O. Daf 85 - Yoruba BibleAdura Ire Orílẹ̀-Èdè 1 OLUWA, o fi ojurere wo ilẹ̀ rẹ; o dá ire Jakọbu pada. 2 O dárí àìdára àwọn eniyan rẹ jì wọ́n; o sì bo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. 3 O mú ìrúnú rẹ kúrò; o dáwọ́ ibinu gbígbóná rẹ dúró. 4 Tún mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun Olùgbàlà wa; dáwọ́ inú tí ń bí ọ sí wa dúró. 5 Ṣé o óo máa bínú sí wa títí lae ni? Ṣé ibinu rẹ yóo máa tẹ̀síwájú láti ìran dé ìran ni? 6 Ṣé o ò ní tún sọ wá jí ni, kí àwọn eniyan rẹ lè máa yọ̀ ninu rẹ? 7 Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn wá, OLUWA; kí o sì fún wa ní ìgbàlà rẹ. 8 Jẹ́ kí n gbọ́ ohun tí Ọlọrun, OLUWA yóo wí, nítorí pé ọ̀rọ̀ alaafia ni yóo sọ fún àwọn eniyan rẹ̀, àní, àwọn olùfọkànsìn rẹ̀, ṣugbọn kí wọn má yipada sí ìwà òmùgọ̀. 9 Nítòótọ́, ìgbàlà rẹ̀ wà nítòsí fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀; kí ògo rẹ̀ lè wà ní ilẹ̀ wa. 10 Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ yóo pàdé; òdodo ati alaafia yóo dì mọ́ ara wọn. 11 Òtítọ́ yóo rú jáde láti inú ilẹ̀; òdodo yóo sì bojú wolẹ̀ láti ojú ọ̀run. 12 Dájúdájú, OLUWA yóo fúnni ní ohun tí ó dára; ilẹ̀ wa yóo sì mú èso jáde lọpọlọpọ. 13 Òdodo yóo máa rìn lọ níwájú rẹ̀, yóo sì sọ ipasẹ̀ rẹ̀ di ọ̀nà. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria