O. Daf 7 - Yoruba BibleỌlọrun Onídàájọ́ Òdodo 1 OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni mo sá di; gbà mí là, kí o sì yọ mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi. 2 Kí wọn má baà fà mí ya bíi kinniun, kí wọn máa wọ́ mi lọ láìsí ẹni tí ó lè gbà mí sílẹ̀. 3 OLUWA, Ọlọrun mi, bí mo bá ṣe nǹkan yìí, bí iṣẹ́ ibi bá ń bẹ lọ́wọ́ mi, 4 bí mo bá fi ibi san án fún olóore, tabi tí mo bá kó ọ̀tá mi lẹ́rú láìnídìí, 5 jẹ́ kí ọ̀tá ó lé mi bá, kí ó tẹ̀ mí pa, kí ó sì bo òkú mi mọ́ ilẹ̀ẹ́lẹ̀. 6 OLUWA, fi ibinu dìde! Gbéra, kí o bá àwọn ọ̀tá mi jà ninu ìrúnú wọn; jí gìrì, Ọlọrun mi; ìwọ ni o ti fi ìlànà òdodo lélẹ̀. 7 Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ayé ó rọ̀gbà yí ọ ká, kí o sì máa jọba lé wọn lórí láti òkè wá. 8 OLUWA ló ń ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ayé; dá mi láre, OLUWA, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi ati ìwà pípé mi. 9 Ìwọ Ọlọrun Olódodo, tí o mọ èrò ati ìfẹ́ inú eniyan, fi òpin sí ìwà ibi àwọn eniyan burúkú, kí o sì fi ìdí àwọn olódodo múlẹ̀. 10 Ọlọrun ni aláàbò mi, òun níí gba àwọn ọlọ́kàn mímọ́ là. 11 Onídàájọ́ òdodo ni Ọlọrun, a sì máa bínú sí àwọn aṣebi lojoojumọ. 12 Bí wọn kò bá yipada, Ọlọrun yóo pọ́n idà rẹ̀; ó ti tẹ ọrun rẹ̀, ó sì ti fi ọfà lé e. 13 Ó ti pèsè ohun ìjà ikú sílẹ̀, ó sì ti tọ́jú ọfà iná. 14 Wò ó, eniyan burúkú lóyún ibi, ó lóyún ìkà, ó sì bí èké. 15 Ó gbẹ́ kòtò, ó sì jìn sinu kòtò tí ó gbẹ́. 16 Ìkà rẹ̀ pada sórí ara rẹ̀, àní ìwà ipá rẹ̀ sì já lù ú ní àtàrí. 17 N óo fi ọpẹ́ tí ó yẹ fún OLUWA nítorí òdodo rẹ̀, n óo fi orin ìyìn kí OLUWA, Ọ̀gá Ògo. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria