Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 3:4 - Bibeli Mimọ

4 Ẹnikẹni ti o ba ndẹṣẹ o nrú ofin pẹlu: nitori ẹ̀ṣẹ ni riru ofin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Gbogbo ẹni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀ ń rú òfin, nítorí rírú òfin ni ẹ̀ṣẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ó ń rú òfin pẹ̀lú: nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ni rírú òfin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 3:4
17 Iomraidhean Croise  

Bi nwọn ba rò inu ara wọn wò ni ilẹ nibiti a gbe kó wọn ni igbèkun lọ, ti nwọn ba si ronupiwàda, ti nwọn ba si bẹ̀ ọ ni ilẹ awọn ti o kó wọn ni igbèkun lọ, wipe, Awa ti dẹṣẹ, awa ti ṣe ohun ti kò tọ, awa ti ṣe buburu;


Bẹ̃ni Saulu kú ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o da si Oluwa, nitori ọ̀rọ Oluwa, ti on kò kiyesi, ati pẹlu nitori o lọ bère ọ̀ràn lọwọ abokusọrọ, lati ṣe ibere.


Ẹmi Ọlọrun si bà le Sakariah, ọmọ Jehoiada alufa, ti o duro ni ibi giga jù awọn enia lọ, o si wi fun wọn pe, Bayi li Ọlọrun wi pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ru ofin Oluwa, ẹnyin kì yio ri ire? nitoriti ẹnyin ti kọ̀ Oluwa silẹ, on pẹlu si ti kọ̀ nyin.


A mu u jade lati ibi ihamọ on idajọ: tani o si sọ iran rẹ̀? nitori a ti ke e kuro ni ilẹ alãye: nitori irekọja awọn enia mi li a ṣe lù u.


Bẹ̃ni gbogbo Israeli ti ṣẹ̀ si ofin rẹ, ani nipa kikuro, ki nwọn ki o máṣe gbà ohùn rẹ gbọ́; nitorina li a ṣe yi egún dà si ori wa, ati ibura na ti a kọ sinu ofin Mose, iranṣẹ Ọlọrun, nitori ti awa ti ṣẹ̀ si i.


Nitoriti o gàn ọ̀rọ OLUWA, o si ru ofin rẹ̀; ọkàn na li a o ke kuro patapata, ẹ̀ṣẹ rẹ̀ yio wà lori rẹ̀.


Ẹnikẹni ti o ba rú ọkan kikini ninu ofin wọnyi, ti o ba si nkọ́ awọn enia bẹ̃, on na li a o pè ni kikini ni ijọba ọrun: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba nṣe wọn ti o ba si nkọ́ wọn, on na li a o pè ni ẹni-nla ni ijọba ọrun.


Nigbana ni Paulu wi fun u pe, Ọlọrun yio lù ọ, iwọ ogiri ti a kùn li ẹfun: iwọ joko lati dajọ mi ni gẹgẹ bi ofin, iwọ si pè ki a lù mi li òdi si ofin?


Nitoripe nipa iṣẹ ofin, a kì yio dá ẹnikẹni lare niwaju rẹ̀: nitori nipa ofin ni ìmọ ẹ̀ṣẹ ti wá.


Nitori ofin nṣiṣẹ́ ibinu: ṣugbọn nibiti ofin kò ba si, irufin kò si nibẹ̀.


Ati nigbati mo ba si pada de, ki Ọlọrun mi má ba rẹ̀ mi silẹ loju nyin, ati ki emi ki o má bã sọkun nitori ọpọlọpọ awọn ti o ti ṣẹ̀ na, ti nwọn kò si ronupiwada ẹ̀ṣẹ ìwa-ẽri, ati ti àgbere, ati ti wọ̀bia ti nwọn ti dá.


Adura igbagbọ́ yio si gbà alaisan na là, Oluwa yio si gbé e dide; bi o ba si ṣe pe o ti dẹ̀ṣẹ, a o dari jì i.


Gbogbo aiṣododo ni ẹ̀ṣẹ: ẹṣẹ̀ kan sì mbẹ ti ki iṣe si ikú.


Saulu si wi fun Samueli pe, Emi ti ṣẹ̀: nitoriti emi ti re ofin Oluwa kọja, ati ọ̀rọ rẹ̀: nitori emi bẹ̀ru awọn enia, emi si gbà ohùn wọn gbọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan