Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Sol 7 - Yoruba Bible

1 Ẹsẹ̀ rẹ ti dára tó ninu bàtà, ìwọ, ọmọ aládé. Itan rẹ dàbí ohun ọ̀ṣọ́, tí ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà ṣe.

2 Ìdodo rẹ dàbí abọ́, tí kì í gbẹ fún àdàlú waini, ikùn rẹ dàbí òkítì ọkà, tí a fi òdòdó lílì yíká.

3 Ọmú rẹ mejeeji dàbí ọmọ àgbọ̀nrín meji, tí wọn jẹ́ ìbejì.

4 Ọrùn rẹ dàbí ilé-ìṣọ́ tí wọn fi eyín erin kọ́. Ojú rẹ dàbí adágún omi ìlú Heṣiboni, tí ó wà ní ẹnubodè Batirabimu. Imú rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Lẹbanoni, tí ó dojú kọ ìlú Damasku.

5 Orí rẹ dàbí adé lára rẹ, ó rí bí òkè Kamẹli, irun rẹ dàbí aṣọ elése-àlùkò tí ó ṣẹ́ léra, wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ irun orí rẹ ń dá ọba lọ́rùn.

6 O dára, o wuni gan-an, olùfẹ́ mi, ẹlẹgẹ́ obinrin.

7 Ìdúró rẹ dàbí igi ọ̀pẹ, ọyàn rẹ ṣù bí ìdì èso àjàrà.

8 Mo ní n óo gun ọ̀pẹ ọ̀hún, kí n di odi rẹ̀ mú. Kí ọmú rẹ dàbí ìdì èso àjàrà, kí èémí ẹnu rẹ rí bí òórùn èso ápù.

9 Ìfẹnukonu rẹ dàbí ọtí waini tí ó dára jùlọ, tí ń yọ́ lọ lọ́nà ọ̀fun, tí ń yọ́ lọ láàrin ètè ati eyín.


Obinrin

10 Olùfẹ́ mi ló ni mí, èmi ni ọkàn rẹ̀ sì fẹ́.

11 Máa bọ̀, olùfẹ́ mi, jẹ́ kí á jáde lọ sinu pápá, kí á lọ sùn ní ìletò kan.

12 Kí á lọ sinu ọgbà àjàrà láàárọ̀ kutukutu, kí á wò ó bóyá àjàrà ti ń rúwé, bóyá ó ti ń tanná; kí á wò ó bóyá igi Pomegiranate ti ń tanná, níbẹ̀ ni n óo ti fi ìfẹ́ mi fún ọ.

13 Èso Mandirake ń tú òórùn dídùn jáde, ẹnu ọ̀nà wa kún fún oríṣìíríṣìí èso tí ó wuni, tí mo ti pèsè wọn dè ọ́, olùfẹ́ mi, ati tuntun ati èyí tó ti pẹ́ nílé.

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan