ọmọlúwàbí yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Nígbà tí wọ́n bá ń wo ìwà rere pẹ̀lú ẹ̀rù yín:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 3:2
13 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn ki olukuluku nyin ki o fẹran aya rẹ̀ bẹ̃ gẹgẹ bi on tikararẹ̀; ki aya ki o si bẹru ọkọ rẹ̀.


Ẹnyin ọmọ-ọdọ, ẹ mã gbọ ti awọn oluwa nyin nipa ti ara, pẹlu ibẹru ati iwarìri, ni otitọ ọkàn nyin, bi ẹnipe si Kristi;


Kìki ki ẹ sá jẹ ki ìwa-aiye nyin ki o mã ri gẹgẹ bi ihinrere Kristi: pe yala bi mo tilẹ wá wò nyin, tabi bi emi kò si, ki emi ki o le mã gburó bi ẹ ti nṣe, pe ẹnyin duro ṣinṣin ninu Ẹmí kan, ẹnyin jùmọ njijakadi nitori igbagbọ́ ihinrere, pẹlu ọkàn kan;


Nitori ilu-ibilẹ wa mbẹ li ọrun: lati ibiti awa pẹlu gbé nfojusọna fun Olugbala, Jesu Kristi Oluwa:


Ẹnyin ọmọ-ọdọ, ẹ gbọ ti awọn oluwa nyin nipa ti ara li ohun gbogbo; kì iṣe ni arojuṣe, bi awọn alaṣewù enia; ṣugbọn ni otitọ inu, ni ibẹ̀ru Ọlọrun:


Máṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o gàn ewe rẹ; ṣugbọn ki iwọ ki o jẹ apẹrẹ fun awọn ti o gbagbọ́, ninu ọ̀rọ, ninu ìwa hihu, ninu ifẹ, ninu ẹmí, ninu igbagbọ́, ninu ìwa mimọ́.


Ṣugbọn gẹgẹ bi Ẹni ti o pè nyin ti jẹ mimọ́, bẹ̃ni ki ẹnyin na si jẹ mimọ́ ninu ìwa nyin gbogbo:


Ki ìwa nyin larin awọn Keferi kí o dara; pe, bi nwọn ti nsọ̀rọ nyin bi oluṣe buburu, nipa iṣẹ rere nyin, ti nwọn o mã kiyesi, ki nwọn ki o le mã yìn Ọlọrun logo li ọjọ ìbẹwo.


BẸ̃ gẹgẹ, ẹnyin aya, ẹ mã tẹriba fun awọn ọkọ nyin; pe, bi ẹnikẹni bá tilẹ nṣe aigbọran si ọ̀rọ na, ki a lè jere wọn li aisọrọ nipa ìwa awọn aya wọn,


Ọṣọ́ ẹniti ki o má jẹ ọṣọ́ ode, ti irun didì, ati ti wura lilo, tabi ti aṣọ wiwọ̀;


Njẹ bi gbogbo nkan wọnyi yio ti yọ́ nì, irú enia wo li ẹnyin iba jẹ ninu ìwa mimọ́ gbogbo ati ìwa-bi-Ọlọrun,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan