O. Sol 1 - Yoruba Bible1 Àwọn orin tí ó dùn jùlọ tí Solomoni kọ nìwọ̀nyí: Orin Kinni Obinrin 2 Wá fi ẹnu kò mí lẹ́nu, nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí waini lọ. 3 Òróró ìpara rẹ ní òórùn dídùn, orúkọ rẹ dàbí òróró ìkunra tí a tú jáde; nítorí náà ni àwọn ọmọbinrin ṣe fẹ́ràn rẹ. 4 Fà mí mọ́ra, jẹ́ kí á ṣe kíá, ọba ti mú mi wọ yàrá rẹ̀. Inú wa yóo máa dùn, a óo sì máa yọ̀ nítorí rẹ a óo gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí waini lọ; abájọ tí gbogbo àwọn obinrin ṣe fẹ́ràn rẹ! 5 Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, mo dúdú lóòótọ́, ṣugbọn mo lẹ́wà, mo dàbí àgọ́ Kedari, mo rí bí aṣọ títa tí ó wà ní ààfin Solomoni. 6 Má wò mí tìka-tẹ̀gbin, nítorí pé mo dúdú, oòrùn tó pa mí ló ṣe àwọ̀ mi bẹ́ẹ̀. Àwọn ọmọ ìyá mi lọkunrin bínú sí mi, wọ́n fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà, ṣugbọn n kò tọ́jú ọgbà àjàrà tèmi alára. 7 Sọ fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mi fẹ́: níbo ni ò ó máa ń da àwọn ẹran rẹ lọ jẹko? Níbo ni wọ́n ti ń sinmi, nígbà tí oòrùn bá mú? Kí n má baà máa wá ọ kiri, láàrin agbo ẹran àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ? Ọkunrin 8 Ìwọ tí o lẹ́wà jùlọ láàrin àwọn obinrin, bí o kò bá mọ ibẹ̀, ṣá máa tẹ̀lé ipa agbo ẹran. Jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹran rẹ máa jẹko lẹ́bàá àgọ́ àwọn olùṣọ́-aguntan. 9 Olólùfẹ́ mi, mo fi ọ́ wé akọ ẹṣin tí ń fa kẹ̀kẹ́ ogun Farao. 10 Nǹkan ọ̀ṣọ́ mú kí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́wà, ẹ̀gbà ọrùn sì mú kí ọrùn rẹ lẹ́wà. 11 A óo ṣe àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà, tí a fi fadaka ṣe ọnà sí lára fún ọ. Obinrin 12 Nígbà tí ọba rọ̀gbọ̀kú lórí ìjókòó rẹ̀, turari mi ń tú òórùn dídùn jáde. 13 Olùfẹ́ mi dàbí àpò òjíá, bí ó ti sùn lé mi láyà. 14 Olùfẹ́ mi dàbí ìdì òdòdó igi Sipirẹsi, ninu ọgbà àjàrà Engedi. Ọkunrin 15 Wò ó! O mà dára o, olólùfẹ́ mi; o lẹ́wà pupọ. Ojú rẹ tutù bíi ti àdàbà. Obinrin 16 Háà, o mà dára o! Olùfẹ́ mi, o lẹ́wà gan-an ni. Ewéko tútù ni yóo jẹ́ ibùsùn wa. 17 Igi Kedari ni òpó ilé wa, igi firi sì ni ọ̀pá àjà ilé wa. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria