Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 1:8 - Bibeli Mimọ

8 Bi awa ba wipe awa kò li ẹ̀ṣẹ, awa tàn ara wa jẹ, otitọ kò si si ninu wa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Bí a bá wí pé a kò lẹ́ṣẹ̀, ara wa ni à ń tàn jẹ, òtítọ́ kò sì sí ninu wa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Bí àwa bá wí pé àwa kò ní ẹ̀ṣẹ̀, àwa ń tan ara wa jẹ, òtítọ́ kan kò sì ṣí nínú wa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 1:8
33 Iomraidhean Croise  

Bi nwọn ba ṣẹ̀ si ọ, nitoriti kò si enia kan ti kì iṣẹ̀, bi iwọ ba si binu si wọn, ti o si fi wọn le ọwọ́ ọta, tobẹ̃ ti a si kó wọn lọ ni igbèkun si ilẹ ọta, jijìna tabi nitosi;


On si wipe, Kini nwọn ri ni ile rẹ? Hesekiah si dahùn wipe, Gbogbo nkan ti mbẹ ni ile mi ni nwọn ti ri: kò si nkan ninu iṣura mi ti emi kò fi hàn wọn.


Bi nwọn ba ṣẹ̀ si ọ (nitoriti kò si enia kan ti kì iṣẹ̀,) bi iwọ ba si binu si wọn, ti o si fi wọn le awọn ọta lọwọ, ti nwọn ba si kó wọn ni igbekun lọ si ilẹ ti o jìna rére, tabi ti o wà nitosi.


Tali o le mu ohun mimọ́ lati inu aimọ́ jade wá? kò si ẹnikan!


Kili enia ti o fi mọ́? ati ẹniti a tinu obinrin bi ti yio fi ṣe olododo?


Eha ti ṣe ti a o fi da enia lare lọdọ Ọlọrun, tabi ẹniti a bi lati inu obinrin wá yio ha ṣe mọ́?


Emi mọ̀ pe bẹ̃ni nitõtọ! bawo li enia yio ha ti ṣe alare niwaju Ọlọrun?


Ki o má si ba ọmọ-ọdọ rẹ lọ sinu idajọ, nitori ti kò si ẹniti o wà lãye ti a o dalare niwaju rẹ.


Tali o le wipe, Mo ti mu aiya mi mọ́, emi ti mọ́ kuro ninu ẹ̀ṣẹ mi?


Nitoriti kò si olõtọ enia lori ilẹ, ti nṣe rere ti kò si dẹṣẹ.


Gbogbo wa ti ṣina kirikiri bi agutan, olukuluku wa tẹ̀le ọ̀na ara rẹ̀; Oluwa si ti mu aiṣedede wa gbogbo pade lara rẹ̀.


Gbogbo wa si dabi ohun aimọ́, gbogbo ododo wa si dabi akisa ẹlẹgbin; gbogbo wa si rẹ̀ bi ewe; aiṣedede wa si mu wa kuro bi afẹfẹ.


Sibẹ iwọ wipe, alaiṣẹ̀ li emi, ibinu rẹ̀ yio sa yipada lọdọ mi. Sa wò o, emi o ba ọ jà, nitori iwọ wipe, emi kò ṣẹ̀.


Bi ẹ̀tẹ ba si sọ jade kakiri li awọ ara, ti ẹ̀tẹ na ba si bò gbogbo ara ẹniti o ní àrun na, lati ori rẹ̀ titi dé ẹsẹ̀ rẹ̀, nibikibi ti alufa ba wò;


Ti eṣu baba nyin li ẹnyin iṣe, ifẹkufẹ baba nyin li ẹ si nfẹ ṣe. Apania li on iṣe lati atetekọṣe, ko si duro ni otitọ; nitoriti kò si otitọ ninu rẹ̀. Nigbati o ba nṣeke, ninu ohun tirẹ̀ li o nsọ, nitori eke ni, ati baba eke.


Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Kò si ẹniti iṣe olododo, kò si ẹnikan:


Gbogbo enia li o sá ti ṣẹ̀, ti nwọn si kuna ogo Ọlọrun;


Ki ẹnikẹni máṣe tàn ara rẹ̀ jẹ. Bi ẹnikẹni ninu nyin laiye yi ba rò pe on gbọ́n, ẹ jẹ ki o di aṣiwere, ki o le ba gbọ́n.


Nitori bi enia kan ba nrò ara rẹ̀ si ẹnikan, nigbati kò jẹ nkan, o ntàn ara rẹ̀ jẹ.


Ọ̀rọ̀ ayipo awọn enia ọlọkan ẽri ti kò si otitọ ninu wọn, ti nwọn ṣebi ọna si ere ni ìwa-bi-Ọlọrun: yẹra lọdọ irú awọn wọnni.


Ṣugbọn awọn enia buburu, ati awọn ẹlẹtàn yio mã gbilẹ siwaju si i, nwọn o mã tàn-ni-jẹ, a o si mã tàn wọn jẹ.


Ṣugbọn ki ẹ jẹ oluṣe ọ̀rọ na, ki o má si ṣe olugbọ́ nikan, ki ẹ mã tàn ara nyin jẹ.


Bi ẹnikẹni ba ro pe on nsìn Ọlọrun nigbati kò kó ahọn rẹ̀ ni ijanu, ṣugbọn ti o ntàn ọkàn ara rẹ̀ jẹ, ìsin oluwarẹ̀ asan ni.


Nitori ninu ohun pipọ ni gbogbo wa nṣì i ṣe. Bi ẹnikan kò ba ṣì i ṣe ninu ọ̀rọ, on na li ẹni pipé, on li o si le kó gbogbo ara ni ijanu.


Nwọn o si jẹ ère aiṣododo, awọn ti nwọn kà a si aiye jijẹ lati mã jẹ adùn aiye li ọsán. Nwọn jẹ́ abawọn ati àbuku, nwọn njaiye ninu asè-ifẹ́ wọn nigbati nwọn ba njẹ ase pẹlu nyin;


Bi awa ba wipe awa kò dẹṣẹ̀, awa mu u li eke, ọ̀rọ rẹ̀ kò si si ninu wa.


Bi awa ba wipe awa ní ìdapọ pẹlu rẹ̀, ti awa si nrìn ninu òkunkun, awa nṣeke, awa kò si ṣe otitọ:


Ẹniti o ba wipe, emi mọ̀ ọ, ti kò si pa ofin rẹ̀ mọ́, eke ni, otitọ kò si si ninu rẹ̀.


Bi ẹnikẹni ba wipe, Emi fẹran Ọlọrun, ti o si korira arakunrin rẹ̀, eke ni: nitori ẹniti kò fẹran arakunrin rẹ̀ ti o ri, bawo ni yio ti ṣe le fẹran Ọlọrun ti on kò ri?


Nitori otitọ ti ngbé inu wa, yio si mã ba wa gbé titi.


Nitori mo yọ̀ gidigidi, nigbati awọn arakunrin de ti nwọn si jẹri si otitọ rẹ, ani bi iwọ ti nrìn ninu otitọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan