O. Daf 93 - Yoruba BibleỌlọrun Ọba 1 OLUWA jọba; ó gbé ọlá ńlá wọ̀ bí ẹ̀wù; OLUWA gbé ọlá ńlá wọ̀, ó sì di agbára ni àmùrè. Ó fi ìdí ayé múlẹ̀; kò sì ní yẹ̀ laelae. 2 A ti fi ìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ láti ìgbà laelae; láti ayérayé ni o ti wà. 3 Ibú omi gbé ohùn wọn sókè, OLUWA, ibú omi gbé ohùn wọn sókè, ó sì ń sán bí ààrá. 4 OLUWA lágbára lókè! Ó lágbára ju ariwo omi òkun lọ, ó lágbára ju ìgbì omi òkun lọ. 5 Àwọn òfin rẹ kìí yipada, ìwà mímọ́ ni ó yẹ ilé rẹ títí lae, OLUWA. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria