Sekariah 5 - Yoruba BibleÌran nípa Ìwé Kíká Tí Ó Ń Fò 1 Mo tún gbé ojú sókè, mo bá rí ìwé kíká kan tí ń fò ní òfuurufú. 2 Angẹli náà bi mí pé, “Kí ni o rí?” Mo bá dáhùn pé “Mo rí ìwé kíká kan tí ń fò ní òfuurufú. Ìwé náà gùn ní ìwọ̀n ogún igbọnwọ, (mita 9); ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá (mita 4½).” 3 Ó bá sọ fún mi pé, “Ègún tí yóo máa káàkiri gbogbo ilẹ̀ náà ni a kọ sinu ìwé yìí. Láti ìsinsìnyìí lọ, ẹnikẹ́ni tí ó bá jalè ati ẹnikẹ́ni tí ó bá búra èké, a óo yọ orúkọ rẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ náà.” 4 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “N óo rán ègún náà lọ sí ilé àwọn olè ati sí ilé àwọn tí wọn ń búra èké ní orúkọ mi. Yóo wà níbẹ̀ títí yóo fi run ilé náà patapata, ati igi ati òkúta rẹ̀.” Ìran nípa Obinrin Tó Wà ninu Apẹ̀rẹ̀ 5 Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ bá jáde, ó ní, “Gbé ojú rẹ sókè kí o tún wo kinní kan tí ń bọ̀.” 6 Mo bèèrè pé, “Kí ni èyí?” Ó dáhùn pé, “Agbọ̀n òṣùnwọ̀n eefa kan ni. Ó dúró fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan jákèjádò ilẹ̀ yìí.” 7 Nígbà tí wọ́n ṣí ìdérí òjé tí wọ́n fi bo agbọ̀n náà kúrò lórí rẹ̀, mo rí obinrin kan tí ó jókòó sinu eefa náà. 8 Angẹli náà sọ pé “Ìwà ìkà ni obinrin yìí dúró fún.” Ó ti obinrin náà pada sinu agbọ̀n eefa náà, ó sì fi ìdérí òjé náà dé e mọ́ ibẹ̀ pada. 9 Bí mo ti gbé ojú sókè ni mo rí àwọn obinrin meji tí wọn ń fi tagbára tagbára fò bọ̀, ìyẹ́ apá wọn dàbí ìyẹ́ ẹyẹ àkọ̀. Wọ́n hán agbọ̀n náà, wọ́n sì ń fò lọ. 10 Mo bi angẹli náà pé, “Níbo ni wọ́n ń gbé e lọ?” 11 Ó dáhùn pé, “Ilẹ̀ Ṣinari ni wọ́n ń gbé e lọ, láti lọ kọ́lé fún un níbẹ̀. Tí wọ́n bá parí ilé náà, wọn yóo gbé e kalẹ̀ sibẹ.” |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria