Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 2:9 - Bibeli Mimọ

9 Ẹniti o ba wipe on mbẹ ninu imọlẹ, ti o si korira arakunrin rẹ̀, o mbẹ ninu òkunkun titi fi di isisiyi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Ẹni tí ó bá wí pé òun wà ninu ìmọ́lẹ̀, tí ó kórìíra arakunrin rẹ̀, wà ninu òkùnkùn sibẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Ẹni tí ó bá sì wí pé òun ń wà nínú ìmọ́lẹ̀, tí ó sì kórìíra arákùnrin rẹ̀ sì ń bẹ nínú òkùnkùn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 2:9
14 Iomraidhean Croise  

Absalomu ko si ba Amnoni sọ nkan, rere, tabi buburu: nitoripe Absalomu korira Amnoni nitori eyi ti o ṣe, ani ti o fi agbara mu Tamari aburo rẹ̀.


Nwọn kò mọ̀, bẹ̃ni nwọn kò fẹ ki oye ki o ye wọn; nwọn nrìn li òkunkun; gbogbo ipilẹ aiye yẹ̀ ni ipò wọn.


Iwọ kò gbọdọ korira arakunrin rẹ li ọkàn rẹ: ki iwọ ki o bá ẹnikeji rẹ wi, ki iwọ ki o máṣe jẹbi nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀.


Jesu wi fun wọn pe, Ibaṣepe ẹnyin fọju, ẹnyin kì ba ti li ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn nisisiyi ẹnyin wipe, Awa riran; nitorina ẹ̀ṣẹ nyin wà sibẹ̀.


Ni ijọ wọnni ni Peteru si dide duro li awujọ awọn ọmọ-ẹhin (iye awọn enia gbogbo ninu ijọ jẹ ọgọfa,) o ni,


Nitori ẹniti o ba ṣe alaini nkan wọnyi, o fọju, kò le riran li òkẽre, o si ti gbagbé pe a ti wẹ̀ on nù kuro ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ atijọ.


Bi awa ba wipe awa ní ìdapọ pẹlu rẹ̀, ti awa si nrìn ninu òkunkun, awa nṣeke, awa kò si ṣe otitọ:


Ṣugbọn ẹniti o ba korira arakunrin rẹ̀ o ngbe inu òkunkun, o si nrìn ninu òkunkun, kò si mọ̀ ibiti on nrè, nitoriti òkunkun ti fọ ọ li oju.


Ẹniti o ba wipe, emi mọ̀ ọ, ti kò si pa ofin rẹ̀ mọ́, eke ni, otitọ kò si si ninu rẹ̀.


Ninu eyi li awọn ọmọ Ọlọrun nfarahan, ati awọn ọmọ Èṣu: ẹnikẹni ti kò ba nṣe ododo kì iṣe ti Ọlọrun, ati ẹniti kò fẹràn arakunrin rẹ̀.


Bi ẹnikẹni ba wipe, Emi fẹran Ọlọrun, ti o si korira arakunrin rẹ̀, eke ni: nitori ẹniti kò fẹran arakunrin rẹ̀ ti o ri, bawo ni yio ti ṣe le fẹran Ọlọrun ti on kò ri?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan