O. Daf 80 - Yoruba BibleFi Ojurere Wò Wá 1 Dẹtí sílẹ̀, ìwọ olùṣọ́-aguntan Israẹli, Ìwọ tí ò ń tọ́jú àwọn ọmọ Josẹfu bí agbo ẹran. Ìwọ tí o gúnwà láàrin àwọn kerubu, yọ bí ọjọ́ 2 níwájú Efuraimu ati Bẹnjamini ati Manase. Sọ agbára rẹ jí, kí o sì wá gbà wá là. 3 Mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun; fi ojurere wò wá, kí á le gbà wá là. 4 OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, yóo ti pẹ́ tó, tí o óo máa bínú sí adura àwọn eniyan rẹ? 5 O ti fi omijé bọ́ wọn bí oúnjẹ, o sì ti fún wọn ní omijé mu ní àmuyó. 6 O ti mú kí àwọn aládùúgbò wa máa jìjàdù lórí wa; àwọn ọ̀tá wa sì ń fi wá rẹ́rìn-ín láàrin ara wọn. 7 Mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun; fi ojurere wò wá, kí á lè là. 8 O mú ìtàkùn àjàrà kan jáde láti Ijipti; o lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde, o sì gbìn ín. 9 O ro ilẹ̀ fún un; ó ta gbòǹgbò wọlẹ̀, igi rẹ̀ sì gbilẹ̀. 10 Òjìji rẹ̀ bo àwọn òkè mọ́lẹ̀, ẹ̀ka rẹ sì bo àwọn igi kedari ńláńlá; 11 àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tàn kálẹ̀ títí kan òkun, àwọn èèhù rẹ̀ sì kan odò ńlá. 12 Kí ló dé tí o fi wó ògiri ọgbà rẹ̀, tí gbogbo àwọn tí ń kọjá lọ sì fi ń ká èso rẹ̀? 13 Àwọn ìmàdò inú ìgbẹ́ ń jẹ ẹ́ ní àjẹrun, gbogbo àwọn nǹkan tí ń káàkiri ninu oko sì ń jẹ ẹ́. 14 Jọ̀wọ́ tún yipada, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun! Bojúwolẹ̀ láti ọ̀run, kí o sì wò ó; kí o sì tọ́jú ìtàkùn àjàrà yìí, 15 ohun ọ̀gbìn tí o fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbìn, àní, ọ̀dọ́ igi tí o fi ọwọ́ ara rẹ tọ́jú. 16 Àwọn ọ̀tá ti dáná sun ún, wọ́n ti gé e lulẹ̀; fi ojú burúkú wò wọ́n, kí wọ́n ṣègbé! 17 Ṣugbọn di ẹni tí o fúnra rẹ yàn mú, àní, ọmọ eniyan, tí o fúnra rẹ sọ di alágbára. 18 Ṣe bẹ́ẹ̀, a kò sì ní pada lẹ́yìn rẹ; dá wa sí, a ó sì máa sìn ọ́! 19 Mú wa bọ̀ sípò, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun! Fi ojurere wò wá, kí á lè là! |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria