O. Daf 87 - Yoruba BibleÌyìn Sioni 1 Ní orí òkè mímọ́ ni ìlú tí OLUWA tẹ̀dó wà. 2 OLUWA fẹ́ràn ẹnubodè Sioni ju gbogbo ìlú yòókù lọ ní ilẹ̀ Jakọbu. 3 Ọpọlọpọ nǹkan tó lógo ni a sọ nípa rẹ, ìwọ ìlú Ọlọrun. 4 Tí mo bá ń ka àwọn ilẹ̀ tí ó mọ rírì mi, n óo dárúkọ Ijipti ati Babiloni, Filistia ati Tire, ati Etiopia. Wọn á máa wí pé, “Ní Jerusalẹmu ni wọ́n ti bí eléyìí.” 5 A óo wí nípa Sioni pé, “Ibẹ̀ ni a ti bí eléyìí ati onítọ̀hún,” nítorí pé Ọ̀gá Ògo yóo fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀. 6 OLUWA yóo ṣírò rẹ̀ mọ́ wọn nígbà tí ó bá ń ṣe àkọsílẹ̀ àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ní Sioni ni a ti bí eléyìí.” 7 Àwọn akọrin ati àwọn afunfèrè ati àwọn tí ń jó yóo máa sọ pé, “Ìwọ, Sioni, ni orísun gbogbo ire wa.” |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria