O. Daf 98 - Yoruba BibleỌlọrun, Ọba gbogbo Ayé 1 Ẹ kọ orin titun sí OLUWA, nítorí tí ó ti ṣe ohun ìyanu; agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati apá mímọ́ rẹ̀ ni ó fi ṣẹgun. 2 OLUWA ti sọ ìṣẹ́gun rẹ̀ di mímọ̀, ó ti fi ìdáláre rẹ̀ hàn lójú àwọn orílẹ̀-èdè. 3 Ó ranti ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́ rẹ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli; gbogbo ayé ti rí ìṣẹ́gun Ọlọrun wa. 4 Gbogbo ayé, ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLUWA; ẹ bú sí orin ayọ̀, kí ẹ sì kọ orin ìyìn. 5 Ẹ fi hapu kọ orin ìyìn sí OLUWA, àní, hapu ati ohùn orin dídùn. 6 Ẹ fun fèrè ati ìwo kí ẹ sì hó ìhó ayọ̀ níwájú OLUWA Ọba. 7 Kí òkun ó hó, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, kí ayé hó, ati àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. 8 Omi òkun, ẹ pàtẹ́wọ́; kí ẹ̀yin òkè sì fi ayọ̀ kọrin pọ̀ 9 níwájú OLUWA, nítorí pé ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé. Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé; yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria