O. Daf 83 - Yoruba BibleAdura Ìṣẹ́gun 1 Ọlọrun, má dákẹ́; má wòran; Ọlọrun má dúró jẹ́ẹ́! 2 Wò ó! Àwọn ọ̀tá rẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọ; àwọn tí ó kórìíra rẹ sì ń yájú sí ọ. 3 Wọ́n pète àrékérekè sí àwọn eniyan rẹ; wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ sí àwọn tí ó sá di ọ́. 4 Wọ́n ní, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pa orílẹ̀-èdè wọn run; kí á má ranti orúkọ Israẹli mọ́!” 5 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jùmọ̀ pète pèrò; wọ́n dá majẹmu láti dojú kọ ọ́. 6 Àwọn ará Edomu, ati àwọn ọmọ Iṣimaeli, àwọn ará Moabu, ati àwọn ọmọ Hagiri, 7 àwọn ará Gebali, àwọn ọmọ Amoni, ati àwọn ọmọ Amaleki, àwọn ará Filistia ati àwọn tí ń gbé Tire. 8 Àwọn ará Asiria pàápàá ti dara pọ̀ mọ́ wọn; àwọn ni alátìlẹ́yìn àwọn ọmọ Lọti. 9 Ṣe wọ́n bí o ti ṣe àwọn ará Midiani, bí o ti ṣe Sisera ati Jabini ni odò Kiṣoni, 10 àwọn tí o parun ní Endori, tí wọ́n di ààtàn lórí ilẹ̀. 11 Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí o ti ṣe Orebu ati Seebu; ṣe àwọn ìjòyè wọn bí o ti ṣe Seba ati Salumuna, 12 àwọn tí ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á mú lára ilẹ̀ Ọlọrun kí á sọ ọ́ di tiwa.” 13 Ọlọrun mi, ṣe wọ́n bí ààjà tíí ṣe ewé, àní, bí afẹ́fẹ́ tíí ṣe fùlùfúlù. 14 Bí iná tíí jó igbó, àní, bí ọwọ́ iná sì ṣe ń jó òkè kanlẹ̀, 15 bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ìjì rẹ lé wọn, kí o sì fi ààjà rẹ dẹ́rù bà wọ́n. 16 Da ìtìjú bò wọ́n, kí wọn lè máa wá ọ kiri, OLUWA. 17 Jẹ́ kí ojú tì wọ́n, kí ìdààmú dé bá wọn títí lae, kí wọn sì ṣègbé ninu ìtìjú. 18 Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ nìkan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA, ni Ọ̀gá Ògo lórí gbogbo ayé. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria