Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 1:3 - Bibeli Mimọ

3 Eyiti awa ti ri, ti awa si ti gbọ́ li awa nsọ fun nyin, ki ẹnyin pẹlu ki o le ní ìdapọ pẹlu wa: nitõtọ ìdapọ wa si mbẹ pẹlu Baba, ati pẹlu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Ohun tí a ti rí, tí a sì ti gbọ́ ni à ń kéde fun yín, kí ẹ lè ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu wa. Ìrẹ́pọ̀ yìí ni a ní pẹlu Baba ati pẹlu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Àwa ń sọ fún yín, èyí tí àwa ti rí, tí àwa sì ti gbọ́, kí ẹ̀yin pẹ̀lú kí ó lè ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú wa. Nítòótọ́ ìdàpọ̀ wa sì ń bẹ pẹ̀lú Baba àti pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 1:3
38 Iomraidhean Croise  

Wò o, oju mi ti ri gbogbo eyi ri, eti mi si gbọ́ o si ti ye e.


Emi o si rohin ipinnu Oluwa: O ti wi fun mi pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bi ọ.


Emi o sọ̀rọ orukọ rẹ fun awọn arakunrin mi: li awujọ ijọ li emi o ma yìn ọ,


Emi o si fi àmi kan si ãrin wọn, emi o si rán awọn ti o salà ninu wọn si awọn orilẹ-ède, si Tarṣiṣi, Puli, ati Ludi, awọn ti nfà ọrun, si Tubali, on Jafani, si awọn erekuṣu ti o jina rére, ti nwọn kò ti igbọ́ okiki mi, ti nwọn kò si ti iri ogo mi; nwọn o si rohin ogo mi lãrin awọn Keferi.


Yio si ṣe, bi iwọ ba bá wa lọ, yio si ṣe, pe, orekore ti OLUWA ba ṣe fun wa, on na li awa o ṣe fun ọ.


Emi kò si si li aiye mọ́, awọn wọnyi si mbẹ li aiye, emi si mbọ̀ wá sọdọ rẹ. Baba mimọ́, pa awọn ti o ti fifun mi mọ́, li orukọ rẹ, ki nwọn ki o le jẹ ọ̀kan, ani gẹgẹ bi awa.


Ki gbogbo nwọn ki o le jẹ ọ̀kan; gẹgẹ bi iwọ, Baba, ti jẹ ninu mi, ati emi ninu rẹ, ki awọn pẹlu ki o le jẹ ọ̀kan ninu wa: ki aiye ki o le gbagbọ́ pe, iwọ li o rán mi.


Baba olododo, aiye kò mọ̀ ọ: ṣugbọn emi mọ̀ ọ, awọn wọnyi si mọ̀ pe iwọ li o rán mi.


Iye ainipẹkun na si li eyi, ki nwọn ki o le mọ̀ ọ, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi, ẹniti iwọ rán.


Ẹniti o ri i si jẹri, otitọ si li ẹrí rẹ̀: o si mọ̀ pe õtọ li on wi, ki ẹnyin ki o le gbagbọ́.


Awa si mu ihinrere wá fun nyin, ti ileri tí a ti ṣe fun awọn baba,


Ẹ wo o, ẹnyin ẹlẹgàn, ki ẹnu ki o si yà nyin, ki a si fẹ nyin kù: nitori emi nṣe iṣẹ kan li ọjọ nyin, iṣẹ ti ẹnyin kò jẹ gbagbọ, bi ẹnikan tilẹ rohìn rẹ̀ fun nyin.


Nwọn si duro ṣinṣin ninu ẹkọ́ awọn aposteli, ati ni idapọ, ni bibu akara ati ninu adura.


Nitoriti emi kò fà sẹhin lati sọ gbogbo ipinnu Ọlọrun fun nyin.


Awa kò sá le ṣaima sọ ohun ti awa ti ri, ti a si ti gbọ́.


Nitõtọ ifẹ inu rere wọn ni; ajigbese wọn ni nwọn sá ṣe. Nitori bi o ba ṣepe a fi awọn Keferi ṣe alajọni ninu ohun ẹmí wọn, ajigbese si ni wọn lati fi nkan ti ara ta wọn lọrẹ.


Ṣugbọn nipasẹ rẹ̀ li ẹnyin wà ninu Kristi Jesu, ẹniti Ọlọrun fi ṣe ọgbọ́n, ati ododo, ati isọdimimọ́, ati idande fun wa:


Olododo li Ọlọrun, nipasẹ ẹniti a pè nyin sinu ìdapọ Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi Oluwa wa.


NJẸ, ará, emi nsọ ihinrere na di mimọ̀ fun nyin ti mo ti wãsu fun nyin, eyiti ẹnyin pẹlu ti gbà, ninu eyi ti ẹnyin si duro;


Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa, ati ifẹ Ọlọrun, ati ìdapọ ti Ẹmí Mimọ́, ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.


Pe, awọn Keferi jẹ àjumọjogun ati ẹya-ara kanna, ati alabapin ileri ninu Kristi Jesu nipa ihinrere:


Gẹgẹ bi o ti tọ́ fun mi lati rò eyi fun gbogbo nyin, nitoriti ọkàn nyin wà lọdọ mi, niwọn bi o ti ṣepe gbogbo nyin ni iṣe alabapin ore-ọfẹ pẹlu mi ninu idè mi ati ninu idahùn-ẹjọ mi ati ifẹsẹmulẹ ihinrere.


NITORINA bi itunu kan ba wà ninu Kristi, bi iṣipẹ ifẹ kan ba si wà, bi ìdapọ ti Ẹmí kan ba wà, bi ìyọ́nu-anu ati iṣeun ba wà,


Ki emi ki o le mọ̀ ọ, ati agbara ajinde rẹ̀, ati alabapin ninu ìya rẹ̀, nigbati mo ba faramọ ikú rẹ̀;


Ẹniti o ti gbà wa kuro lọwọ agbara òkunkun, ti o si ṣi wa nipo sinu ijọba ayanfẹ ọmọ rẹ̀:


Ati lati duro dè Ọmọ rẹ̀ lati ọrun wá, ẹniti o si ji dide kuro ninu okú, ani Jesu na, ẹniti ngbà wa kuro ninu ibinu ti mbọ̀.


Awọn ti o si ni oluwa onigbagbọ́, ki nwọn máṣe gàn wọn nitori arakunrin ni nwọn; ṣugbọn ki nwọn tubọ mã sìn wọn, nitori awọn ti iṣe alabapin iṣẹ rere wọn jẹ onigbagbọ́ ati olufẹ. Nkan wọnyi ni ki o mã kọ́ni ki o si mã fi gba-ni-niyanju.


Wipe, Emi ó sọ̀rọ orukọ rẹ fun awọn ará mi, li ãrin ijọ li emi o kọrin iyìn rẹ.


NITORINA ẹnyin ará mimọ́, alabapín ìpe ọ̀run, ẹ gbà ti Aposteli ati Olori Alufa ijẹwọ wa ro, ani Jesu;


Nitori awa di alabapín pẹlu Kristi, bi awa ba dì ipilẹṣẹ igbẹkẹle wa mu ṣinṣin titi de opin;


AWỌN alàgba ti mbẹ lãrin nyin ni mo bẹ̀, emi ẹniti iṣe alàgba bi ẹnyin, ati ẹlẹri ìya Kristi, ati alabapin ninu ogo ti a o fihàn:


Nitori ki iṣe bi ẹniti ntọ ìtan asan lẹhin ti a fi ọgbọ́n-kọgbọn là silẹ, li awa fi agbara ati wíwá Jesu Kristi Oluwa wa hàn nyin, ṣugbọn ẹlẹri ọlá nla rẹ̀ li awa iṣe.


EYITI o ti wà li àtetekọṣe, ti awa ti gbọ́, ti awa ti fi oju wa ri, ti awa si ti tẹjumọ, ti ọwọ́ wa si ti dìmu, niti Ọrọ ìye;


Eyi si ni iṣẹ ti awa ti gbọ́ lẹnu rẹ̀ ti awa si njẹ́ fun nyin, pe imọlẹ li Ọlọrun, òkunkun kò si sí lọdọ rẹ̀ rara.


Ṣugbọn bi awa ba nrìn ninu imọlẹ, bi on ti mbẹ ninu imọlẹ, awa ní ìdapọ pẹlu ara wa, ẹ̀jẹ Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀ ni nwẹ̀ wa nù kuro ninu ẹṣẹ gbogbo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan