O. Sol 3 - Yoruba Bible1 Mo wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́, lórí ibùsùn mi lálẹ́, mo wá a, ṣugbọn n kò rí i; mo pè é, ṣugbọn kò dáhùn. 2 N óo dìde nisinsinyii, n óo sì lọ káàkiri ìlú, n óo wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́, ní gbogbo òpópónà ati ní gbogbo gbàgede. Mo wá a ṣugbọn n kò rí i. 3 Àwọn aṣọ́de rí mi, bí wọ́n ṣe ń lọ káàkiri ìlú. Mo bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?” 4 Mo fẹ́rẹ̀ má tíì kúrò lọ́dọ̀ wọn, ni mo bá rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́. Mo dì í mú, n kò sì jẹ́ kí ó lọ, títí tí mo fi mú un dé ilé ìyá mi, ninu ìyẹ̀wù ẹni tí ó lóyún mi. 5 Mò ń kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, mo fi egbin ati àgbọ̀nrín inú igbó búra, pé, ẹ kò gbọdọ̀ jí olùfẹ́ mi, títí yóo fi wù ú láti jí. Orin Kẹta Obinrin 6 Kí ló ń jáde bọ̀ láti inú aṣálẹ̀ yìí, tí ó dàbí òpó èéfín, tí ó kún fún òórùn dídùn òjíá ati turari, pẹlu òórùn dídùn àtíkè àwọn oníṣòwò? 7 Wò ó! Solomoni ni wọ́n ń gbé bọ̀, lórí ìtẹ́ rẹ̀, ọgọta akọni ọkunrin, lára àwọn akọni Israẹli, ni ó yí ìtẹ́ rẹ̀ ká. 8 Gbogbo wọn dira ogun pẹlu idà, akọni sì ni wọ́n lójú ogun. Olukuluku dira pẹlu idà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, nítorí ìdágìrì ọ̀gànjọ́. 9 Igi Lẹbanoni ni Solomoni fi ṣe ìtẹ́ rẹ̀. 10 Ó fi fadaka ṣe àwọn ẹsẹ̀ ìjókòó rẹ̀, ó fi wúrà ṣe ẹ̀yìn rẹ̀, Aṣọ elése-àlùkò tí àwọn ọmọbinrin Jerusalẹmu hun ni ó fi ṣe tìmùtìmù ìjókòó rẹ̀. 11 Ẹ jáde lọ, ẹ̀yin ọmọbinrin Sioni, ẹ lọ wo Solomoni ọba, pẹlu adé tí ìyá rẹ̀ fi dé e lórí, ní ọjọ́ igbeyawo, ní ọjọ́ ìdùnnú ati ọjọ́ ayọ̀ rẹ̀. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria