Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 4:2 - Bibeli Mimọ

2 Eyi li ẹ o fi mọ̀ Ẹmí Ọlọrun: gbogbo ẹmí ti o ba jẹwọ pe, Jesu Kristi wá ninu ara, ti Ọlọrun ni:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Ọ̀nà tí a óo fi mọ Ẹ̀mí Ọlọrun nìyí: gbogbo ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá sáyé gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran-ara jẹ́ ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Èyí ni ẹ ó fi mọ Ẹ̀mí Ọlọ́run: gbogbo ẹ̀mí tí ó ba jẹ́wọ́ pé, Jesu Kristi wá nínú ara, ti Ọlọ́run ni:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 4:2
10 Iomraidhean Croise  

Ọ̀rọ na si di ara, on si mba wa gbé, (awa si nwò ogo rẹ̀, ogo bi ti ọmọ bíbi kanṣoṣo lati ọdọ Baba wá,) o kún fun ore-ọfẹ ati otitọ.


Nitorina mo fẹ ki ẹ mọ̀ pe, kò si ẹniti nsọ̀rọ nipa Ẹmí Ọlọrun ki o wipe ẹni ifibu ni Jesu: ati pe, kò si ẹniti o le wipe, Oluwa ni Jesu, bikoṣe nipa Ẹmí Mimọ́.


Laiṣiyemeji, titobi ni ohun ijinlẹ ìwa-bi-Ọlọrun, ẹniti a fihan ninu ara, ti a dalare ninu Ẹmí, ti awọn angẹli ri, ti a wasu rẹ̀ lãrin awọn orilẹ-ede, ti a gbagbọ ninu aiye, ti a gba soke sinu ogo.


(Ìye na si ti farahàn, awa si ti ri i, awa si njẹri, awa si nsọ ti ìye ainipẹkun na fun nyin, ti o ti mbẹ lọdọ Baba, ti o si farahàn fun wa;)


Ẹnikẹni ti o ba sẹ́ Ọmọ, on na ni kò gbà Baba: ṣugbọn ẹniti o ba jẹwọ Ọmọ, o gbà Baba pẹlu.


Ẹnikẹni ti o ba jẹwọ pe Jesu Ọmọ Ọlọrun ni, Ọlọrun ngbé inu rẹ̀, ati on ninu Ọlọrun.


Gbogbo ẹmí ti kò si jẹwọ pe, Jesu Kristi wá ninu ara, kì iṣe ti Ọlọrun: eyi si li ẹmí Aṣodisi-Kristi na, ti ẹnyin ti gbọ́ pe o mbọ̀, ati nisisiyi o si ti de sinu aiye.


OLUKULUKU ẹniti o ba gbagbọ́ pe Jesu ni Kristi, a bí i nipa ti Ọlọrun: ati gbogbo ẹniti o fẹran ẹniti o bí ni, o fẹran ẹniti a bí nipasẹ rẹ̀ pẹlu.


Nitori ẹlẹtàn pupọ̀ ti jade wá sinu aiye, awọn ti kò jẹwọ pe Jesu Kristi wá ninu ara. Eyi li ẹlẹtàn ati Aṣodisi Kristi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan