O. Daf 86 - Yoruba BibleAdura Ìrànlọ́wọ́ 1 Tẹ́tí sí mi OLUWA, kí o sì gbọ́ adura mi, nítorí òtòṣì ati aláìní ni mí. 2 Dá ẹ̀mí mi sí nítorí olùfọkànsìn ni mí; gba èmi iranṣẹ rẹ tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là; ìwọ ni Ọlọrun mi. 3 Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí ìwọ ni mò ń kígbe pè tọ̀sán-tòru. 4 Mú inú iranṣẹ rẹ dùn, nítorí ìwọ ni mò ń gbadura sí. 5 Nítorí pé olóore ni ọ́, OLUWA, o máa ń dárí jini; ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ sí gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́. 6 Fetí sí adura mi, OLUWA, gbọ́ igbe ẹ̀bẹ̀ mi. 7 Ní ọjọ́ ìpọ́njú mo ké pè ọ́, nítorí pé o máa ń gbọ́ adura mi. 8 OLUWA, kò sí èyí tí ó dàbí rẹ ninu àwọn oriṣa; kò sì sí iṣẹ́ ẹni tí ó dàbí iṣẹ́ rẹ. 9 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí o dá ni yóo wá, OLUWA, wọn óo máa forí balẹ̀ níwájú rẹ: wọn óo sì máa yin orúkọ rẹ lógo. 10 Nítorí pé o tóbi, o sì ń ṣe ohun ìyanu; ìwọ nìkan ni Ọlọrun. 11 OLUWA, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, kí n lè máa rìn ninu òtítọ́ rẹ; kí n lè pa ọkàn pọ̀ láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ. 12 Gbogbo ọkàn ni mo fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, OLUWA, Ọlọrun mi; n óo máa yin orúkọ rẹ lógo títí lae. 13 Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi sí mi; o ti yọ ọkàn mi kúrò ninu isà òkú. 14 Ọlọrun, àwọn agbéraga dìde sí mi; ẹgbẹ́ àwọn ìkà, aláìláàánú kan ń lépa ẹ̀mí mi; wọn kò sì bìkítà fún ọ. 15 Ṣugbọn ìwọ, OLUWA, ni Ọlọrun aláàánú ati olóore; o kì í tètè bínú, o sì kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́. 16 Kọjú sí mi, kí o sì ṣàánú mi; fún èmi iranṣẹ rẹ ní agbára rẹ; kí o sì gba èmi ọmọ iranṣẹbinrin rẹ là. 17 Fi àmì ojurere rẹ hàn mí, kí àwọn tí ó kórìíra mi lè rí i, kí ojú sì tì wọ́n; nítorí pé ìwọ, OLUWA, ni o ràn mí lọ́wọ́, tí o sì tù mí ninu. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria