O. Daf 82 - Yoruba BibleỌlọrun, Ọba Àwọn Ọba 1 Ọlọrun ti jókòó ní ààyè rẹ̀ ninu ìgbìmọ̀ ọ̀run; ó sì ń ṣe ìdájọ́ láàrin àwọn ẹ̀dá ọ̀run: 2 “Yóo ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin óo máa fi aiṣododo ṣe ìdájọ́, tí ẹ óo sì máa ṣe ojuṣaaju fún àwọn eniyan burúkú? 3 Ẹ ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn ọmọ aláìníbaba; ẹ sì máa ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn tí ojú ń pọ́n ati àwọn talaka. 4 Ẹ gba talaka ati aláìní sílẹ̀, ẹ gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú.” 5 Wọn kò ní ìmọ̀ tabi òye, wọ́n ń rìn kiri ninu òkùnkùn, títí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé fi mì tìtì. 6 Mo ní, “oriṣa ni yín, gbogbo yín ni ọmọ Ọ̀gá Ògo. 7 Ṣugbọn sibẹsibẹ, ẹ óo kú bí eniyan, ẹ ó sùn bí èyíkéyìí ninu àwọn ìjòyè.” 8 Dìde, Ọlọrun, ṣe ìdájọ́ ayé, nítorí tìrẹ ni gbogbo orílẹ̀-èdè! |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria