O. Daf 71 - Yoruba BibleAdura Àgbàlagbà kan 1 OLUWA, ìwọ ni mo sá di; má jẹ́ kí ojú ó tì mí laelae! 2 Gbà mí, kí o sì yọ mí nítorí òdodo rẹ; tẹ́tí sí mi kí o sì gbà mí là! 3 Máa ṣe àpáta ààbò fún mi, jẹ́ odi alágbára fún mi kí o sì gbà mí, nítorí ìwọ ni ààbò ati odi mi. 4 Ọlọrun mi, gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú, àwọn alaiṣootọ ati ìkà. 5 Nítorí ìwọ OLUWA, ni ìrètí mi, OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé láti ìgbà èwe mi. 6 Ìwọ ni mo gbára lé láti inú oyún; ìwọ ni o mú mi jáde láti inú ìyá mi. Ìwọ ni n óo máa yìn nígbà gbogbo. 7 Mo di ẹni àmúpòwe fún ọpọlọpọ eniyan, ṣugbọn ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára. 8 Ẹnu mi kún fún ìyìn rẹ, ó kún fún ògo rẹ tọ̀sán-tòru. 9 Má ta mí nù ní ìgbà ogbó mi; má sì gbàgbé mi nígbà tí n kò bá lágbára mọ́. 10 Nítorí pé àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi, àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi ti pàmọ̀ pọ̀, 11 wọ́n ní, “Ọlọrun ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀; ẹ lé e, ẹ mú un; nítorí kò sí ẹni tí yóo gbà á sílẹ̀ mọ́.” 12 Ọlọrun, má jìnnà sí mi; yára, Ọlọrun mi, ràn mí lọ́wọ́! 13 Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn alátakò mi, kí wọn parun; kí ẹ̀gàn ati ìtìjú bo àwọn tí ń wá ìpalára mi. 14 Ní tèmi, èmi ó máa ní ìrètí nígbà gbogbo, n óo sì túbọ̀ máa yìn ọ́. 15 N óo máa ṣírò iṣẹ́ rere rẹ, n óo máa ròyìn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ tọ̀sán-tòru, nítorí wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí n kò lè mọ iye wọn. 16 N óo wá ninu agbára OLUWA Ọlọrun, n óo máa kéde iṣẹ́ òdodo rẹ, àní, iṣẹ́ òdodo tìrẹ nìkan. 17 Ọlọrun, láti ìgbà èwe mi ni o ti kọ́ mi, títí di òní ni mo sì ń polongo iṣẹ́ ìyanu rẹ, 18 Nisinsinyii tí mo ti dàgbà, tí ewú sì ti gba orí mi, Ọlọrun, má kọ̀ mí sílẹ̀, títí tí n óo fi ròyìn iṣẹ́ ńlá rẹ, àní, iṣẹ́ agbára rẹ, fún gbogbo àwọn ìran tí ń bọ̀. 19 Ọlọrun, iṣẹ́ òdodo rẹ kan ojú ọ̀run, ìwọ tí o ṣe nǹkan ńlá, Ọlọrun, ta ni ó dàbí rẹ? 20 O ti jẹ́ kí n rí ọpọlọpọ ìpọ́njú ńlá, ṣugbọn óo tún mú ìgbé ayé mi pada bọ̀ sípò; óo tún ti gbé mi dìde láti inú isà òkú. 21 O óo fi kún ọlá mi, o óo sì tún tù mí ninu. 22 Èmi náà óo máa fi hapu yìn ọ́, nítorí òtítọ́ rẹ, Ọlọrun mi; n óo máa fi ohun èlò orin yìn ọ́, ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli. 23 N óo máa kígbe fún ayọ̀, nígbà tí mo bá ń kọ orin ìyìn sí ọ; ẹ̀mí mi tí o ti kó yọ, yóo ké igbe ayọ̀. 24 Ẹnu mi yóo ròyìn iṣẹ́ rẹ tọ̀sán-tòru, nítorí a ti ṣẹgun àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára, a sì ti dójú tì wọ́n. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria