Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 4:9 - Bibeli Mimọ

9 Nipa eyi li a gbé fi ifẹ Ọlọrun hàn ninu wa, nitoriti Ọlọrun rán Ọmọ bíbi rẹ̀ nikanṣoṣo si aiye, ki awa ki o le yè nipasẹ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Ọ̀nà tí Ọlọrun fi fi ìfẹ́ tí ó ní sí wa hàn ni pé ó ti rán ààyò ọmọ rẹ̀ wá sáyé kí á lè ní ìgbàlà nípasẹ̀ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Nípa èyí ni a gbé fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn nínú wa, nítorí tí Ọlọ́run rán ọmọ bíbí rẹ̀ nìkan ṣoṣo sì ayé, kí àwa lè yè nípasẹ̀ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 4:9
27 Iomraidhean Croise  

O si wi fun u pe, Mu ọmọ rẹ nisisiyi, Isaaki, ọmọ rẹ na kanṣoṣo, ti iwọ fẹ́, ki iwọ ki o si lọ si ilẹ Moria; ki o si fi i rubọ sisun nibẹ̀ lori ọkan ninu oke ti emi o sọ fun ọ.


Emi o si rohin ipinnu Oluwa: O ti wi fun mi pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bi ọ.


Ṣugbọn o kù ọmọ rẹ̀ kan ti o ni, ti iṣe ayanfẹ rẹ̀, o si rán a si wọn pẹlu nikẹhin, o wipe, Nwọn ó ṣe ojuṣãju fun ọmọ mi.


Ẹmi Oluwa mbẹ lara mi, nitoriti o fi àmi oróro yàn mi lati wasu ihinrere fun awọn òtoṣi; o ti rán mi wá lati ṣe iwosan awọn ọkàn onirobinujẹ, lati wasu idasilẹ fun awọn igbekun, itunriran fun awọn afọju, ati lati jọwọ awọn ti a pa lara lọwọ.


Olè kì iwá bikoṣe lati jale, ati lati pa, ati lati parun: emi wá ki nwọn le ni ìye, ani ki nwọn le ni i lọpọlọpọ.


Jesu wi fun u pe, Emi li ọ̀na, ati otitọ, ati iye: kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi.


Nitori Ọlọrun fẹ araiye tobẹ̃ gẹ, ti o fi Ọmọ bíbi rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ má bà ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun.


Ẹniti o ba gbà a gbọ́, a ko ni da a lẹjọ; ṣugbọn a ti da ẹniti kò gbà a gbọ́ lẹjọ na, nitoriti kò gbà orukọ Ọmọ bíbi kanṣoṣo ti Ọlọrun gbọ́.


Ki gbogbo enia ki o le mã fi ọlá fun Ọmọ gẹgẹ bi nwọn ti nfi ọlá fun Baba. Ẹniti kò ba fi ọlá fun Ọmọ, kò fi ọlá fun Baba ti o rán a.


Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Eyi ni iṣẹ Ọlọrun pe, ki ẹnyin ki o gbà ẹniti o rán gbọ́.


Emi ni onjẹ ìye nì ti o ti ọrun sọkalẹ wá: bi ẹnikẹni ba jẹ ninu onjẹ yi, yio yè titi lailai: onjẹ na ti emi o si fifunni li ara mi, fun ìye araiye.


Gẹgẹ bi Baba alãye ti rán mi, ti emi si ye nipa Baba: gẹgẹ bẹ̃li ẹniti o jẹ mi, on pẹlu yio yè nipa mi.


Ẹniti o rán mi si mbẹ pẹlu mi: kò jọwọ emi nikan si; nitoriti emi nṣe ohun ti o wù u nigbagbogbo.


Jesu wi fun wọn pe, Ibaṣepe Ọlọrun ni Baba nyin, ẹnyin iba fẹran mi: nitoriti emi ti ọdọ Ọlọrun jade, mo si wá: bẹ̃li emi kò si wá fun ara mi, ṣugbọn on li o rán mi.


Jesu dahùn pe, Kì iṣe nitoriti ọkunrin yi dẹṣẹ, tabi awọn obi rẹ̀: ṣugbọn ki a le fi iṣẹ Ọlọrun hàn lara rẹ̀.


Ẹniti kò da Ọmọ on tikararẹ̀ si, ṣugbọn ti o jọwọ rẹ̀ lọwọ fun gbogbo wa, yio ha ti ṣe ti kì yio fun wa li ohun gbogbo pẹlu rẹ̀ lọfẹ?


Nitori ewo ninu awọn angẹli li o wi fun rí pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bí ọ? Ati pẹlu, Emi yio jẹ Baba fun u, on yio si jẹ Ọmọ fun mi?


Nipa eyi li awa mọ̀ ifẹ nitoriti o fi ẹmí rẹ̀ lelẹ fun wa: o si yẹ ki awa fi ẹmí wa lelẹ fun awọn ará.


Ninu eyi ni ifẹ wà, kì iṣe pe awa fẹ Ọlọrun, ṣugbọn on fẹ wa, o si rán Ọmọ rẹ̀ lati jẹ ètutu fun ẹ̀ṣẹ wa.


Awa ti mọ̀, a si gbà ifẹ ti Ọlọrun ní si wa gbọ́. Ifẹ ni Ọlọrun; ẹniti o ba si ngbé inu ifẹ o ngbé inu Ọlọrun, ati Ọlọrun ninu rẹ̀.


Ẹ̀rí na si li eyi pe Ọlọrun fun wa ni ìye ainipẹkun, ìye yi si mbẹ ninu Ọmọ rẹ̀.


Nkan wọnyi ni mo kọwe rẹ̀ si nyin ani si ẹnyin ti o gbà orukọ Ọmọ Ọlọrun gbọ́; ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe ẹnyin ni iye ainipẹkun, ani fun ẹnyin ti o gbà orukọ Ọmọ Ọlọrun gbọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan