Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 1:6 - Bibeli Mimọ

6 Bi awa ba wipe awa ní ìdapọ pẹlu rẹ̀, ti awa si nrìn ninu òkunkun, awa nṣeke, awa kò si ṣe otitọ:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Bí a bá wí pé a ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu rẹ̀, tí a bá ń gbé inú òkùnkùn, òpùrọ́ ni wá, a kò sì ṣe olóòótọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Bí àwa bá wí pé àwa ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, tí àwa sì ń rìn nínú òkùnkùn, àwa ń ṣèké, àwa kò sì gbé nínú òtítọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 1:6
25 Iomraidhean Croise  

Nwọn kò mọ̀, bẹ̃ni nwọn kò fẹ ki oye ki o ye wọn; nwọn nrìn li òkunkun; gbogbo ipilẹ aiye yẹ̀ ni ipò wọn.


Itẹ́ ẹ̀ṣẹ ha le ba ọ kẹgbẹ pọ̀, ti nfi ofin dimọ ìwa-ika?


Ẹniti o fi ipa-ọ̀na iduroṣinṣin silẹ, lati rìn li ọ̀na òkunkun;


Ọpọlọpọ enia ni yio wi fun mi li ọjọ na pe, Oluwa, Oluwa, awa ko ha sọtẹlẹ li orukọ rẹ? ati orukọ rẹ ki a fi lé awọn ẹmi èṣu jade? ati li orukọ rẹ ki a fi ṣe ọ̀pọ iṣẹ iyanu nla?


Ṣugbọn bi ẹnikan ba rìn li oru, yio kọsẹ̀, nitoriti kò si imọlẹ ninu rẹ̀.


Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Nigba diẹ si i ni imọlẹ wà lãrin nyin. Ẹ mã rìn nigbati ẹnyin ni imọlẹ, ki òkunkun máṣe ba le nyin: ẹniti o ba si nrìn li òkunkun kò mọ̀ ibiti on gbé nlọ.


Emi ni imọlẹ ti o wá si aiye, ki ẹnikẹni ti o ba gbà mi gbọ́ ki o máṣe wà li òkunkun.


Jesu si tun sọ fun wọn pe, Emi ni imọlẹ aiye; ẹniti o ba tọ̀ mi lẹhin kì yio rìn ninu òkunkun, ṣugbọn yio ni imọlẹ ìye.


Ẹ kò si mọ̀ ọ; ṣugbọn emi mọ̀ ọ: bi mo ba si wipe, emi kò mọ̀ ọ, emi ó di eke gẹgẹ bi ẹnyin: ṣugbọn emi mọ̀ ọ, mo si pa ọ̀rọ rẹ̀ mọ́.


Nipa agabagebe awọn ti nṣeke, awọn ti ọkàn awọn tikarawọn dabi eyiti a fi irin gbigbona jó.


Ere kili o jẹ, ará mi, bi ẹnikan wipe on ni igbagbọ́, ṣugbọn ti kò ni iṣẹ? igbagbọ́ nì le gbà a là bi?


Ti ẹnikan ninu nyin si wi fun wọn pe, Ẹ mã lọ li alafia, ki ara nyin ki o maṣe tutu, ki ẹ si yó; ṣugbọn ẹ kò fi nkan wọnni ti ara nfẹ fun wọn; ère kili o jẹ?


Ṣugbọn ẹnikan le wipe, Iwọ ni igbagbọ́, emi si ni iṣẹ: fi igbagbọ́ rẹ hàn mi li aisi iṣẹ, emi o si fi igbagbọ́ mi hàn ọ nipa iṣẹ mi.


Bi awa ba wipe awa kò dẹṣẹ̀, awa mu u li eke, ọ̀rọ rẹ̀ kò si si ninu wa.


Eyiti awa ti ri, ti awa si ti gbọ́ li awa nsọ fun nyin, ki ẹnyin pẹlu ki o le ní ìdapọ pẹlu wa: nitõtọ ìdapọ wa si mbẹ pẹlu Baba, ati pẹlu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi.


Bi awa ba wipe awa kò li ẹ̀ṣẹ, awa tàn ara wa jẹ, otitọ kò si si ninu wa.


Ẹniti o ba wipe, emi mọ̀ ọ, ti kò si pa ofin rẹ̀ mọ́, eke ni, otitọ kò si si ninu rẹ̀.


Bi ẹnikẹni ba wipe, Emi fẹran Ọlọrun, ti o si korira arakunrin rẹ̀, eke ni: nitori ẹniti kò fẹran arakunrin rẹ̀ ti o ri, bawo ni yio ti ṣe le fẹran Ọlọrun ti on kò ri?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan