O. Daf 73 - Yoruba BibleÌdájọ́ Òdodo Ọlọrun 1 Nítòótọ́ Ọlọrun ṣeun fún Israẹli, ó ṣeun fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́. 2 Ṣugbọn, ní tèmi, mo fẹ́rẹ̀ yọ̀ ṣubú, ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ tàsé. 3 Nítorí mò ń ṣe ìlara àwọn onigbeeraga nígbà tí mo rí ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú. 4 Wọn kì í jẹ ìrora kankan, ara wọn dá pé, ó sì jọ̀lọ̀. 5 Wọn kì í ní wahala bí àwọn ẹlòmíràn; ìyọnu tíí dé bá àwọn ẹlòmíràn kì í dé ọ̀dọ̀ wọn. 6 Nítorí náà, wọn á kó ìgbéraga bọ ọrùn bí ẹ̀gbà, wọn á fi ìwà ipá bora bí aṣọ. 7 Wọ́n sanra tóbẹ́ẹ̀ tí ojú wọn yíbò; èrò òmùgọ̀ sì kún ọkàn wọn ní àkúnwọ́sílẹ̀. 8 Wọ́n ń pẹ̀gàn eniyan, wọ́n ń sọ̀rọ̀ pẹlu ìlara; wọ́n sì ń fi ìgbéraga halẹ̀. 9 Wọ́n ń fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun; wọn a sì máa sọ̀rọ̀ ìgbéraga káàkiri ayé. 10 Nítorí náà, àwọn eniyan á yipada, wọn á fara mọ́ wọn, wọn á máa yìn wọ́n, láìbìkítà fún ibi tí wọn ń ṣe. 11 Wọn á máa wí pé, “Báwo ni Ọlọrun ṣe lè mọ̀? Ǹjẹ́ Ọ̀gá Ògo tilẹ̀ ní ìmọ̀?” 12 Ẹ wò ó! Ayé àwọn eniyan burúkú nìwọ̀nyí; ara dẹ̀ wọ́n nígbà gbogbo, ọrọ̀ wọn sì ń pọ̀ sí i. 13 Lásán ni gbogbo aáyan mi láti rí i pé ọkàn mi mọ́, tí mo sì yọwọ́-yọsẹ̀ ninu ibi. 14 Nítorí pé tọ̀sán-tòru ni mò ń rí ìyọnu; láràárọ̀ ni à ń jẹ mí níyà. 15 Bí mo bá ní, “N óo sọ̀rọ̀ báyìí,” n óo kó àwọn ọmọ rẹ ṣìnà. 16 Ṣugbọn nígbà tí mo rò bí nǹkan wọnyi ṣe lè yé mi, mo rí i pé iṣẹ́ tíí dáni lágara ni. 17 Àfi ìgbà tí mo wọ ibi mímọ́ Ọlọrun lọ, ni mo tó wá rí òye ìgbẹ̀yìn wọn. 18 Nítòótọ́ ibi tí ń yọ̀ ni ó gbé wọn lé, ó sì mú kí wọn ṣubú sinu ìparun. 19 Wò ó bí wọn ṣe parun lọ́gán, tí ìpayà sì gbá wọn lọ patapata. 20 Wọ́n dàbí àlá tíí pòórá nígbà tí eniyan bá ta jí. OLUWA, nígbà tí o bá jí gìrì, wọn óo pòórá. 21 Nígbà tí ọkàn mí bàjẹ́, tí ọ̀rọ̀ náà gbóná lára mi, 22 mo hùwà òmùgọ̀, n kò sì lóye, mo sì dàbí ẹranko lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ. 23 Sibẹsibẹ nígbà gbogbo ni mo wà lọ́dọ̀ rẹ; o sì di ọwọ́ ọ̀tún mi mú. 24 Ò ń fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi sọ́nà; lẹ́yìn náà, o óo sì gbà mí sinu ògo. 25 Ta ni mo ní lọ́run lẹ́yìn rẹ? Kò sì sí ohun kan tí ó wù mí láyé yìí bíkòṣe ìwọ. 26 Àárẹ̀ lè mú ara ati ẹ̀mí mi, ṣugbọn Ọlọrun ni agbára ẹ̀mí mi, ati ìpín mi títí lae. 27 Ó dájú pé àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóo ṣègbé, o óo sì pa àwọn tí ó bá ṣe alaiṣootọ sí ọ run. 28 Ní tèmi o, ó dára láti súnmọ́ Ọlọrun; mo ti fi ìwọ OLUWA Ọlọrun ṣe ààbò mi, kí n lè máa ròyìn gbogbo iṣẹ́ rẹ. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria