Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 4:5 - Bibeli Mimọ

5 Ti aiye ni nwọn, nitorina ni nwọn ṣe nsọrọ bi ẹni ti aiye, aiye si ngbọ́ ti wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 Láti inú ayé ni àwọn yìí ti wá; nítorí náà, wọ́n ń sọ nǹkan ti ayé, àwọn aráyé sì ń gbọ́ tiwọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Tí ayé ni wọ́n, nítorí náà ni wọn ṣe ń sọ̀rọ̀ bí ẹni ti ayé, ayé sì ń gbọ́ tí wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 4:5
15 Iomraidhean Croise  

Niti iṣẹ enia, nipa ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ emi ti pa ara mi mọ́ kuro ni ipa alaparun.


Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi pe, Ẹ máṣe jẹ ki awọn woli nyin ti o wà lãrin nyin ati awọn alafọṣẹ nyin tàn nyin jẹ, ki ẹ má si feti si alá nyin ti ẹnyin lá.


Awọn woli sọ asọtẹlẹ eke, ati awọn alufa ṣe akoso labẹ ọwọ wọn, awọn enia mi si fẹ ki o ri bẹ̃; kini ẹnyin o si ṣe ni igbẹhin rẹ̀?


Bi enia kan ti nrin ninu ẹmi ati itanjẹ ba ṣeke, wipe, emi o sọ asọtẹlẹ̀ ti ọti-waini ati ọti-lile fun ọ; on ni o tilẹ ṣe woli awọn enia yi.


Oluwa rẹ̀ si yìn alaiṣõtọ iriju na, nitoriti o fi ọgbọ́n ṣe e: awọn ọmọ aiye yi sá gbọ́n ni iran wọn jù awọn ọmọ imọlẹ lọ.


Emi ti fi ọ̀rọ rẹ fun wọn; aiye si ti korira wọn, nitoriti nwọn kì iṣe ti aiye, gẹgẹ bi emi kì iti iṣe ti aiye.


Nwọn kì iṣe ti aiye, gẹgẹ bi emi kì ti iṣe ti aiye.


Ẹniti o ti oke wá ju gbogbo enia lọ: ẹniti o ti aiye wá ti aiye ni, a si ma sọ̀ ohun ti aiye: ẹniti o ti ọrun wá ju gbogbo enia lọ.


O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti isalẹ wá; emi ti oke wá: ẹnyin jẹ ti aiye yi; emi kì iṣe ti aiye yi.


Nitoripe ìgba yio de, ti nwọn kì yio le gba ẹkọ́ ti o yè kõro; ṣugbọn bi nwọn ti jẹ ẹniti eti nrìn nwọn ó lọ kó olukọ jọ fun ara wọn ninu ifẹkufẹ ara wọn.


A si lé dragoni nla na jade, ejò lailai nì, ti a npè ni Èṣu, ati Satani, ti ntàn gbogbo aiye jẹ, a si lé e jù si ilẹ aiye, a si le awọn angẹli rẹ̀ jade pẹlu rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan