Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 1:3 - Bibeli Mimọ

3 Olubukún li Ọlọrun ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, Ẹniti o tún wa bí, gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀, sinu ireti ãye nipa ajinde Jesu Kristi kuro ninu okú,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, Baba Jesu Kristi Oluwa wa, tí ó fi ọ̀pọ̀ àánú rẹ̀ tún wa bí sí ìrètí tí ó wà láàyè nípa ajinde Jesu Kristi kúrò ninu òkú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ìyìn yẹ Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa! Ẹni tí ó tún wa bí gẹ́gẹ́ bí àánú ńlá rẹ̀ sínú ìrètí ààyè nípa àjíǹde Jesu Kristi kúrò nínú òkú,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 1:3
56 Iomraidhean Croise  

O si wipe, Ibukún ni fun Oluwa, Ọlọrun Israeli, ti o fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ fun Dafidi, baba mi, ti o si fi ọwọ́ rẹ̀ mu u ṣẹ, wipe,


Dafidi si sọ fun gbogbo ijọ enia pe, Nisisiyi ẹ fi iyìn fun Oluwa Ọlọrun nyin. Gbogbo enia si fi iyìn fun Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn, nwọn si tẹ ori wọn ba, nwọn wolẹ fun Oluwa ati ọba.


Nigbati Hesekiah ati awọn ijoye de, ti nwọn si ri òkiti wọnni, nwọn fi ibukún fun Oluwa, ati Israeli enia rẹ̀.


Olubukún ni Oluwa, Ọlọrun Israeli, lailai titi lai. Amin, Amin.


Ṣugbọn iwọ, Oluwa, li Ọlọrun ti o kún fun iyọ́nu, ati olore-ọfẹ, olupamọra, o si pọ̀ li ãnu ati otitọ.


Nitori iwọ, Oluwa, o ṣeun, o si mura ati dariji; o si pọ̀ li ãnu fun gbogbo awọn ti nkepè ọ.


OLUWA si rekọja niwaju rẹ̀, o si nkepè, OLUWA, OLUWA, Olọrun alãnu ati olore-ọfẹ, onipamọra, ati ẹniti o pọ̀ li ore ati otitọ;


Awọn okú rẹ yio yè, okú mi, nwọn o dide. Ẹ ji, ẹ si kọrin, ẹnyin ti ngbe inu ekuru: nitori ìri rẹ ìri ewebẹ̀ ni, ilẹ yio si sọ awọn okú jade.


O si gbadura si Oluwa, o si wipe, Emi bẹ ọ, Oluwa, ọ̀rọ mi kọ yi nigbati mo wà ni ilẹ mi? nitorina ni mo ṣe salọ si Tarṣiṣi ni iṣaju: nitori emi mọ̀ pe, Ọlọrun olore-ọfẹ ni iwọ, ati alãnu, o lọra lati binu, o si ṣeun pupọ, o si ronupiwada ibi na.


Awọn ẹniti a bí, kì iṣe nipa ti ẹ̀jẹ, tabi nipa ti ifẹ ara, bẹ̃ni kì iṣe nipa ifẹ ti enia, bikoṣe nipa ifẹ ti Ọlọrun.


Ẹ mã yọ̀ ni ireti; ẹ mã mu sũru ninu ipọnju; ẹ mã duro gangan ninu adura;


Njẹ ki Ọlọrun ireti ki o fi gbogbo ayọ̀ on alafia kún nyin ni gbigbagbọ, ki ẹnyin ki o le pọ̀ ni ireti nipa agbara Ẹmí Mimọ́.


Ẹniti a fi tọrẹ ẹ̀ṣẹ wa, ti a si jinde nitori idalare wa.


Njẹ bi, nigbati awa wà li ọtá, a mu wa ba Ọlọrun làja nipa ikú Ọmọ rẹ̀, melomelo, nigbati a là wa ni ìja tan, li a o gbà wa là nipa ìye rẹ̀.


Ṣugbọn bi Ẹmí ẹniti o jí Jesu dide kuro ninu okú ba ngbe inu nyin, ẹniti o ji Kristi Jesu dide kuro ninu okú yio fi Ẹmí rẹ̀ ti ngbe inu nyin, sọ ara kikú nyin di ãye pẹlu.


Nitori ireti li a fi gbà wa là: ṣugbọn ireti ti a bá ri kì iṣe ireti: nitori tani nreti ohun ti o bá ri?


Njẹ nisisiyi igbagbọ́, ireti, ati ifẹ mbẹ, awọn mẹta yi: ṣugbọn eyiti o tobi jù ninu wọn ni ifẹ.


Njẹ nisisiyi Kristi ti jinde kuro ninu okú, o si di akọbi ninu awọn ti o sùn.


Olubukún li Ọlọrun, ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, Baba iyọ́nu, ati Ọlọrun itunu gbogbo;


Iye awọn ti o si nrìn gẹgẹ bi ìwọn yi, alafia lori wọn ati ãnu, ati lori Israeli Ọlọrun.


Pe ki Ọlọrun Jesu Kristi Oluwa wa, Baba ogo, le fun nyin li Ẹmi nipa ti ọgbọ́n ati ti ifihan ninu ìmọ rẹ̀:


Olubukún li Ọlọrun ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, ẹniti o ti fi gbogbo ibukún ẹmí ninu awọn ọrun bukún wa ninu Kristi:


Ninu ẹniti awa ni irapada wa nipa ẹjẹ rẹ̀, idariji ẹ̀ṣẹ wa, gẹgẹ bi ọrọ̀ ore-ọfẹ rẹ̀;


Ṣugbọn Ọlọrun, ẹniti iṣe ọlọrọ̀ li ãnu, nitori ifẹ nla rẹ̀ ti o fi fẹ wa,


Njẹ ẹniti o le ṣe lọpọlọpọ jù gbogbo eyiti a mbère tabi ti a nrò lọ, gẹgẹ bi agbara ti nṣiṣẹ ninu wa,


Bi ẹnyin ba duro ninu igbagbọ́, ti ẹ fẹsẹmulẹ ti ẹ si duro ṣinṣin, ti ẹ kò si yẹsẹ kuro ninu ireti ihinrere ti ẹnyin ti gbọ́, eyiti a si ti wasu rẹ̀ ninu gbogbo ẹda ti mbẹ labẹ ọrun, eyiti a fi emi Paulu ṣe iranṣẹ fun.


Awọn ẹniti Ọlọrun fẹ lati fi ọrọ̀ ohun ijinlẹ yi larin awọn Keferi hàn fun, ti iṣe Kristi ninu nyin, ireti ogo:


Li aisimi li awa nranti iṣẹ igbagbọ́ nyin ati lãla ifẹ ati sũru ireti nyin ninu Oluwa wa Jesu Kristi, niwaju Ọlọrun ati Baba wa;


Ṣugbọn awa kò fẹ ki ẹnyin ki o jẹ òpe, ará, niti awọn ti o sùn, pe ki ẹ má binujẹ gẹgẹ bi awọn iyoku ti kò ni ireti.


Njẹ ki Jesu Kristi Oluwa wa tikararẹ̀, ati Ọlọrun Baba wa, ẹniti o ti fẹ wa, ti o si ti fi itunu ainipẹkun ati ireti rere nipa ore-ọfẹ fun wa,


Ore-ọfẹ Oluwa wa si pọ̀ rekọja pẹlu igbagbọ́ ati ifẹ, ti mbẹ ninu Kristi Jesu.


Ki a mã wo ọna fun ireti ti o ni ibukún ati ifarahan ogo Ọlọrun wa ti o tobi, ati ti Olugbala wa Jesu Kristi;


Ṣugbọn Kristi bi ọmọ lori ile rẹ̀; ile ẹniti awa iṣe, bi awa ba dì igbẹkẹle ati iṣogo ireti wa mu ṣinṣin titi de opin.


Nipa ifẹ ara rẹ̀ li o fi ọ̀rọ otitọ bí wa, ki awa ki o le jẹ bi akọso awọn ẹda rẹ̀.


Nitorina ẹ di ọkàn nyin li amure, ẹ mã wa li airekọja, ki ẹ si mã reti ore-ọfẹ nì titi de opin, eyiti a nmu bọ̀ fun nyin wá ni igba ifarahàn Jesu Kristi:


Ani ẹnyin ti o ti ipasẹ rẹ̀ gbà Ọlọrun gbọ́, ẹniti o jí i dide kuro ninu okú, ti o si fi ogo fun u; ki igbagbọ́ ati ireti nyin ki o le wà lọdọ Ọlọrun.


Bi a ti tun nyin bi, kì iṣe lati inu irú ti idibajẹ wá, bikoṣe eyiti ki idibajẹ, nipa ọ̀rọ Ọlọrun ti mbẹ lãye ti o si duro.


Bi ọmọ-ọwọ titun, ki ẹ mã fẹ wàra ti Ẹmí na eyiti kò li ẹ̀tan, ki ẹnyin ki o le mã ti ipasẹ rẹ̀ dàgba si igbala,


Ṣugbọn ẹ bọ̀wọ fun Kristi bi Oluwa lọkan nyin: ki ẹ si mura tan nigbagbogbo lati dá olukuluku lohùn ti mbere ireti ti o mbẹ ninu nyin, ṣugbọn pẹlu ọkàn tutù ati ìbẹru.


Apẹrẹ eyiti ngbà nyin là nisisiyi pẹlu, ani baptismu, kì iṣe ìwẹ ẽri ti ara nù, bikoṣe idahùn ọkàn rere sipa Ọlọrun, nipa ajinde Jesu Kristi:


Nitori bayi li awọn obinrin mimọ́ igbãni pẹlu, ti nwọn gbẹkẹle Ọlọrun, fi ṣe ara wọn li ọ̀ṣọ́, nwọn a mã tẹriba fun awọn ọkọ tiwọn.


Bi ẹnyin ba mọ̀ pe olododo ni on, ẹ mọ̀ pe a bi olukuluku ẹniti nṣe ododo nipa rẹ̀.


Olukuluku ẹniti o ba si ni ireti yi ninu rẹ̀, a wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́, ani bi on ti mọ́.


Ẹnikẹni ti a ti ipa Ọlọrun bí, ki idẹṣẹ; nitoriti irú rẹ̀ ngbe inu rẹ̀: kò si le dẹṣẹ nitoripe a ti ti ipa Ọlọrun bi i.


Olufẹ, ẹ jẹ ki a fẹràn ara wa: nitori ifẹ ti ọdọ Ọlọrun wá; ati gbogbo ẹniti o ba ni ifẹ, a bí i nipa ti Ọlọrun, o si mọ̀ Ọlọrun.


OLUKULUKU ẹniti o ba gbagbọ́ pe Jesu ni Kristi, a bí i nipa ti Ọlọrun: ati gbogbo ẹniti o fẹran ẹniti o bí ni, o fẹran ẹniti a bí nipasẹ rẹ̀ pẹlu.


Awa mọ̀ pe ẹnikẹni ti a bí nipa ti Ọlọrun kì idẹṣẹ: ṣugbọn ẹniti a bí nipa ti Ọlọrun a mã pa ara rẹ̀ mọ́, ẹni buburu nì ki si ifọwọ́kàn a.


Nitori olukuluku ẹniti a bí nipa ti Ọlọrun o ṣẹgun aiye: eyi si ni iṣẹgun ti o ṣẹgun aiye, ani igbagbọ́ wa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan