Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 5:3 - Bibeli Mimọ

3 Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, pe ki awa ki o pa ofin rẹ̀ mọ́: ofin rẹ̀ kò si nira.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Fífẹ́ràn Ọlọrun ni pé kí á pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́: àwọn àṣẹ rẹ̀ kò sì wọni lọ́rùn,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Nítorí èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run, pé kí àwa pa òfin rẹ̀ mọ́: òfin rẹ̀ kò sì nira,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 5:3
26 Iomraidhean Croise  

Nitoriti o faramọ Oluwa, kò si lọ kuro lẹhin rẹ̀, ṣugbọn o pa ofin rẹ̀ wọnni mọ, ti Oluwa ti pa li aṣẹ fun Mose.


Funfun gbò li ọ̀rọ rẹ: nitorina ni iranṣẹ rẹ ṣe fẹ ẹ.


Bẹ̃li emi o ma rìn ni alafia; nitori ti mo wá ẹkọ́ rẹ.


Emi a si ma fi ãnu hàn ẹgbẹgbẹrun awọn ti o fẹ́ mi, ti nwọn si npa ofin mi mọ́.


Ọ̀na rẹ̀, ọ̀na didùn ni, ati gbogbo ipa-ọ̀na rẹ̀, alafia.


Emi si gbadura si Oluwa Ọlọrun mi, mo si ṣe ijẹwọ mi, mo si wipe, Oluwa, iwọ Ọlọrun ti o tobi, ti o si li ẹ̀ru, ti npa majẹmu ati ãnu mọ́ fun awọn ti o fẹ ẹ, ati fun awọn ti o pa ofin rẹ̀ mọ́;


A ti fi hàn ọ, Iwọ enia, ohun ti o dara; ati ohun ti Oluwa bère lọwọ rẹ, bikoṣe ki o ṣe otitọ, ki o si fẹ ãnu, ati ki o rìn ni irẹ̀lẹ pẹlu Ọlọrun rẹ?


Nitori nwọn a di ẹrù wuwo ti o si ṣoro lati rù, nwọn a si gbé e kà awọn enia li ejika; ṣugbọn awọn tikarawọn ko jẹ fi ika wọn kàn ẹrù na.


Bi ẹnyin ba fẹran mi, ẹ ó pa ofin mi mọ́.


Bi ẹnyin ba pa ofin mi mọ́, ẹ o duro ninu ifẹ mi; gẹgẹ bi emi ti pa ofin Baba mi mọ́, ti mo si duro ninu ifẹ rẹ̀.


Ọrẹ́ mi li ẹnyin iṣẹ, bi ẹ ba ṣe ohun ti emi palaṣẹ fun nyin.


Bẹ̃ni mimọ́ li ofin, mimọ́ si li aṣẹ, ati ododo, ati didara.


Inu mi sá dùn si ofin Ọlọrun nipa ẹni ti inu:


Emi a si ma ṣe ãnu fun ẹgbẹgbẹrun awọn ti o fẹ́ mi, ti nwọn si pa ofin mi mọ́.


Nitorina ki iwọ ki o mọ̀ pe, OLUWA Ọlọrun rẹ, on li Ọlọrun; Ọlọrun olõtọ, ti npa majẹmu mọ́ ati ãnu fun awọn ti o fẹ́ ẹ, ti nwọn si pa ofin rẹ̀ mọ́ dé ẹgbẹrun iran;


Nitori eyi ni majẹmu ti emi ó ba ile Israeli da lẹhin ọjọ wọnni, li Oluwa wi; Emi ó fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ wọn si ọkàn wọn: emi o si mã jẹ́ Ọlọrun fun wọn, nwọn o si mã jẹ́ enia fun mi:


Nipa eyi li a si mọ̀ pe awa mọ̀ ọ, bi awa ba npa ofin rẹ̀ mọ́.


Eyi si ni ifẹ, pe, ki awa ki o mã rìn nipa ofin rẹ̀. Eyi li ofin na, ani bi ẹ ti gbọ́ li àtetekọṣe, pe, ki ẹnyin ki o mã rìn ninu rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan