O. Daf 99 - Yoruba BibleỌlọrun Ọba Atóbijù 1 OLUWA jọba, kí àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì; ó gúnwà lórí àwọn kerubu; kí ilẹ̀ mì tìtì. 2 OLUWA tóbi ní Sioni, ó sì jọba lórí gbogbo orílẹ̀-èdè. 3 Jẹ́ kí wọ́n yin orúkọ rẹ tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, mímọ́ ni OLUWA! 4 Ọba alágbára, ìwọ tí o fẹ́ràn òdodo, o ti fi ìdí ẹ̀tọ́ múlẹ̀; o ti dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ ati òdodo ní ilẹ̀ Jakọbu. 5 Ẹ yin OLUWA, Ọlọrun wa, ẹ jọ́sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀; mímọ́ ni OLUWA! 6 Mose ati Aaroni wà lára àwọn alufaa rẹ̀; Samuẹli pàápàá wà lára àwọn tí ń pe orúkọ rẹ̀; wọ́n ké pe OLUWA ó sì dá wọn lóhùn. 7 Ó bá wọn sọ̀rọ̀ ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu; wọ́n pa òfin rẹ̀ mọ́; wọ́n sì tẹ̀lé ìlànà tí ó fún wọn. 8 OLUWA Ọlọrun wa, o dá wọn lóhùn; Ọlọrun tíí dáríjì ni ni o jẹ́ fún wọn; ṣugbọn ó gbẹ̀san ìwàkiwà wọn. 9 Ẹ yin OLUWA, Ọlọrun wa, kí ẹ sì jọ́sìn níbi òkè mímọ́ rẹ̀; nítorí pé mímọ́ ni OLUWA Ọlọrun wa. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria