Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 3:3 - Bibeli Mimọ

3 Olukuluku ẹniti o ba si ni ireti yi ninu rẹ̀, a wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́, ani bi on ti mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Gbogbo ẹni tí ó bá ní ìrètí yìí ninu Jesu yóo wẹ ara rẹ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bí Jesu fúnrarẹ̀, ti jẹ́ mímọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Olúkúlùkù ẹni tí ó ba sì ní ìrètí yìí nínú rẹ̀, ń wẹ ara rẹ̀ mọ́, àní bí òun ti mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 3:3
21 Iomraidhean Croise  

Fun oninu-funfun ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni funfun: ati fun ẹni-wiwọ ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni wiwọ.


Nitorina ki ẹnyin ki o pé, bi Baba nyin ti mbẹ li ọrun ti pé.


Njẹ ki ẹnyin ki o li ãnu, gẹgẹ bi Baba nyin si ti li ãnu.


Emi si yà ara mi si mimọ́ nitori wọn, ki a le sọ awọn tikarawọn pẹlu di mimọ́ ninu otitọ.


Kò si fi iyatọ si ãrin awa ati awọn, o nfi igbagbọ́ wẹ̀ wọn li ọkàn mọ́.


Isaiah si tún wipe, Gbòngbo Jesse kan mbọ̀ wá, ati ẹniti yio dide ṣe akoso awọn Keferi; on li awọn Keferi yio ni ireti si.


NITORINA, ẹnyin olufẹ, bi a ti ni ileri wọnyi, ẹ jẹ ki a wẹ̀ ara wa mọ́ kuro ninu gbogbo ẹgbin ti ara ati ti ẹmí, ki a mã sọ ìwa mimọ́ di pipé ni ìbẹru Ọlọrun.


Nitori ireti ti a gbé kalẹ fun nyin li ọrun, nipa eyiti ẹnyin ti gbọ́ ṣaju ninu ọ̀rọ otitọ ti ihinrere,


Njẹ ki Jesu Kristi Oluwa wa tikararẹ̀, ati Ọlọrun Baba wa, ẹniti o ti fẹ wa, ti o si ti fi itunu ainipẹkun ati ireti rere nipa ore-ọfẹ fun wa,


Ki a le dá wa lare nipa ore-ọfẹ rẹ̀, ki a si le sọ wa di ajogún gẹgẹ bi ireti ìye ainipẹkun.


Ẹ mã lepa alafia pẹlu enia gbogbo, ati ìwa mimọ́, li aisi eyini kò si ẹniti yio ri Oluwa:


Pe, nipa ohun aileyipada meji, ninu eyiti ko le ṣe iṣe fun Ọlọrun lati ṣeke, ki awa ti o ti sá sabẹ ãbo le ni ìṣírí ti o daju lati dì ireti ti a gbé kalẹ niwaju wa mu:


Nitoripe irú Olori Alufa bẹ̃ li o yẹ wa, mimọ́, ailẹgan, ailẽri, ti a yà si ọ̀tọ kuro ninu ẹlẹṣẹ, ti a si gbéga jù awọn ọrun lọ;


Ẹ sunmọ Ọlọrun, on o si sunmọ nyin, Ẹ wẹ̀ ọwọ́ nyin mọ́, ẹnyin ẹlẹṣẹ; ẹ si ṣe ọkàn nyin ni mimọ́, ẹnyin oniye meji.


Ṣugbọn gẹgẹ bi Ẹni ti o pè nyin ti jẹ mimọ́, bẹ̃ni ki ẹnyin na si jẹ mimọ́ ninu ìwa nyin gbogbo:


Olubukún li Ọlọrun ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, Ẹniti o tún wa bí, gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀, sinu ireti ãye nipa ajinde Jesu Kristi kuro ninu okú,


Nipa eyiti o ti fi awọn ileri rẹ̀ ti o tobi pupọ ti o si ṣe iyebiye fun wa: pe nipa iwọnyi ni ki ẹnyin ki o le di alabapin ninu ìwa Ọlọrun, nigbati ẹnyin bá ti yọ kuro ninu ibajẹ ti mbẹ ninu aiye nipa ifẹkufẹ.


Nitorina, olufẹ, bi ẹnyin ti nreti irú nkan wọnyi, ẹ mura giri, ki a le bá nyin li alafia, li ailabawọn, ati li ailàbuku li oju rẹ̀.


Ẹniti o ba wipe on ngbé inu rẹ̀, on na pẹlu si yẹ lati mã rìn gẹgẹ bi on ti rìn.


Ninu eyi li a mu ifẹ ti o wà ninu wa pé, ki awa ki o le ni igboiya li ọjọ idajọ: nitoripe bi on ti ri, bẹ̃li awa si ri li aiye yi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan