O. Daf 92 - Yoruba BibleOrin Ìyìn 1 Ó dára kí eniyan máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, OLUWA; kí ó sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ, ìwọ Ọ̀gá Ògo; 2 ó dára kí eniyan máa kéde ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ní òwúrọ̀, kí ó máa kéde òtítọ́ rẹ ní alẹ́, 3 pẹlu orin, lórí ohun èlò orin olókùn mẹ́wàá, ati hapu. 4 Nítorí ìwọ, OLUWA, ti mú inú mi dùn nípa iṣẹ́ rẹ; OLUWA, mò ń fi ayọ̀ kọrin nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. 5 Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tóbi pupọ, OLÚWA! Èrò rẹ sì jinlẹ̀ pupọ! 6 Òpè eniyan kò lè mọ̀, kò sì le yé òmùgọ̀: 7 pé bí eniyan burúkú bá tilẹ̀ rú bíi koríko, tí gbogbo àwọn aṣebi sì ń gbilẹ̀, ó dájú pé ìparun ayérayé ni òpin wọn. 8 Ṣugbọn ẹni àgbéga títí lae ni ọ́, OLUWA. 9 Wò ó, OLUWA, àwọn ọ̀tá rẹ yóo parun; gbogbo àwọn aṣebi yóo sì fọ́n ká. 10 Ṣugbọn o ti gbé mi ga, o ti fún mi lágbára bíi ti ẹfọ̀n; o ti da òróró dáradára sí mi lórí. 11 Mo ti fi ojú mi rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi, mo sì ti fi etí mi gbọ́ ìparun àwọn ẹni ibi tí ó gbé ìjà kò mí. 12 Àwọn olódodo yóo gbilẹ̀ bí igi ọ̀pẹ, wọn óo dàgbà bí igi kedari ti Lẹbanoni. 13 Wọ́n dàbí igi tí a gbìn sí ilé OLUWA, tí ó sì ń dàgbà ninu àgbàlá Ọlọrun wa. 14 Wọn á máa so èso títí di ọjọ́ ogbó wọn, wọn á máa lómi lára, ewé wọn á sì máa tutù nígbà gbogbo; 15 láti fihàn pé olóòótọ́ ni OLUWA; òun ni àpáta mi, kò sì sí aiṣododo lọ́wọ́ rẹ̀. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria