Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 1:4 - Bibeli Mimọ

4 Sinu ogún aidibajẹ, ati ailabawọn, ati eyi ti kì iṣá, ti a ti fi pamọ́ li ọrun dè nyin,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Ó fún wa ni ogún ainipẹkun, ogún tí kò lè díbàjẹ́, tí kò lè ṣá, tí a ti fi pamọ́ fun yín ní ọ̀run.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 àti sínú ogún àìdíbàjẹ́, àti àìlábàwọ́n, àti èyí tí kì í ṣá, tí a ti fi pamọ́ ni ọ̀run dè yin,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 1:4
27 Iomraidhean Croise  

Ore rẹ ti tobi to, ti iwọ fi ṣura dè awọn ti o bẹru rẹ: ore ti iwọ ti ṣe fun awọn ti o gbẹkẹle ọ niwaju awọn ọmọ enia!


On ni yio yàn ilẹ-ini wa fun wa, ọlá Jakobu, ẹniti o fẹ.


Nitori gẹgẹ bi awọn ọrun titun, ati aiye titun, ti emi o ṣe, yio ma duro niwaju mi, bẹ̃ni iru-ọmọ rẹ ati orukọ rẹ yio duro, li Oluwa wi.


Ati lẹba odò ni eti rẹ̀, ni ihà ihin ati ni ihà ọhun, ni gbogbo igi jijẹ yio hù, ti ewe rẹ̀ kì yio rọ, ti eso rẹ̀ kì yio si run: yio ma so eso titun rẹ̀ li oṣù rẹ̀, nitori omi wọn lati ibi mimọ́ ni nwọn ti ntú jade: eso rẹ̀ yio si jẹ fun jijẹ, ati ewe rẹ̀ fun imunilaradá.


Nigbana li Ọba yio wi fun awọn ti o wà li ọwọ́ ọtun rẹ pe, Ẹ wá, ẹnyin alabukun-fun Baba mi, ẹ jogún ijọba, ti a ti pèse silẹ fun nyin lati ọjọ ìwa:


Bi o si ti njade bọ̀ si ọ̀na, ẹnikan nsare tọ̀ ọ wá, o si kunlẹ fun u, o bi i lẽre, wipe, Olukọni rere, kili emi o ṣe ti emi o fi le jogún ìye ainipẹkun?


Njẹ nisisiyi, ará, mo fi nyin le Ọlọrun lọwọ ati ọ̀rọ ore-ọfẹ rẹ̀, ti o le gbe nyin duro, ti o si le fun nyin ni ini lãrin gbogbo awọn ti a sọ di mimọ́.


Lati là wọn li oju, ki nwọn ki o le yipada kuro ninu òkunkun si imọlẹ, ati kuro lọwọ agbara Satani si Ọlọrun, ki nwọn ki o le gbà idariji ẹ̀ṣẹ, ati ogún pẹlu awọn ti a sọ di mimọ́ nipa igbagbọ ninu mi.


Bi awa ba si jẹ ọmọ, njẹ ajogun li awa, ajogun Ọlọrun, ati ajumọ-jogun pẹlu Kristi; biobaṣepe awa bá a jìya, ki a si le ṣe wa logo pẹlu rẹ̀.


Ati olukuluku ẹniti njijàdu ati bori a ma ni iwọntunwọnsi ninu ohun gbogbo. Njẹ nwọn nṣe e lati gbà adé idibajẹ; ṣugbọn awa eyi ti ki idibajẹ.


Nitori bi ijogun na ba ṣe ti ofin, kì iṣe ti ileri mọ́: ṣugbọn Ọlọrun ti fi i fun Abrahamu nipa ileri.


Ninu ẹniti a fi wa ṣe ini rẹ̀ pẹlu, awa ti a ti yan tẹlẹ, gẹgẹ bi ipinnu ẹniti nṣiṣẹ ohun gbogbo gẹgẹ bi ìmọ ifẹ rẹ̀:


Eyiti iṣe ẹri ini wa, fun irapada ohun ini Ọlọrun si iyìn ogo rẹ̀.


Ki oju ọkàn nyin le mọlẹ; ki ẹnyin ki o le mọ ohun ti ireti ìpe rẹ̀ jẹ, ati ohun ti ọrọ̀ ogo ini rẹ̀ ninu awọn enia mimọ́ jẹ,


Ki a mã dupẹ lọwọ Baba, ẹniti o mu wa yẹ lati jẹ alabapin ninu ogún awọn enia mimọ́ ninu imọlẹ:


Nitori ireti ti a gbé kalẹ fun nyin li ọrun, nipa eyiti ẹnyin ti gbọ́ ṣaju ninu ọ̀rọ otitọ ti ihinrere,


Ki ẹ mọ̀ pe lọwọ Oluwa li ẹnyin ó gbà ère ogun: nitori ẹnyin nsìn Oluwa Kristi.


Lati isisiyi lọ a fi ade ododo lelẹ fun mi, ti Oluwa, onidajọ ododo, yio fifun mi li ọjọ na, kì si iṣe kìki emi nikan, ṣugbọn pẹlu fun gbogbo awọn ti o ti fẹ ifarahàn rẹ̀.


Nitori ẹnyin bá awọn ti o wà ninu ìde kẹdun, ẹ si fi ayọ̀ gbà ìkolọ ẹrù nyin, nitori ẹnyin mọ̀ ninu ara nyin pe, ẹ ni ọrọ̀ ti o wà titi, ti o si dara ju bẹ̃ lọ li ọ̀run.


Ati nitori eyi li o ṣe jẹ alarina majẹmu titun pe bi ikú ti mbẹ fun idande awọn irekọja ti o ti wà labẹ majẹmu iṣaju, ki awọn ti a ti pè le ri ileri ogún ainipẹkun gbà.


Nitori õrun là ti on ti õru mimu, o si gbẹ koriko, itanná rẹ̀ si rẹ̀ danu, ẹwà oju rẹ̀ si parun: bẹ̃ pẹlu li ọlọrọ̀ yio ṣegbe ni ọ̀na rẹ̀.


Ẹ máṣe fi buburu san buburu, tabi fi ẽbú san ẽbú; ṣugbọn kàka bẹ̃, ẹ mã súre; nitori eyi li a pè nyin si, ki ẹnyin ki o le jogún ibukún.


Nigbati olori Oluṣọ-agutan ba si fi ara hàn, ẹnyin ó gbà ade ogo ti kì iṣá.


Ohun alaimọ́ kan kì yio si wọ̀ inu rẹ̀ rara, tabi ohun ti nṣiṣẹ irira ati eke; bikoṣe awọn ti a kọ sinu iwe ìye Ọdọ-Agutan.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan