O. Daf 75 - Yoruba BibleỌlọrun Onídàájọ́ 1 A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Ọlọrun; a dúpẹ́. À ń kéde orúkọ rẹ, a sì ń ròyìn iṣẹ́ ribiribi tí o ṣe. 2 OLUWA ní, “Nígbà tí àkókò tí mo yà sọ́tọ̀ bá tó, n óo ṣe ìdájọ́ pẹlu àìṣojúṣàájú. 3 Nígbà tí ayé bá ń mì síhìn-ín sọ́hùn-ún, ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀; èmi a mú kí òpó rẹ̀ dúró wámúwámú. 4 Èmi a sọ fún àwọn tí ń fọ́nnu pé, ‘Ẹ yé fọ́nnu’; èmi a sì sọ fún àwọn eniyan burúkú pé, ‘Ẹ yé ṣe ìgbéraga.’ 5 Ẹ má halẹ̀ ju bí ó ti yẹ lọ, ẹ má sì gbéraga.” 6 Nítorí pé kì í ṣe láti ìlà oòrùn, tabi láti ìwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í ṣe apá gúsù tabi àríwá ni ìgbéga tií wá. 7 Ọlọrun níí dájọ́ bí ó ti wù ú: á rẹ ẹnìkan sílẹ̀, á sì gbé ẹlòmíràn ga. 8 Ife kan wà ní ọwọ́ OLUWA, Ibinu Oluwa ló kún inú rẹ̀, ó ń ru bí ọtí àní bí ọtí tí a ti lú, yóo ṣẹ́ ninu rẹ̀; gbogbo àwọn eniyan burúkú ilẹ̀ ayé ni yóo sì mu ún, wọn óo mu ún tán patapata tòun ti gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀. 9 Ṣugbọn èmi óo máa yọ̀ títí lae, n óo kọ orin ìyìn sí Ọlọrun Jakọbu. 10 Ọlọrun yóo gba gbogbo agbára ọwọ́ àwọn eniyan burúkú kúrò; ṣugbọn yóo fi agbára kún agbára fún àwọn olódodo. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria