Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 2:2 - Bibeli Mimọ

2 Bi ọmọ-ọwọ titun, ki ẹ mã fẹ wàra ti Ẹmí na eyiti kò li ẹ̀tan, ki ẹnyin ki o le mã ti ipasẹ rẹ̀ dàgba si igbala,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Ẹ ṣe bí ọmọ-ọwọ́ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, tí òùngbẹ wàrà gidi ti ẹ̀mí ń gbẹ, kí ó lè mu yín dàgbà fún ìgbàlà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Bí ọmọ ọwọ́ tuntun, kí ẹ máa fẹ́ wàrà ti Ẹ̀mí, èyí tí kò lẹ́tàn, kí ẹ̀yin lè máa tipasẹ̀ rẹ̀ dàgbà sí ìgbàlà,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 2:2
21 Iomraidhean Croise  

Lõtọ ile mi kò ri bẹ niwaju Ọlọrun, ṣugbọn o ti ba mi da majẹmu ainipẹkun, ti a tunṣe ninu ohun gbogbo, ti a si pamọ: nitoripe gbogbo eyi ni igbala mi, ati gbogbo ifẹ mi, ile mi kò le ṣe ki o ma dagbà?


Olododo pẹlu yio di ọ̀na rẹ̀ mu, ati ọlọwọ mimọ́ yio ma lera siwaju.


Ṣugbọn ipa-ọ̀na awọn olõtọ dabi titàn imọlẹ, ti o ntàn siwaju ati siwaju titi di ọsangangan.


Emi o dabi ìri si Israeli: on o tanná bi eweko lili; yio si ta gbòngbo rẹ̀ bi Lebanoni.


Awọn ti o ngbe abẹ ojiji rẹ̀ yio padà wá; nwọn o sọji bi ọkà: nwọn o si tanná bi àjara: õrun rẹ̀ yio dabi ọti-waini ti Lebanoni.


Nigbana li awa o mọ̀, bi a ba tẹramọ́ ati mọ̀ Oluwa: ati pèse ijadelọ rẹ̀ bi owùrọ: on o si tọ̀ wa wá bi ojò: bi arọ̀kuro ati akọrọ̀ òjo si ilẹ.


Ṣugbọn Õrùn ododo yio là, ti on ti imularada ni iyẹ́-apá rẹ̀, fun ẹnyin ti o bẹ̀ru orukọ mi; ẹnyin o si jade lọ, ẹnyin o si ma dagba bi awọn ẹgbọrọ malu inu agbo.


O si wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, bikoṣepe ẹnyin ba pada, ki ẹ si dabi awọn ọmọ kekere, ẹnyin kì yio le wọle ijọba ọrun.


Ṣugbọn Jesu ni, Jọwọ awọn ọmọ kekere, ẹ má si ṣe da wọn lẹkun ati wá sọdọ mi; nitori ti irú wọn ni ijọba ọrun.


Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti kò ba gbà ijọba Ọlọrun bi ọmọ kekere, kì yio le wọ̀ inu rẹ̀ bi o ti wù o ri.


Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti kò ba gbà ijọba Ọlọrun bi ọmọ kekere, kì yio wọ̀ inu rẹ̀ bi o ti wù ki o ri.


Njẹ a fi baptismu sinu ikú sin wa pọ̀ pẹlu rẹ̀: pe gẹgẹ bi a ti jí Kristi dide kuro ninu okú nipa ogo Baba bẹ̃ni ki awa pẹlu ki o mã rìn li ọtun ìwa.


Ará, ẹ máṣe jẹ ọmọde ni oye: ṣugbọn ẹ jẹ ọmọde li arankan, ṣugbọn ni oye ki ẹ jẹ agba.


Ninu ẹniti gbogbo ile na, ti a nkọ ṣọkan pọ, ndagbà soke ni tẹmpili mimọ́ ninu Oluwa:


Ṣugbọn ki a mã sọ otitọ ni ifẹ, ki a le mã dàgbasoke ninu rẹ̀ li ohun gbogbo, ẹniti iṣe ori, ani Kristi:


Iṣẹ wa ni lati mã dupẹ lọwọ Ọlọrun nigbagbogbo nitori nyin, ará, ani gẹgẹ bi o ti yẹ, nitoripe igbagbọ́ nyin ndàgba gidigidi, ati ifẹ olukuluku nyin gbogbo si ara nyin ndi pupọ;


Bi a ti tun nyin bi, kì iṣe lati inu irú ti idibajẹ wá, bikoṣe eyiti ki idibajẹ, nipa ọ̀rọ Ọlọrun ti mbẹ lãye ti o si duro.


Ṣugbọn ẹ mã dàgba ninu õre-ọfẹ ati ninu ìmọ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi; ẹniti ogo wà fun nisisiyi ati titi lai. Amin.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan