Romu 7 - Yoruba BibleÀpẹẹrẹ láti inú Igbeyawo 1 Ẹ̀yin ará mi, ohun tí mò ń wí yìí kò ṣe àjèjì si yín (nítorí ẹ̀yin náà mọ òfin), pé òfin de eniyan níwọ̀n ìgbà tí ó bá wà láàyè nìkan. 2 Bí àpẹẹrẹ, òfin igbeyawo de abilekọ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ rẹ̀ wà láàyè. Ṣugbọn bí ọkọ rẹ̀ bá kú, òfin tí ó de obinrin náà mọ́ ọkọ rẹ̀ kò ṣiṣẹ́ mọ́. 3 Wàyí ò, bí obinrin náà bá lọ bá ọkunrin mìíràn nígbà tí ọkọ rẹ̀ wà láàyè, alágbèrè ni a óo pè é. Ṣugbọn tí ọkọ rẹ̀ bá ti kú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin igbeyawo, kì í ṣe àgbèrè mọ́, bí ó bá lọ fẹ́ ọkọ mìíràn. 4 Bẹ́ẹ̀ náà ni, ẹ̀yin ará mi, ẹ̀yin náà ti kú ní ti Òfin, nígbà tí ẹ di ara kan náà pẹlu Kristi. Ẹ ti ní ọkọ mìíràn, àní, ẹni tí a ti jí dìde kúrò ninu òkú, kí á lè sin Ọlọrun lọ́nà tí yóo yọrí sí rere. 5 Tẹ́lẹ̀ rí, nígbà tí a ti ń ṣe ìfẹ́ inú wa bí ẹlẹ́ran-ara, èrò ọkàn wa a máa fà sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Òfin dá wa lẹ́kun rẹ̀, láti tì wá sí ohun tí àyọrísí rẹ̀ jẹ́ ikú. 6 Ṣugbọn nisinsinyii, a ti bọ́ kúrò lábẹ́ Òfin. A ti kú sí ohun tí ó dè wá. Báyìí, a kò sin Ọlọrun lọ́nà àtijọ́ mọ́, àní lọ́nà ti Òfin àkọsílẹ̀, ṣugbọn ní ọ̀nà titun ti Ẹ̀mí. Bí Òfin ti ń mú Eniyan Dẹ́ṣẹ̀ 7 Kí ni kí á wá wí wàyí ò? Ṣé Òfin wá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni? Rárá o! Ṣugbọn ṣá, èmi kì bá tí mọ ẹ̀ṣẹ̀ bí Òfin kò bá fi í hàn mí. Bí àpẹẹrẹ, ǹ bá tí mọ ojúkòkòrò bí Òfin kò bá sọ pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò.” 8 Àṣẹ yìí ni ẹ̀ṣẹ̀ rí dìrọ̀ mọ́ láti fi ṣiṣẹ́. Ó ń fi èrò oríṣìíríṣìí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí mi lọ́kàn. Bí a bá mú òfin kúrò, ẹ̀ṣẹ̀ di òkú. 9 Nígbà kan rí mò ń gbé ìgbésí-ayé mi láìsí òfin. Ṣugbọn nígbà tí òfin dé, ẹ̀ṣẹ̀ yọjú pẹlu, 10 ni mo bá kú. Òfin tí ó yẹ kí ó mú ìyè wá, ni ó wá di ọ̀ràn ikú fún mi. 11 Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ rí ohun dìrọ̀ mọ́ ninu òfin, ó tàn mí jẹ, ó sì pa mí kú. 12 Dájú, ohun mímọ́ ni Òfin, àwọn àṣẹ tí ó wà ninu rẹ̀ náà sì jẹ́ ohun mímọ́, ohun tí ó tọ́, tí ó sì dára. 13 Ǹjẹ́ ohun tí ó dára yìí ni ó ṣe ikú pa mí? Rárá o! Ẹ̀ṣẹ̀ níí ṣekú pani. Kí ẹ̀ṣẹ̀ lè fara rẹ̀ hàn bí ẹ̀ṣẹ̀, ó lo ohun tí ó dára láti pa mí kú, báyìí, ó hàn gbangba pé ibi gan-an ni ẹ̀ṣẹ̀ í ṣe, nítorí ó kó sábẹ́ òfin láti ṣe ibi. Ogun Tí Ń Jà ninu Eniyan 14 Àwa mọ̀ dájú pé Òfin jẹ́ nǹkan ti Ẹ̀mí. Ṣugbọn èmi jẹ́ eniyan ẹlẹ́ran-ara, tí a ti tà lẹ́rú fún ẹ̀ṣẹ̀. 15 Ìwà mi kò yé èmi alára; nítorí kì í ṣe àwọn nǹkan tí mo bá fẹ́ ṣe ni mò ń ṣe, àwọn nǹkan tí mo kórìíra gan-an ni mò ń ṣe. 16 Níwọ̀n ìgbà tí mo bá ń ṣe àwọn nǹkan tí n kò fẹ́, mò ń jẹ́rìí sí i pé Òfin jẹ́ ohun tí ó dára. 17 Wàyí ò, ó já sí pé kì í ṣe èmi alára ni mò ń hùwà bẹ́ẹ̀, bíkòṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi. 18 Mo mọ̀ dájú pé, kò sí agbára kan ninu èmi eniyan ẹlẹ́ran-ara, láti ṣe rere, n kò lágbára láti ṣe é. 19 Nítorí kì í ṣe nǹkan rere tí mo fẹ́ ṣe ni mò ń ṣe, ṣugbọn àwọn nǹkan burúkú tí n kò fẹ́, ni mò ń ṣe. 20 Tí ó bá wá jẹ́ pé àwọn nǹkan tí n kò fẹ́ ni mò ń ṣe, a jẹ́ pé kì í ṣe èmi ni mò ń ṣe é, bíkòṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi. 21 Mo wá rí i wàyí pé, ó ti di bárakú fún mi, pé nígbà tí mo bá fẹ́ ṣe rere, àwọn nǹkan burúkú ni ó yá sí mi lọ́wọ́. 22 Mo yọ̀ gidigidi ninu ọkàn mi pé Ọlọrun ṣe òfin. 23 Ṣugbọn bí mo ti wòye, àwọn ẹ̀yà ara mi ń tọ ọ̀nà mìíràn, tí ó lòdì sí ọ̀nà tí ọkàn mi fẹ́, ọ̀nà òdì yìí ni ó gbé mi sinu ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ninu àwọn ẹ̀yà ara mi. 24 Irú ẹ̀dá wo tilẹ̀ ni tèmi yìí! Ta ni yóo gbà mí lọ́wọ́ ara tí ó fẹ́ ṣekú pa mí yìí? 25 Háà! Ọpẹ́ ni fún Ọlọrun! Òun nìkan ló lè gbà mí là nípa Jesu Kristi Oluwa wa. Bí ọ̀rọ̀ ara mi ti wá rí nìyí: ní ìdà kinni, mò ń tẹ̀lé ìlànà òfin Ọlọrun ninu àwọn èrò ọkàn mi: ní ìdà keji ẹ̀wẹ̀, èmi yìí kan náà, gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran-ara, mo tún ń tọ ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria