O. Daf 96 - Yoruba BibleỌlọrun Ọba Àwọn Ọba (1Kron 16:23-33) 1 Ẹ kọ orin titun sí OLUWA; gbogbo ayé, ẹ kọ orin sí OLUWA. 2 Ẹ kọ orin sí OLUWA, ẹ yin orúkọ rẹ̀; ẹ sọ nípa ìgbàlà rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́. 3 Ẹ kéde ògo rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè; ẹ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrin àwọn eniyan. 4 Nítorí OLUWA tóbi, ó yẹ kí á máa yìn ín lọpọlọpọ; ó sì yẹ kí á bẹ̀rù rẹ̀ ju gbogbo oriṣa lọ. 5 Nítorí oriṣa lásán ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ń sìn, ṣugbọn OLUWA ni ó dá ọ̀run. 6 Iyì ati ọlá ńlá ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀; agbára ati ẹwà kún inú ilé mímọ́ rẹ̀. 7 Ẹ yin OLUWA, gbogbo ẹ̀yin aráyé; ẹ kókìkí ògo ati agbára rẹ̀. 8 Ẹ fún OLUWA ní iyì tí ó tọ́ sí orúkọ rẹ̀, ẹ mú ọrẹ lọ́wọ́ wá sinu àgbàlá rẹ̀. 9 Ẹ sin OLUWA ninu ẹwà ìwà mímọ́; gbogbo ayé, ẹ wárìrì níwájú rẹ̀. 10 Ẹ wí láàrin àwọn orílẹ̀-èdè pé, “OLUWA jọba! A ti fi ìdí ayé múlẹ̀, kò sì ní yẹ̀ lae; OLUWA yóo fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan.” 11 Jẹ́ kí inú ọ̀run ó dùn, sì jẹ́ kí ayé ó yọ̀; kí òkun ó hó, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀. 12 Jẹ́ kí pápá oko ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ yọ̀. Nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóo fi ayọ̀ kọrin, 13 níwájú OLUWA, nítorí pé ó ń bọ̀; ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé. Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé; yóo sì fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria