Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 2:7 - Bibeli Mimọ

7 Ẹnyin olufẹ, ki iṣe ofin titun ni mo nkọwe rẹ̀ si nyin, ṣugbọn ofin atijọ ti ẹnyin ti ni li àtetekọṣe. Ofin atijọ ni ọ̀rọ na ti ẹnyin ti gbọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Olùfẹ́, kì í ṣe òfin titun ni mò ń kọ si yín. Òfin àtijọ́ tí ẹ ti níláti ìbẹ̀rẹ̀ ni. Òfin àtijọ́ náà ni ọ̀rọ̀ tí ẹ ti gbọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kì í ṣe òfin tuntun ni mo ń kọ̀wé rẹ̀ sí yín ṣùgbọ́n òfin àtijọ́, èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ ní àtètèkọ́ṣe. Òfin àtijọ́ ni ọ̀rọ̀ náà tí ẹ̀yin tí gbọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 2:7
22 Iomraidhean Croise  

Iwọ kò gbọdọ gbẹsan, bẹ̃ni ki o máṣe ṣe ikùnsinu si awọn ọmọ enia rẹ, ṣugbọn ki iwọ ki o fẹ́ ẹnikeji rẹ bi ara rẹ: Emi li OLUWA.


Ki alejò ti mbá nyin gbé ki o jasi fun nyin bi ibilẹ, ki iwọ ki o si fẹ́ ẹ bi ara rẹ; nitoripe ẹnyin ti ṣe alejò ni ilẹ Egipti: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.


Ẹnyin ti gbọ́ bi a ti wipe, Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ, ki iwọ si korira ọtá rẹ.


Ofin titun kan ni mo fifun nyin, Ki ẹnyin ki o fẹ ọmọnikeji nyin; gẹgẹ bi emi ti fẹran nyin, ki ẹnyin ki o si le fẹran ọmọnikeji nyin.


Nwọn si mu u, nwọn si fà a lọ si Areopagu, nwọn wipe, A ha le mọ̀ kili ẹkọ́ titun ti iwọ nsọrọ rẹ̀ yi jẹ́.


Ki iwọ ki o si fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo agbara rẹ fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ.


Ṣugbọn, olufẹ, awa ni igbagbọ ohun ti o dara jù bẹ̃ lọ niti nyin, ati ohun ti o faramọ igbala, bi awa tilẹ nsọ bayi.


Ṣugbọn ẹnyin, ki eyini ki o mã gbe inu nyin, ti ẹnyin ti gbọ́ li àtetekọṣe. Bi eyiti ẹnyin ti gbọ́ li àtetekọṣe ba ngbe inu nyin, ẹnyin ó si duro pẹlu ninu Ọmọ ati ninu Baba.


Nitori eyi ni iṣẹ ti ẹnyin ti gbọ́ li àtetekọṣe, ki awa ki o fẹràn ara wa.


Olufẹ, ọmọ Ọlọrun li awa iṣe nisisiyi, a kò si ti ifihàn bi awa ó ti ri: awa mọ pe, nigbati a bá fihan, a ó dabi rẹ̀; nitori awa o ri i ani bi on ti ri.


Olufẹ, bi ọkàn wa kò ba dá wa lẹbi, njẹ awa ni igboiya niwaju Ọlọrun.


Eyi si li ofin rẹ̀, pe ki awa ki o gbà orukọ Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀ gbọ́, ki a si fẹràn ara wa, gẹgẹ bi o ti fi ofin fun wa.


OLUFẸ, ẹ máṣe gbà gbogbo ẹmí gbọ́, ṣugbọn ẹ dán awọn ẹmí wò bi nwọn ba ṣe ti Ọlọrun: nitori awọn woli eke pupọ̀ ti jade lọ sinu aiye.


Olufẹ, bi Ọlọrun ba fẹ wa bayi, o yẹ ki a fẹràn ara wa pẹlu.


Ofin yi li awa si ri gbà lati ọwọ́ rẹ̀ wá, pe ẹniti o ba fẹran Ọlọrun ki o fẹran arakunrin rẹ̀ pẹlu.


Olufẹ, ẹ jẹ ki a fẹràn ara wa: nitori ifẹ ti ọdọ Ọlọrun wá; ati gbogbo ẹniti o ba ni ifẹ, a bí i nipa ti Ọlọrun, o si mọ̀ Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan