Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 1:5 - Bibeli Mimọ

5 Eyi si ni iṣẹ ti awa ti gbọ́ lẹnu rẹ̀ ti awa si njẹ́ fun nyin, pe imọlẹ li Ọlọrun, òkunkun kò si sí lọdọ rẹ̀ rara.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 Iṣẹ́ tí ó fi rán wa, tí à ń jẹ́ fun yín nìyí: pé ìmọ́lẹ̀ ni Ọlọrun, kò sí òkùnkùn ninu rẹ̀ rárá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Èyí sì ni iṣẹ́ tí àwa ti gbọ́ lẹ́nu rẹ̀, tí àwa sì ń jẹ́ fún yín: pé ìmọ́lẹ̀ ni Ọlọ́run; ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ kò sì òkùnkùn rárá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 1:5
19 Iomraidhean Croise  

Nitõtọ òkunkun kì iṣu lọdọ rẹ; ṣugbọn oru tàn imọlẹ bi ọsan: ati òkunkun ati ọsan, mejeji bakanna ni fun ọ.


OLUWA ni imọlẹ mi ati igbala mi; tali emi o bẹ̀ru? Oluwa li agbara ẹmi mi; aiya tali yio fò mi?


Nitori pe pẹlu rẹ li orisun ìye wà: ninu imọlẹ rẹ li awa o ma ri imọlẹ.


Nitori Oluwa Ọlọrun li õrun ati asà: Oluwa yio fun ni li ore-ọfẹ ati ogo: kò si ohun rere ti yio fà sẹhin lọwọ awọn ti nrìn dede.


Ara ile Jakobu, ẹ wá, ẹ jẹ́ ka rìn ninu imọlẹ Ọluwa.


Õrùn kì yio jẹ imọlẹ rẹ mọ li ọsan, bẹ̃ni oṣupa kì yio fi imọlẹ rẹ̀ ràn fun ọ; ṣugbọn Oluwa yio ṣe imọlẹ ainipẹkun rẹ, ati Ọlọrun rẹ ogo rẹ.


O fi ohun ijinlẹ ati aṣiri hàn: o mọ̀ ohun ti o wà li òkunkun, lọdọ rẹ̀ ni imọlẹ si wà.


Eyi si li ẹrí Johanu, nigbati awọn Ju rán awọn alufã ati awọn ọmọ Lefi lati Jerusalemu wá lati bi i lẽre pe, Tani iwọ ṣe?


Ninu rẹ̀ ni ìye wà; ìye na si ni imọlẹ̀ araiye.


Imọlẹ otitọ mbẹ ti ntàn mọlẹ fun olúkulùku enia ti o wá si aiye.


Jesu si tun sọ fun wọn pe, Emi ni imọlẹ aiye; ẹniti o ba tọ̀ mi lẹhin kì yio rìn ninu òkunkun, ṣugbọn yio ni imọlẹ ìye.


Niwọn igba ti mo wà li aiye, emi ni imọlẹ aiye.


Nitoripe lọwọ Oluwa li emi ti gbà eyiti mo si ti fifun nyin, pe Jesu Oluwa li oru ọjọ na ti a fi i han, o mu akara:


Ẹnikanṣoṣo ti o ni aikú, ti ngbe inu imọlẹ ti a kò le sunmọ, ẹniti enia kan kò ri rí ti kò si le ri: ẹniti ọla ati agbara titi lai iṣe tirẹ. Amin.


Gbogbo ẹ̀bun rere ati gbogbo ẹ̀bun pipé lati oke li o ti wá, o si nsọkalẹ lati ọdọ Baba imọlẹ wá, lọdọ Ẹniti kò le si iyipada tabi ojiji àyida.


Nitori eyi ni iṣẹ ti ẹnyin ti gbọ́ li àtetekọṣe, ki awa ki o fẹràn ara wa.


Ilu na kò si ni iwá õrùn, tabi oṣupa, lati mã tan imọlẹ si i: nitoripe ogo Ọlọrun li o ntàn imọlẹ si i, Ọdọ-Agutan si ni fitila rẹ̀.


Oru kì yio si si mọ́; nwọn kò si ni iwá imọlẹ fitila, tabi imọlẹ õrùn; nitoripe Oluwa Ọlọrun ni yio tan imọlẹ fun wọn: nwọn o si mã jọba lai ati lailai.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan