Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 97 - Yoruba Bible


Ọlọrun Ọba Atóbijù

1 OLUWA jọba, kí ayé ó yọ̀; jẹ́ kí inú ogunlọ́gọ̀ erékùṣù ó dùn.

2 Ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri ni ó yí i ká; òdodo ati ẹ̀tọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀.

3 Iná ń jó lọ níwájú rẹ̀, ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́tùn-ún lósì.

4 Mànàmáná rẹ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí ayé, ilẹ̀ ayé rí i, ó sì wárìrì.

5 Àwọn òkè ńlá yọ́ bí ìda níwájú OLUWA, àní, níwájú OLUWA gbogbo ayé.

6 Ojú ọ̀run ń kéde òdodo rẹ̀; gbogbo orílẹ̀-èdè sì ń wo ògo rẹ̀.

7 Ojú ti gbogbo àwọn tí ń bọ oriṣa, àwọn tí ń fi ère lásánlàsàn yangàn; gbogbo oriṣa ní ń foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀.

8 Àwọn ará Sioni gbọ́, inú wọn dùn. Àwọn ará ìlú Juda sì ń yọ̀, nítorí ìdájọ́ rẹ, OLUWA.

9 Nítorí ìwọ OLUWA ni Ọ̀gá Ògo, o ju gbogbo ayé lọ, a gbé ọ ga ju gbogbo oriṣa lọ.

10 Ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn OLUWA, ẹ kórìíra ibi; OLUWA á máa dá ẹ̀mí àwọn olùfọkànsìn rẹ̀ sí, a sì máa gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú.

11 Ìmọ́lẹ̀ á máa tàn fún àwọn olódodo, ayọ̀ sì wà fún àwọn olótìítọ́ inú.

12 Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA, ẹ̀yin olódodo, kí ẹ sì máa yin orúkọ mímọ́ rẹ̀.

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan