O. Daf 8 - Yoruba BibleÒgo OLUWA ati Ipò Eniyan 1 OLUWA, Oluwa wa, orúkọ rẹ níyìn pupọ ní gbogbo ayé! Ìwọ ni o gbé ògo rẹ kalẹ̀ lókè ọ̀run. 2 Àwọn ọmọ-ọwọ́ ati àwọn ọmọ-ọmú ń kọrin ògo rẹ, wọ́n ti fi ìdí agbára rẹ múlẹ̀, nítorí àwọn tí ó kórìíra rẹ, kí á lè pa àwọn ọ̀tá ati olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́. 3 Nígbà tí mo ṣe akiyesi ojú ọ̀run, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀, tí o sọlọ́jọ̀– 4 Kí ni eniyan jẹ́, tí o fi n náání rẹ̀? Àní, kí ni ọmọ eniyan, tí o fi ń ṣìkẹ́ rẹ̀? 5 O dá a, ipò rẹ̀ rẹlẹ̀ díẹ̀ sí ti ìwọ Ọlọrun, o sì ti fi ògo ati ọlá dé e ní adé. 6 O mú un jọba lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, o sì fi gbogbo nǹkan sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀: 7 àwọn aguntan, ati àwọn mààlúù, ati gbogbo ẹranko ninu igbó; 8 àwọn ẹyẹ ojú ọrun, àwọn ẹja inú òkun, ati gbogbo nǹkan tí ó ń lúwẹ̀ẹ́ ninu òkun. 9 OLUWA, Oluwa wa, orúkọ rẹ níyìn pupọ ní gbogbo ayé! |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria