Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 4:1 - Bibeli Mimọ

1 OLUFẸ, ẹ máṣe gbà gbogbo ẹmí gbọ́, ṣugbọn ẹ dán awọn ẹmí wò bi nwọn ba ṣe ti Ọlọrun: nitori awọn woli eke pupọ̀ ti jade lọ sinu aiye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Olùfẹ́, ẹ má ṣe gba gbogbo ẹni tí ó bá wí pé òun ní Ẹ̀mí Ọlọrun gbọ́. Ẹ kọ́kọ́ wádìí wọn láti mọ ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, nítorí ọpọlọpọ àwọn èké wolii ti wọ inú ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Olùfẹ́, ẹ má ṣe gba gbogbo ẹ̀mí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn ẹ̀mí wò bí wọn ba ń ṣe tí Ọlọ́run: nítorí àwọn wòlíì èké púpọ̀ tí jáde lọ sínú ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 4:1
29 Iomraidhean Croise  

O si wi fun u pe, Woli li emi pẹlu gẹgẹ bi iwọ; angeli si sọ fun mi nipa ọ̀rọ Oluwa wipe, Mu u ba ọ pada sinu ile rẹ, ki o le jẹ onjẹ ki o si le mu omi. Ṣugbọn o purọ fun u.


Òpe enia gbà ọ̀rọ gbogbo gbọ́: ṣugbọn amoye enia wò ọ̀na ara rẹ̀ rere.


Nigbana ni Oluwa wi fun mi pe, awọn woli nsọ asọtẹlẹ eke li orukọ mi; emi kò rán wọn, bẹ̃ni emi kò paṣẹ fun wọn, emi kò si sọ̀rọ kan fun wọn, iran eke, afọṣẹ, ati ohun asan, ati ẹ̀tan inu wọn, ni awọn wọnyi sọtẹlẹ fun nyin.


Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: Ẹ máṣe feti si ọ̀rọ awọn woli ti nsọ asọtẹlẹ fun nyin: nwọn sọ nyin di asan, nwọn sọ̀rọ iran inu ara wọn, kì iṣe lati ẹnu Oluwa.


Awọn woli sọ asọtẹlẹ eke, ati awọn alufa ṣe akoso labẹ ọwọ wọn, awọn enia mi si fẹ ki o ri bẹ̃; kini ẹnyin o si ṣe ni igbẹhin rẹ̀?


Nitorina bi ẹnikan ba wi fun nyin pe, wo o, Kristi mbẹ nihinyi; tabi, wo o, o mbẹ lọ́hun; ẹ máṣe gbà a gbọ́:


Ẽha si ti ṣe ti ẹnyin tikara nyin ko fi rò ohun ti o tọ́?


O si wipe, Ẹ mã kiyesara, ki a má bà mu nyin ṣina: nitori ọpọlọpọ yio wá li orukọ mi, ti yio mã wipe, Emi ni Kristi; akokò igbana si kù si dẹ̀dẹ: ẹ máṣe tọ̀ wọn lẹhin.


Awọn wọnyi si ni iyìn jù awọn ti Tessalonika lọ, niti pe nwọn fi tọkantọkan gbà ọ̀rọ na, nwọn si nwá inu iwe-mimọ́ lojojumọ́ bi nkan wọnyi ri bẹ̃.


Nitoriti emi mọ̀ pe, lẹhin lilọ mi, ikõkò buburu yio wọ̀ ãrin nyin, li aidá agbo si.


Ati fun ẹlomiran iṣẹ iyanu iṣe; ati fun ẹlomiran isọtẹlẹ; ati fun ẹlomiran ìmọ ẹmí yatọ; ati fun ẹlomiran onirũru ède; ati fun ẹlomiran itumọ̀ ède:


Jẹ ki awọn woli meji bi mẹta sọrọ, ki awọn iyoku si ṣe idajọ.


Ẹ máṣe kẹgan isọtẹlẹ.


Ẹ mã wadi ohun gbogbo daju; ẹ dì eyiti o dara mu ṣinṣin.


Ki ọkàn nyin ki o máṣe tete mì, tabi ki ẹ máṣe jaiya, yala nipa ẹmí, tabi nipa ọ̀rọ, tabi nipa iwe bi lati ọdọ wa wá, bi ẹnipe ọjọ Oluwa de.


ṢUGBỌN Ẹmí ntẹnumọ ọ pe, ni igba ikẹhin awọn miran yio kuro ninu igbagbọ́, nwọn o mã fiyesi awọn ẹmí ti ntan-ni-jẹ, ati ẹkọ́ awọn ẹmí èṣu;


Ṣugbọn awọn enia buburu, ati awọn ẹlẹtàn yio mã gbilẹ siwaju si i, nwọn o mã tàn-ni-jẹ, a o si mã tàn wọn jẹ.


ṢUGBỌN awọn woli eke wà lãrin awọn enia na pẹlu, gẹgẹ bi awọn olukọ́ni eke yio ti wà larin nyin, awọn ẹniti yio yọ́ mu adámọ ègbé wọ̀ inu nyin wá, ani ti yio sẹ́ Oluwa ti o rà wọn, nwọn o si mu iparun ti o yara kánkán wá sori ara wọn.


Ẹnyin ọmọ mi, igba ikẹhin li eyi: bi ẹnyin si ti gbọ́ pe Aṣodisi-Kristi mbọ̀wá, ani nisisiyi Aṣodisi-Kristi pupọ̀ ni mbẹ; nipa eyiti awa fi mọ̀ pe igba ikẹhin li eyi.


Ẹnyin olufẹ, ki iṣe ofin titun ni mo nkọwe rẹ̀ si nyin, ṣugbọn ofin atijọ ti ẹnyin ti ni li àtetekọṣe. Ofin atijọ ni ọ̀rọ na ti ẹnyin ti gbọ́.


Nitori ẹlẹtàn pupọ̀ ti jade wá sinu aiye, awọn ti kò jẹwọ pe Jesu Kristi wá ninu ara. Eyi li ẹlẹtàn ati Aṣodisi Kristi.


Olufẹ, máṣe afarawe ohun ti iṣe ibi, bikoṣe ohun ti iṣe rere. Ẹniti o ba nṣe rere ti Ọlọrun ni: ẹniti o ba nṣe buburu kò ri Ọlọrun.


Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati lãlã rẹ, ati ìfarada rẹ, ati bi ara rẹ kò ti gba awọn ẹni buburu: ati bi iwọ si ti dan awọn ti npè ara wọn ni aposteli, ti nwọn kì sì iṣe bẹ̃ wo, ti iwọ si ri pe eleke ni wọn;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan